13 – àwọn tọkọtaya oníbálòpọ̀ kan náà

Awọn wọnyi ni awọn ọrọ mimọ ti Ọlọrun Olodumare.
A ko nifẹ si awọn ọrọ ti awọn eniyan.
Fun ẹnikẹni ti o ba fẹràn Ọlọrun ... Eyi ni ohun ti Ọlọrun sọ nipa: àwọn tọkọtaya oníbálòpọ̀ kan náà.

Top 3 julọ pataki ẹsẹ

Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìṣòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jesu Kristi Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa.

Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́: nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ ń yí ìṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tí ó tọ̀nà, sí èyí tí kò tọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìbálòpọ̀ obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí. Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe:

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọkùnrin lòpọ̀ bí ìgbà tí ènìyàn ń bá obìnrin lòpọ̀: ìríra ni èyí jẹ́. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀ kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́. Obìnrin kò sì gbọdọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀, ohun tó lòdì ni.

Gbogbo ẹsẹ ni Canonical Order – 21 awọn ẹsẹ

Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ní àwòrán Ọlọ́run ni Ó dá a, akọ àti abo ni Ó dá wọn.

Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.

OLÚWA sì wí pé, igbe Sodomu àti Gomorra pọ̀ púpọ̀ àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jọjọ. “Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ síbẹ̀ láti ṣe ìwádìí igbe tí ó dé sí etí ìgbọ́ mi nípa wọn, kí èmi sì mọ òtítọ́ tí ó wà níbẹ̀.” Àwọn ọkùnrin náà yí padà, wọ́n sì ń lọ sí ìhà Sodomu. Ṣùgbọ́n Abrahamu dúró níbẹ̀ níwájú OLÚWA. Nígbà náà ni Abrahamu súnmọ́ ọ̀dọ̀ OLÚWA, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa olódodo ènìyàn àti ènìyàn búburú run papọ̀ bí?” “Bí ó bá ṣe pé Ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, Ìwọ yóò ha run ún, Ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà? Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú, Ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tọ́ bi?” OLÚWA wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta (50) olódodo ní ìlú Sodomu, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tiwọn.” Abrahamu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú OLÚWA, èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú, bí ó bá ṣe pe olódodo márùn-dínláàádọ́ta (45) ni ó wà nínú ìlú, Ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?” OLÚWA dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùn-dínláàádọ́ta nínú rẹ̀.” Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, “Bí ó bá ṣe pé ogójì (40) ni ńkọ́?” OLÚWA sì tún wí pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo ogójì nínú rẹ̀.” Abrahamu sì tún bẹ OLÚWA pé, “Kí Olúwa má ṣe bínú, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ̀rọ̀. Bí ó bá ṣe pé ọgbọ̀n (30) ni a rí níbẹ̀ ńkọ́?” OLÚWA dáhùn pé, “Bí mó bá rí ọgbọ̀n, Èmi kì yóò pa ìlú run.” Abrahamu wí pé, “Níwọ́n bí mo ti ní ìgboyà láti bá Olúwa sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀síwájú. Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ńkọ́?” OLÚWA sì dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa á run nítorí ogún ènìyàn náà.” Abrahamu sì wí pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú OLÚWA. Jẹ́ kí ń béèrè lẹ́ẹ̀kan si. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn mẹ́wàá ni ó jẹ́ olódodo ńkọ́?” OLÚWA wí pé, “Nítorí ènìyàn mẹ́wàá náà, Èmi kì yóò pa á run.”

Ní àṣálẹ́, àwọn angẹli méjì sì wá sí ìlú Sodomu, Lọti sì jókòó ní ẹnu ibodè ìlú. Bí ó sì ti rí wọn, ó sì dìde láti pàdé wọn, ó kí wọn, ó sì foríbalẹ̀ fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ̀yin olúwa mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ yà sí ilé ìránṣẹ́ yín kí ẹ sì wẹ ẹsẹ̀ yín, kí n sì gbà yín lálejò, ẹ̀yin ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti máa bá ìrìnàjò yín lọ.” Wọ́n sì wí pé, “Rárá o, àwa yóò dúró ní ìgboro ní òru òní.” Ṣùgbọ́n Lọti rọ̀ wọ́n gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n gbà láti bá a lọ sì ilé. Ó sì ṣe àsè fún wọn, ó sì dín àkàrà aláìwú fún wọ́n, wọ́n sì jẹ. Ṣùgbọ́n kí ó tó di pé wọ́n lọ sùn, àwọn ọkùnrin ìlú Sodomu tọmọdé tàgbà yí ilé náà ká. Wọ́n pe Lọti pé, “Àwọn ọkùnrin tí ó wọ̀ sí ilé rẹ lálẹ́ yìí ńkọ́? Mú wọn jáde fún wa, kí a le ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn.” Lọti sì jáde láti pàdé wọn, ó sì ti ìlẹ̀kùn lẹ́yìn rẹ̀ bí ó ti jáde. Ó sì wí pé; “Rárá, ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe ṣe ohun búburú yìí, kíyèsi i, mo ní ọmọbìnrin méjì tí kò mọ ọkùnrin rí, ẹ jẹ́ kí n mú wọn tọ̀ yín wá kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ fẹ́ pẹ̀lú wọn. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ibi kan nítorí wọ́n wá wọ̀ lábẹ́ ààbò ní ilé mi.” Wọ́n sì wí fún pé, “Bì sẹ́yìn fún wa. Èyí yìí wá ṣe àtìpó láàrín wa, òun sì fẹ́ ṣe onídàájọ́! Aburú tí a ó fi ṣe ọ́ yóò pọ̀ ju tí wọn lọ.” Wọn rọ́ lu Lọti, wọ́n sì súnmọ́ ọn láti fọ́ ìlẹ̀kùn. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà nawọ́ fa Lọti wọlé, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn. Wọ́n sì bu ìfọ́jú lu àwọn ọkùnrin tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà ilé náà, àti èwe àti àgbà: wọ́n kò sì rí ẹnu-ọ̀nà mọ́.

Àwọn ọkùnrin náà sì wí fún Lọti pé, “Ǹjẹ́ ó ní ẹlòmíràn ní ìlú yìí bí? Àna rẹ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí ẹnikẹ́ni tí ìwọ ní ní ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò ní ibí yìí, nítorí a ó pa ìlú yìí run, nítorí igbe iṣẹ́ búburú wọn ń dí púpọ̀ níwájú OLÚWA, OLÚWA sì rán wa láti pa á run.” Nígbà náà ni Lọti jáde, ó sì wí fún àwọn àna rẹ̀ ọkùnrin tí ó ti bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe kánkán, kí ẹ jáde ní ìlú yìí, nítorí OLÚWA fẹ́ pa ìlú yìí run!” Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ wọ̀nyí rò pé àwàdà ló ń ṣe. Ní àfẹ̀mọ́júmọ́, àwọn angẹli náà rọ Lọti pé, “Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìn-ín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Nígbà tí ó ń jáfara, àwọn ọkùnrin náà nawọ́ mú un lọ́wọ́, wọ́n sì nawọ́ mú aya rẹ̀ náà lọ́wọ́ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì mú wọn jáde sẹ́yìn odi ìlú, nítorí OLÚWA ṣàánú fún wọn. Ní kété tí wọ́n mú wọn jáde sẹ́yìn odi tán, ọ̀kan nínú wọn wí pé, “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe wo ẹ̀yìn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó má ṣe dúró ní gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀! Sá àsálà lọ sí orí òkè, kí ìwọ ó má ba ṣègbé!”

Nígbà náà ni OLÚWA rọ̀jò iná àti Sulfuru (òkúta iná) sórí Sodomu àti Gomorra—láti ọ̀run lọ́dọ̀ OLÚWA wá.

Ṣùgbọ́n aya Lọti bojú wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ́n iyọ̀.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọkùnrin lòpọ̀ bí ìgbà tí ènìyàn ń bá obìnrin lòpọ̀: ìríra ni èyí jẹ́. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀ kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́. Obìnrin kò sì gbọdọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀, ohun tó lòdì ni.

“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin mìíràn lòpọ̀ bí wọ́n ti í bá obìnrin lòpọ̀: àwọn méjèèjì ti ṣe ohun ìríra: pípa ni kí ẹ pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

Obìnrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, tàbí kí ọkùnrin wọ aṣọ obìnrin, nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó ṣe èyí.

Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹyin kò ti kà á pé ‘ẹni tí ó dá wọn ní ìgbà àtètèkọ́ṣe, Ọlọ́run dá wọn ni ti akọ ti abo.’ Ó sì wí fún un pé, ‘Nítorí ìdí èyí ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’ Wọn kì í túnṣe méjì mọ́, ṣùgbọ́n ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run bá ti so ṣọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà wọ́n.”

Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo. Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì fi ara mọ́ aya rẹ̀. Òun àti ìyàwó rẹ̀ yóò di ara kan náà. Nítorí náà, wọn kì í túnṣe méjì mọ́ bí kò ṣe ẹyọ ọ̀kan ṣoṣo. Nítorí náà ohun ti Ọlọ́run bá sọ dọ̀kan, ki ẹnikẹ́ni máa ṣe yà wọ́n.”

Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ń bẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”

Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,

Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́. Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín. Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́: nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ ń yí ìṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tí ó tọ̀nà, sí èyí tí kò tọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìbálòpọ̀ obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí. Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe: Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ a fi-ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-banijẹ́. Asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, akórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgbọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.

Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìṣòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jesu Kristi Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa.

Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá wọn àti àwọn apànìyàn, fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro.

Nítorí pé bi Ọlọ́run kò bá dá àwọn angẹli si nígbà tí wọn ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ti ó sọ wọ́n sí ìsàlẹ̀ ọ̀run àpáàdì tí ó sì fi wọ́n sínú ọ̀gbun òkùnkùn biribiri nínú ìfipamọ́ títí dé ìdájọ́. Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Noa mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn. Tí ó sọ àwọn ìlú Sodomu àti Gomorra di eérú, nígbà tí ó fi ìparun pátápátá dá wọn lẹ́bi, tí ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run. Tí ó sì yọ Lọti olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí ìwà ẹ̀gbin àwọn ènìyàn láìlófin bà nínú jẹ́; (nítorí ọkùnrin olóòtítọ́ náà bí ó ti ń gbé àárín wọn, tí ó ń rí, tí ó sì ń gbọ́, lójoojúmọ́ ni ìwà búburú wọn ń bá ọkàn òtítọ́ rẹ̀ jẹ́) Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdánwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè. Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo.

Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.

Àti àwọn angẹli tí kò tọ́jú ipò ọlá wọn, ṣùgbọ́n tí wọn fi ipò wọn sílẹ̀, àwọn tí ó pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n àìnípẹ̀kun ní ìsàlẹ̀ òkùnkùn de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá nì. Àní bí Sodomu àti Gomorra, àti àwọn ìlú agbègbè wọn, ti fi ara wọn fún àgbèrè ṣíṣe, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé ará àjèjì lẹ́yìn, àwọn ni ó fi lélẹ̀ bí àpẹẹrẹ, àwọn tí ó ń jìyà iná àìnípẹ̀kun. Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjòyè, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búburú sí àwọn ọlọ́lá.

Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fi iná àti sulfuru jó: èyí tí i ṣe ikú kejì.”

Yoruba - Yorùbá - YO

YCB'17 - Bibeli Mimo Ni Ede Yoruba Ode Oni - 2017

This Bible text is from Biblica Open Yoruba Contemporary Bible 2017
https://open.bible/bibles/yoruba-biblica-text-bible/
provided by: Biblica Inc, available by Creative Commons CC-BY-SA-4.0,
and this new compilation is shared as www.creativecommons.org/licenses/by-sa/4.0.
Languages are made available to you by www.ipedge.net