02 – Ọlọ́run
Awọn wọnyi ni awọn ọrọ mimọ ti Ọlọrun Olodumare.
A ko nifẹ si awọn ọrọ ti awọn eniyan.
Fun ẹnikẹni ti o ba fẹràn Ọlọrun ... Eyi ni ohun ti Ọlọrun sọ nipa: Ọlọ́run.
Awọn wọnyi ni awọn ọrọ mimọ ti Ọlọrun Olodumare.
A ko nifẹ si awọn ọrọ ti awọn eniyan.
Fun ẹnikẹni ti o ba fẹràn Ọlọrun ... Eyi ni ohun ti Ọlọrun sọ nipa: Ọlọ́run.
“Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.”
”“Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé tẹmpili tí a fi ọwọ́ kọ́;
”Kò sí ẹ̀dá kan tí kò farahàn níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni ó wà níhòhò tí a sì ṣípáyà fún ojú rẹ̀, níwájú ẹni tí àwa yóò jíyìn.
”Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé.
”Ní ìgbà tí Abramu di ẹni ọ̀kàn-dínlọ́gọ́rùnún (99) ọdún, OLÚWA farahàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai), máa rìn níwájú mi, kí o sì jẹ́ aláìlábùkù.
”Mose sì wí fún Ọlọ́run pé, “Bí mo bá tọ àwọn ará Israẹli lọ tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ tí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn ní ìgbà náà?” Ọlọ́run sì sọ fún Mose pé, “ÈMI NI TI Ń JẸ́ ÈMI NI. Èyí ni ìwọ yóò sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘ÈMI NI ni ó rán mi sí i yín.’ ” Ọlọ́run sì wí fún Mose pẹ̀lú pé, “Báyìí ni kí ìwọ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba yín; Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu; ni ó rán mi sí i yín.’ “Èyí ni orúkọ Mi títí ayérayé, orúkọ ti ẹ ó fi máa rántí Mi láti ìran dé ìran.
”OLÚWA ni agbára àti orin mi; òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga. Ológun ni OLÚWA, OLÚWA ni orúkọ rẹ,
”“Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, OLÚWA, pọ̀ ní agbára. Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, OLÚWA, fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú.
”Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “OLÚWA, OLÚWA, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́, Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1,000), ó sì ń dáríjì àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń ṣọ̀tẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.”
”Ẹ má ṣe sin ọlọ́run mìíràn, nítorí OLÚWA, orúkọ ẹni ti ń jẹ́ Òjòwú, Ọlọ́run owú ni.
”Ṣùgbọ́n nítòótọ́ bí mo ti wà láààyè, gbogbo ayé yóò kún fún ògo OLÚWA.
”Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà. Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é? Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu un ṣẹ?
”Torí pé iná ajónirun ni OLÚWA Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni.
”A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé OLÚWA ni Ọlọ́run. Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀. Ó jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, láti kọ́ ọ yín. Ní ayé, ó fi iná ńlá rẹ̀ hàn yín, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárín iná wá,
”Gbọ́ ìwọ Israẹli, OLÚWA Ọlọ́run wa, OLÚWA kan ni.
”Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé OLÚWA Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olóòtítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ni yóò san ẹ̀san fún ní gbangba nípa pípa wọ́n run; kì yóò sì jáfara láti san ẹ̀san fún àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ní gbangba.
”Torí pé OLÚWA Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
”Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé, gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo. Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan, Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.
”Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ, àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà. Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ, ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’
”“Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi OLÚWA; kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ; kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.
”“Ṣùgbọ́n nítòótọ́, Ọlọ́run yóò máa gbé ayé bí? Ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò le gbà ọ́. Kí a má sọ pé ilé yìí tí mo kọ́ fún ọ!
”Ṣùgbọ́n OLÚWA ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀.
”Fi ọpẹ́ fún OLÚWA, nítorí tí ó dára; ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé.
”“Àti ìwọ, ọmọ mi Solomoni, rántí Ọlọ́run baba à rẹ, kí o sì sìn ín pẹ̀lú tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfọkànsí pẹ̀lú ọkàn tí ó pé, nítorí OLÚWA ṣàwárí gbogbo ọkàn ó sì mọ gbogbo èrò. Tí ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i; ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ títí láé.
”Tìrẹ OLÚWA ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn àti ọláńlá àti dídán, nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ. Tìrẹ OLÚWA ni ìjọba; a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo. Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ; ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan. Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti láti fi agbára fún ohun gbogbo.
”O sì wí pé: “OLÚWA, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú.
”Ìwọ OLÚWA, Ọlọ́run Israẹli, ìwọ jẹ́ olódodo! Àwa ìgbèkùn tí ó ṣẹ́kù bí ó ti rí lónìí. Àwa dúró níwájú rẹ nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí èyí ẹnikẹ́ni nínú wa kò lè dúró níwájú rẹ”.
”Ìwọ nìkan ni OLÚWA. Ìwọ ni ó dá ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù pẹ̀lú gbogbo ogun wọn, ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ìwọ sì pa gbogbo wọn mọ́ láàyè, ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́.
”“Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí? Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olódùmarè dé bi?
”“Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo, àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
”Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín; Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
”Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́, Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́.
”Fún adarí orin. Ti Dafidi. Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé, “Ko sí Ọlọ́run.” Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú; kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere. OLÚWA sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá lórí àwọn ọmọ ènìyàn bóyá ó le rí ẹni tí òye yé, ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run. Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́; kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.
”Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.
”Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run; Àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
”Saamu ti Dafidi. OLÚWA ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
”Ohùn OLÚWA ní agbára; ohùn OLÚWA kún fún ọláńlá.
”OLÚWA wò láti ọ̀run wá; Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn. Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́ Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé
”Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́, wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn; ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú, nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.
”Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé, ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu! Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí; Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.
”Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú rẹ, kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.
”Dá mí lóhùn, OLÚWA, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ; nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.
”Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé; kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀. Àmín àti Àmín.
”Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, OLÚWA, ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́,
”Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, OLÚWA: kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá yóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, OLÚWA; wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀. Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu; ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.
”Ṣùgbọ́n ìwọ, OLÚWA, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere, Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
”Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ: ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ síwájú rẹ.
”Kí a tó bí àwọn òkè ńlá àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé, láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.
”Nítorí pé ìwọ, OLÚWA, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.
”OLÚWA jẹ ọba; jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.
”Gbígbéga ni OLÚWA Ọlọ́run wa kí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀ nítorí OLÚWA Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.
”Nítorí tí OLÚWA pọ̀ ní oore ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé; àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.
”Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà; gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ. Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn wọn yóò sì di àpatì. Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀, ọdún rẹ kò sì ní òpin.
”OLÚWA ni aláàánú àti olóore, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
”Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.
”Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́ OLÚWA ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n. OLÚWA ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run, ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo.
”Yin OLÚWA, ìwọ ọkàn mi. OLÚWA Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ; ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ. Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ; ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní
”Ẹ fi ọpẹ́ fún OLÚWA, nítorí tí ó ṣeun; nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
”OLÚWA ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
”Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run: tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú.
”OLÚWA ṣe ohunkóhun tí ó wù ú, ní ọ̀run àti ní ayé, ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo.
”Ẹ fi ọpẹ́ fún OLÚWA nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
”Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
”Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
”Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
”Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ? Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ? Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀; bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
”Títóbi ni OLÚWA. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀: kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.
”Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo, èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.
”Olóore-ọ̀fẹ́ ni OLÚWA àti aláàánú ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.
”OLÚWA jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá. OLÚWA wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
”Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé. Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa OLÚWA, tú àwọn oǹdè sílẹ̀ (ẹlẹ́wọ̀n)
”Ó ka iye àwọn ìràwọ̀ ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
”Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
”Ojú OLÚWA wà níbi gbogbo, Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.
”Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀? Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀? Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ? Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀? Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀? Sọ fún mi bí o bá mọ̀.
”Wọ inú àpáta lọ, fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀ kúrò nínú ìpayà OLÚWA, àti ògo ọláńlá rẹ̀!
”Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”
”OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni Ẹni tí ìwọ yóò kà sí mímọ́, Òun ni kí o bẹ̀rù Òun ni kí àyà rẹ̀ fò ọ́,
”Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa, ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. A ó sì máa pè é ní: Ìyanu Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà.
”Ẹ̀mí OLÚWA yóò sì bà lé e ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù OLÚWA
”Síbẹ̀síbẹ̀ OLÚWA sì fẹ́ ṣíjú àánú wò ọ́; ó dìde láti ṣàánú fún ọ. Nítorí OLÚWA jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é!
”Nítorí OLÚWA ni onídàájọ́ wa, OLÚWA ni onídàájọ́ wa, OLÚWA òun ni ọba wa; òun ni ẹni tí yóò gbà wá là.
”Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí; gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò tí kò tó ohun tí kò sí. Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé? Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀?
”Òun jókòó lórí ìtẹ́ ní òkè òbírí ilẹ̀ ayé, àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata. Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà, ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.
”Ìwọ kò tí ì mọ̀? Ìwọ kò tí ì gbọ́? OLÚWA òun ni Ọlọ́run ayérayé, Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé. Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀, àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀.
”“Èmi ni OLÚWA; orúkọ mi nìyìí! Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn tàbí ìyìn mi fún ère òrìṣà.
”“Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLÚWA wí, “Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́ tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà. Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá, tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi. Èmi, àní Èmi, Èmi ni OLÚWA, yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
”“Ohun tí OLÚWA wí nìyìí ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun: Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn, lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan.
”“Ohun tí OLÚWA wí nìyìí Olùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́ láti inú ìyá rẹ wá: “Èmi ni OLÚWA tí ó ti ṣe ohun gbogbo tí òun nìkan ti na àwọn ọ̀run tí o sì tẹ́ ayé pẹrẹsẹ òun tìkára rẹ̀,
”tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀ kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi. Èmi ni OLÚWA, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́. Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn mo mú àlàáfíà wá, mo sì dá àjálù; Èmi OLÚWA ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.
”Nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA wí— ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run, Òun ni Ọlọ́run; ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé, Òun ló ṣe é; Òun kò dá a láti wà lófo, ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀— Òun wí pé: “Èmi ni OLÚWA, kò sì ṣí ẹlòmíràn.
”Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀. Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́, ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe? Kì í ha á ṣe Èmi, OLÚWA? Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi, Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà; kò sí ẹlòmíràn àfi èmi. “Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là, ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé; nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn.
”Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́; Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn; Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi. Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá. Mo wí pé: Ète mi yóò dúró, àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.
”Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀ Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ; a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
”“Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín, tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,” ni OLÚWA wí. “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ àti èrò mi ju èrò yín lọ.
”Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́: “Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.
”Báyìí ni OLÚWA wí: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi, Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà? Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?
”Ṣùgbọ́n OLÚWA ni Ọlọ́run tòótọ́, òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé. Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì; orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀.
”Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀, ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀.
”“Nítorí náà, Èmi yóò kọ́ wọn ní àkókò yìí, Èmi yóò kọ́ wọn pẹ̀lú agbára àti títóbi mi; nígbà náà ni wọn ó mọ orúkọ mi ní OLÚWA.
”Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sápamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan, kí èmi má ba a rí?” ni OLÚWA wí. “Ǹjẹ́ èmi kò ha a kún ọ̀run àti ayé bí?” ni OLÚWA wí.
”OLÚWA ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé: “Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin; mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín,
”Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀ tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ OLÚWA,’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,” ni OLÚWA wí. “Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì, èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”
”“Háà! OLÚWA Olódùmarè, ìwọ tí o dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú títóbi agbára rẹ àti gbogbo ọ̀rọ̀ apá rẹ. Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ láti ṣe. O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn. Ọlọ́run títóbi àti alágbára, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ.
”“Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run gbogbo ẹran-ara. Ǹjẹ́ ohun kan ha a ṣòro fún mi bí?
”Daniẹli wí pé: “Ọpẹ́ ni fún orúkọ Ọlọ́run láé àti láéláé; tirẹ̀ ni ọgbọ́n àti agbára Ó yí ìgbà àti àkókò padà; ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò. Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye. Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àṣírí hàn; ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùn àti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà
”Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé. Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú.
”àní OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; OLÚWA ni orúkọ ìrántí rẹ̀
”Ẹni tí ó dá àwọn òkè tí ó dá afẹ́fẹ́ tí ó sì fi èrò rẹ̀ hàn sí ènìyàn, ẹni tí ó yípadà sí òkùnkùn tí ó sì tẹ ibi gíga ayé. OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
”Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san. OLÚWA ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú OLÚWA ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ OLÚWA lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára; OLÚWA kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà. Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì, Ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.
”Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo OLÚWA, bí omi ti bo Òkun.
”OLÚWA Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là. Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀; Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”
”Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, ẹ má ṣe búra rárá: ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni. Tàbí fi ayé búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerusalẹmu, nítorí olórí ìlú ọba Ńlá ni.
”Nítorí náà, ẹ jẹ́ pípé, gẹ́gẹ́ bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.
”“Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín,
”Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò, Ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi. Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’
”Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Mo yìn ọ Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, nítorí ìwọ ti fi òtítọ́ yìí pamọ́ fún àwọn tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti amòye, Ìwọ sì ti fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.
”Ṣùgbọ́n Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ni èyí ṣòro fún; ṣùgbọ́n fún Ọlọ́run ohun gbogbo ni ṣíṣe.”
”‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run òkú, ṣùgbọ́n tí àwọn alààyè.”
”“Ṣùgbọ́n nígbà ti Ọmọ Ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn angẹli rẹ̀ nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo ní ọ̀run. Gbogbo orílẹ̀-èdè ni a ó kójọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn ayé sí ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn ṣe é ya àgùntàn kúrò lára àwọn ewúrẹ́.
”Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi. Nítorí náà, Ẹ lọ, ẹ sọ wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitiisi wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́.
”Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ní èyí kò ṣe é ṣe fún ṣùgbọ́n kì í ṣe fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ni ṣíṣe fún Ọlọ́run.”
”Jesu dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé: ‘Gbọ́ Israẹli; Olúwa Ọlọ́run wa Olúwa kan ni.
”Jesu wá dáhùn, ó ni, “Èmi ni: Ẹ̀yin yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára. Ẹ̀yin yóò sì tún rí Ọmọ Ènìyàn tí ó ń bọ̀ láti inú àwọsánmọ̀ ojú ọ̀run.”
”Jesu sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jordani wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù;
”Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú.
”Ní wákàtí kan náà Jesu yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sá à yẹ ní ojú rẹ.
”Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ máa wí pé: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ yín. Kí ìjọba yín dé, ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe, bí i ti ọrun, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.
”Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà. Òun ni ó sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtètèkọ́ṣe. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá.
”“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.
”Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́
”Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”
”Jesu wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè: ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á; ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé.
”Èmi ni oúnjẹ ìyè.
”Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá: bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé: oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.”
”Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”
”Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rìí mi.”
”Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ìsàlẹ̀ wá; èmi ti òkè wá; ẹ̀yin jẹ́ ti ayé yìí; èmi kì í ṣe ti ayé yìí.
”Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kí Abrahamu tó wà, èmi ti wa.”
”“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.
”Jesu wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè:
”Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi. Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú: láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”
”Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín.
”Kò sí ẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.
”Nítorí náà bí ó ti wí fún wọn pé, “Èmi nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀.
”Wọn sì gbàdúrà, wọn sì wí pé, “Olúwa, ìwọ mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, fihàn wá nínú àwọn méjì yìí, èwo ni ìwọ yàn
”“Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́: gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé: “ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Irú ilé kín ní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi? ni Olúwa wí. Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi ìsinmi mi?
”“Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé tẹmpili tí a fi ọwọ́ kọ́;
”Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.
”Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.
”Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.
”A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run! Àwámárídìí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí, ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ! “Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa? Tàbí ta ni í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀?” “Tàbí ta ni ó kọ́ fi fún un, tí a kò sì san padà fún un?” Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo; ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín.
”Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run.
”Nítorí ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀, bí kò ṣe nínú agbára.
”Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.
”èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run. Ó gbéga ju gbogbo ìjọba, àti àṣẹ, àti agbára, àti òye àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú. Ọlọ́run sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ, èyí tí i ṣe ara rẹ̀, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹni tí ó kún ohun gbogbo ní gbogbo ọ̀nà.
”Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe ọlọ́rọ̀ ni àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa,
”Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan.
”Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó ṣe olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú ohun gbogbo.
”Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè.
”Nítorí náà, Ọlọ́run ti gbé e ga sí ipele tí ó ga jùlọ, ó sì ti fi orúkọ kan ti ó borí gbogbo orúkọ fún un Pé ni orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa wólẹ̀, ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé, Àti pé kí gbogbo ahọ́n jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi ni Olúwa, fún ògo Ọlọ́run Baba.
”Kristi ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá. Nítorí nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un. Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ ṣọ̀kan. Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí òun lè ní ipò tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun tìkára rẹ̀ lè máa gbé nínú rẹ̀.
”Nítorí nínú Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run gbé ní ara, ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kristi, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ.
”Ǹjẹ́ fún ọba ayérayé, àìdíbàjẹ́, àìrí, Ọlọ́run kan ṣoṣo, ni ọlá àti ògo wà fún láéláé. Àmín.
”Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí, tí a kò sì lè rí: ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀. Àmín.
”Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà, ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀: Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè.
”Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé, “Ìtẹ́ rẹ, Ọlọ́run, láé àti láéláé ni, ọ̀pá aládé òdodo ni ọ̀pá ìjọba rẹ.
”Kò sí ẹ̀dá kan tí kò farahàn níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni ó wà níhòhò tí a sì ṣípáyà fún ojú rẹ̀, níwájú ẹni tí àwa yóò jíyìn.
”Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó ni run ni.”
”Jesu Kristi ọ̀kan náà ni lánàá, àti lónìí, àti títí láé.
”Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà.
”Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wárìrì.
”Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn angẹli, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.
”Nítorí tí Ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, nígbà tí irú ohùn yìí fọ̀ sí i láti inú ògo ńlá náà wá pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
”Èyí sì ni iṣẹ́ tí àwa ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, tí àwa sì ń jẹ́ fún yín: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọ́run; ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì òkùnkùn rárá.
”Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọ́run: nítorí pé ìfẹ́ ni Ọlọ́run.
”Báyìí ni àwa mọ̀, tí a sì gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́. Ìfẹ́ ni Ọlọ́run; ẹni tí ó bá sì ń gbé inú ìfẹ́, ó ń gbé inú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀.
”Nítorí pé àwọn mẹ́ta ni ó ń jẹ́rìí. Ẹ̀mí, omi, àti ẹ̀jẹ̀: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wà ni ìṣọ̀kan.
”Àwa sì mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run dé, ó sì tí fi òye fún wa, kí àwa lè mọ ẹni tí í ṣe òtítọ́, àwa sì ń bẹ nínú ẹni tí í ṣe òtítọ́, àní, nínú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Èyí ni Ọlọ́run òtítọ́, àti ìyè àìnípẹ̀kun.
”tí Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n nìkan ṣoṣo, Olùgbàlà wa, ní ògo àti ọláńlá, ìjọba àti agbára, nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, kí gbogbo ayé tó wà, nísinsin yìí àti títí láéláé! Àmín.
”“Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.”
”“Àti sí angẹli ìjọ ni Sardi kọ̀wé: Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ni Ẹ̀mí méje Ọlọ́run, àti ìràwọ̀ méje wí pé: Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀, àti pé ìwọ ní orúkọ pé ìwọ ń bẹ láààyè, ṣùgbọ́n ìwọ ti kú.
”Lójúkan náà, mo sì wà nínú Ẹ̀mí: sì kíyèsi i, a tẹ́ ìtẹ́ kan ní ọ̀run, ẹnìkan sì jókòó lórí ìtẹ́ náà. Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jasperi àti kaneliani lójú. Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta emeradi lójú. Yí ìtẹ́ náà ká sì ni ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún mìíràn; àti lórí àwọn ìtẹ́ náà mo rí àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún jókòó, tí a wọ̀ ni aṣọ àlà; adé wúrà sì wà ni orí wọn. Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni ìró mọ̀nàmọ́ná àti ohùn àti àrá ti jáde wá: níwájú ìtẹ́ náà ni fìtílà iná méje sì ń tàn, èyí tí ń ṣe Ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run. Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni òkun bi dígí wà tí o dàbí kristali. Àti yí ìtẹ́ náà ká ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí ó kún fún ojú níwájú àti lẹ́yìn wọn. Ẹ̀dá kìn-ín-ní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kejì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹrin sì dàbí idì tí ń fò. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn àti lóru, láti wí pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè, tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá!” Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láààyè láé àti láéláé. Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé: “Olúwa àti Ọlọ́run, ìwọ ni o yẹ, láti gba ògo àti ọlá àti agbára: nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni wọn fi wà tí a sì dá wọn.”
”Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo.
”Gbogbo ẹ̀dá tí o sì ń bẹ ni ọ̀run, àti lórí ilẹ̀ ayé, àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ àti irú àwọn tí ń bẹ nínú Òkun, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé, “Kí a fi ìbùkún àti ọlá, àti ògo, àti agbára, fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti fún Ọ̀dọ́-àgùntàn náà láé àti láéláé.”
”Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”
”Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé: “Haleluya! Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.
”Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ: ọba àwọn ọba àti olúwa àwọn olúwa.
”Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀: nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn. Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i: nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀.
”Èmi ni Alfa àti Omega, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin.
”