25 – Owo
Awọn wọnyi ni awọn ọrọ mimọ ti Ọlọrun Olodumare.
A ko nifẹ si awọn ọrọ ti awọn eniyan.
Fun ẹnikẹni ti o ba fẹràn Ọlọrun ... Eyi ni ohun ti Ọlọrun sọ nipa: Owo.
Awọn wọnyi ni awọn ọrọ mimọ ti Ọlọrun Olodumare.
A ko nifẹ si awọn ọrọ ti awọn eniyan.
Fun ẹnikẹni ti o ba fẹràn Ọlọrun ... Eyi ni ohun ti Ọlọrun sọ nipa: Owo.
“Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le bàjẹ́ àti ibi tí àwọn olè lè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ. Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti jí í lọ. Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú.
”Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni. Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ. Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn. Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹ̀kùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa ni lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀.
”Jesu wò ó bí ọkùnrin náà ti ń lọ. Ó yípadà, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àní, ohun ìṣòro ni fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!” Ọ̀rọ̀ yìí ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu. Jesu tún sọ fún wọn pé, “Ẹyin ọmọ yóò tí ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run. Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ kan láti wọ ìjọba ọ̀run.” Ẹnu túbọ̀ ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sí i. Wọ́n béèrè wí pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni nínú ayé ni ó lè ní ìgbàlà?” Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ní èyí kò ṣe é ṣe fún ṣùgbọ́n kì í ṣe fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ni ṣíṣe fún Ọlọ́run.”
”Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Kaini mú ọrẹ wá fún OLÚWA nínú èso ilẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Abeli mú ẹran tí ó sanra wá fún OLÚWA nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn rẹ̀. OLÚWA sì fi ojúrere wo Abeli àti ọrẹ rẹ̀, ṣùgbọ́n OLÚWA kò fi ojúrere wo Kaini àti ẹbọ rẹ̀. Nítorí náà inú bí Kaini gidigidi, ojú rẹ̀ sì fàro.
”Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.
”Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀.
”Ìbùkún sì ni fún Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ, tí ó fi àwọn ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́.” Abramu sì fún un ní ìdámẹ́wàá ohun gbogbo.
”OLÚWA sì ti bùkún olúwa mi gidigidi. Ó sì ti di ọlọ́rọ̀, Ó sì ti fún un ní àgùntàn, màlúù, àti fàdákà àti wúrà, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin àti ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
”Nígbà náà ni ó kó ohun èlò wúrà àti fàdákà jáde àti aṣọ, ó sì fi wọ́n fún Rebeka, ó fún arákùnrin Rebeka àti ìyá rẹ̀ ní ẹ̀bùn olówó iyebíye pẹ̀lú.
”Ní ọdún náà, Isaaki gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà, ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́ọ̀rún ni ọdún kan náà, nítorí Ọlọ́run bùkún un. Ọkùnrin náà sì di ọlọ́rọ̀ púpọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ènìyàn ńlá. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Filistini ń ṣe ìlara rẹ̀.
”Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ́n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, nínú gbogbo ohun tí ìwọ ó fi fún mi, èmi yóò sì fi ìdámẹ́wàá rẹ̀ fún ọ.”
”Josẹfu pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà mọ́ bí iyanrìn Òkun; ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò ṣe àkọsílẹ̀ mọ́ nítorí, ó tayọ kíkà.
”Nígbà tí ìyàn sì ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà, Josẹfu ṣí inú àká, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ìyàn náà mú gan an ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè sì ń wá sí Ejibiti láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Josẹfu, nítorí ìyàn náà pọ̀ gidigidi káàkiri gbogbo ayé.
”Josẹfu sì pèsè oúnjẹ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi iye àwọn ọmọ wọn.
”Ṣùgbọ́n kò sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ náà nítorí tí ìyàn náà mú púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ Ejibiti àti ilẹ̀ Kenaani gbẹ nítorí ìyàn náà. Josẹfu gba gbogbo owó tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti àti Kenaani ní ìpààrọ̀ fún ti ọkà tí wọn ń rà, ó sì mú owó náà wá sí ààfin Farao. Nígbà tí owó wọn tán pátápátá ní Ejibiti àti Kenaani, gbogbo Ejibiti wá bá Josẹfu, wọ́n wí pé, “Fún wa ní oúnjẹ, èéṣe tí a ó fi kú ní ojú rẹ? Gbogbo owó wa ni a ti ná tán.” Josẹfu wí pé, “Ẹ mú àwọn ẹran ọ̀sìn yín wá, èmi yóò fún un yín ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran ọ̀sìn yín, níwọ̀n bí owó yín ti tan.” Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tọ Josẹfu wá, ó sì fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹṣin, àgùntàn, ewúrẹ́, màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó sì mú wọn la ọdún náà já, tí ó ń fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran ọ̀sìn wọn. Nígbà tí ọdún náà parí, wọn padà tọ̀ ọ́ wá ní ọdún tí ó tẹ̀lé, wọn wí pé, “A kò le fi pamọ́ fun olúwa wa pé níwọ̀n bí owó wa ti tan tí gbogbo ẹran ọ̀sìn wa sì ti di tirẹ̀ pé, kò sí ohunkóhun tókù fún olúwa wa bí kò ṣe ara wa àti ilẹ̀ wa. Èéṣe tí àwa yóò fi parun lójú rẹ, ra àwa tìkára wa àti ilẹ̀ wa ní ìpààrọ̀ fún oúnjẹ, àwa àti ilẹ̀ wa yóò sì wà nínú ìgbèkùn Farao. Fún wa ni oúnjẹ kí àwa kí ó má ba à kú, kí ilẹ̀ wa má ba à di ahoro.” Nítorí náà Josẹfu ra gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní Ejibiti fún Farao, kò sí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù ní Ejibiti tí kò ta ilẹ̀ tirẹ̀ nítorí ìyàn náà mú jù fún wọn. Gbogbo ilẹ̀ náà sì di ti Farao, Josẹfu sì sọ gbogbo ará Ejibiti di ẹrú láti igun kan dé èkejì
”Gbogbo àwọn obìnrin ni ó ní láti béèrè lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wọn àti gbogbo àwọn obìnrin ti ń gbé nínú ilé rẹ fún ohun fàdákà àti wúrà àti fún aṣọ, èyí ti ẹ̀yin yóò wọ̀ sí ọrùn àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin. Báyìí ni ẹ̀yin yóò sì kó ẹrù àwọn ará Ejibiti.”
”Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mose pé, “Èmi yóò rọ òjò oúnjẹ láti ọ̀run wá fún yín. Àwọn ènìyàn yóò sì máa jáde lọ ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti kó ìwọ̀nba oúnjẹ ti ó tó fún oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ní ọ̀nà yìí ni, èmi yóò fi dán wọn wò láti mọ bóyá wọn yóò máa tẹ̀lé ìlànà mi. Ní ọjọ́ kẹfà, ki wọn kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń ko ni ojoojúmọ́ tẹ́lẹ̀.”
”Mose sì wí fún wọ́n pé, “Kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe kó pamọ́ lára rẹ̀ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì.” Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mose; Wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mose bínú sí wọn.
”Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
”Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéjì rẹ.”
”Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi: ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín.
”“Ẹnikẹ́ni ti ó bá jí ènìyàn gbé, tí ó sì tà á tàbí tí ó fi pamọ́, pípa ni a ó pa á.
”“Bí ọkùnrin kan bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní fàdákà tàbí ohun èlò fún ìtọ́jú, ti wọ́n sì jí gbé lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí a bá mú irú olè bẹ́ẹ̀, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì. Ṣùgbọ́n ti a kò bá rí olè náà mú, baálé ilé náà yóò fi ara hàn níwájú ìdájọ́ láti jẹ́ kí a mọ̀ bí òun fúnrarẹ̀ ni ó gbé ohun ti ó sọnù náà.
”“Bí ìwọ bá yá ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn mi tí ìyà ń jẹ láàrín yín lówó, má ṣe dàbí ayánilówó, kí o má sì gba èlé.
”“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn mú ọrẹ wá fún mi, ìwọ yóò gba ọrẹ náà fún mi ni ọwọ́ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ti ọkàn rẹ bá fẹ́ láti fi fún mi.
”Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún OLÚWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún OLÚWA ní ti: “wúrà, fàdákà àti idẹ;
”Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ̀ wúrà: òrùka etí, òrùka àti ọ̀ṣọ́. Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún OLÚWA.
”Mose sì wí pé, “Àwọn ènìyàn mú púpọ̀ wá fún ṣíṣe iṣẹ́ náà ju bi OLÚWA ti pa á láṣẹ láti ṣe lọ.” Mose sì pàṣẹ, wọ́n sì rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo ibùdó: “Kí ọkùnrin tàbí obìnrin má ṣe ṣe ohun kankan bí ọrẹ fún ibi mímọ́ náà mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni a dá àwọn ènìyàn lẹ́kun láti mú un wá sí i, nítorí ohun tí wọ́n ti ní ti ju ohun tí wọn fẹ́ fi ṣe gbogbo iṣẹ́ náà lọ.
”“Bí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí OLÚWA nípa títan ẹnìkejì rẹ̀ lórí ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ tàbí tí wọ́n fi pamọ́ sí i lọ́wọ́, tàbí bí ó bá jalè, tàbí kí ó yan ẹnìkejì rẹ̀ jẹ, tàbí kí ó rí ohun tó sọnù he tó sì parọ́ tàbí kí ó búra èké, tàbí kí ó tilẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ kan, irú èyí tí ènìyàn lè ṣẹ̀.
”“ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣa ẹ̀ṣẹ́ (nǹkan oko tí ẹ ti gbàgbé tàbí tí ó bọ́ sílẹ̀). Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú ọgbà àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ parọ́. “ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ tan ara yín jẹ.
”“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ aládùúgbò rẹ jẹ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ jà á lólè. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dá owó iṣẹ́ alágbàṣe dúró di ọjọ́ kejì.
”“ ‘Ẹ má ṣe lo òṣùwọ̀n èké, nígbà tí ẹ bá ń díwọ̀n yálà nípa òṣùwọ̀n ọ̀pá, òṣùwọ̀n ìwúwo tàbí òṣùwọ̀n onínú. Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òṣùwọ̀n yín òṣùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òṣùwọ̀n wíwúwo, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òṣùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti.
”“ ‘Nígbà tí ẹ bá kórè ilẹ̀ yín ẹ má ṣe kórè dé ìkangun oko yín, tàbí kí ẹ padà gé èyí tí ó ṣẹ́kù sílẹ̀ nínú ìkórè yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn tálákà àti àwọn àlejò: Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.’ ”
”Ọdún mẹ́fà ni ìwọ ó fi gbin oko rẹ, ọdún mẹ́fà ni ìwọ ó fi tọ́jú ọgbà àjàrà rẹ, tí ìwọ ó sì fi kó èso wọn jọ. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje kí ilẹ̀ náà ní ìsinmi: ìsinmi fún OLÚWA. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ tọ́jú ọgbà àjàrà rẹ. Ẹ má ṣe kórè ohun tí ó tìkára rẹ̀ hù: ẹ má ṣe kórè èso àjàrà ọgbà tí ẹ ò tọ́jú. Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ ní ìsinmi fún ọdún kan
”“ ‘Ọdún ìsinmi méje èyí tí í ṣe ọdún mọ́kàn-dínláàdọ́ta ni kí ẹ kà. Lẹ́yìn náà, kí ẹ fọn fèrè ní gbogbo ibikíbi ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́. Ní ọjọ́ ètùtù yìí, ẹ fọn fèrè yíká gbogbo ilẹ̀ yín. Ẹ ya àádọ́ta ọdún náà sọ́tọ̀ kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo ẹni tí ń gbé ilẹ̀ náà. Yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Kí olúkúlùkù padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀. Àádọ́ta ọdún ni yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Ẹ má ṣe gbin ohunkóhun, ẹ kò sì gbọdọ̀ kórè ohun tí ó hù fúnrarẹ̀ tàbí kí ẹ kórè ọgbà àjàrà tí ẹ kò dá. Torí pé ọdún ìdásílẹ̀ ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún yín. Ẹ jẹ ohun tí ẹ mú jáde nínú oko náà.
”“ ‘Bí arákùnrin yín kan bá tálákà tí kò sì le è pèsè fún àìní ara rẹ̀: ẹ pèsè fún un bí ẹ ti ń ṣe fún àwọn àlejò tàbí àwọn tí ẹ gbà sílé: kí ó ba à le è máa gbé láàrín yín.
”Ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé kankan lọ́wọ́ rẹ̀: ẹ bẹ̀rù OLÚWA kí arákùnrin yín le è máa gbé láàrín yín. Ẹ má ṣe gba èlé lórí owó tí ẹ yá a bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ èrè lórí oúnjẹ tí ẹ tà fún un.
”“ ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà yálà tí èso ilẹ̀ ni, tàbí tí èso igi, ti OLÚWA ni. Mímọ́ ni fún OLÚWA.
”OLÚWA sọ fún Aaroni pé, “O kò ní ní ogún nínú ilẹ̀ wọn bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ní ní ìpín láàrín wọn, Èmi ni ìpín àti ogún rẹ láàrín àwọn ọmọ Israẹli. “Mó ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi àgọ́ ìpàdé
”OLÚWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Lefi kí o sì wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ìdámẹ́wàá bá ń wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ. O gbọdọ̀ mú ìdámẹ́wàá lára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ OLÚWA. A ó ka ọrẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkà irúgbìn láti ilẹ̀ ìpakà tàbí wáìnì láti fún wa. Báyìí ni ìwọ gan an náà yóò mú ọrẹ wa fún OLÚWA láti ara ìdámẹ́wàá tí ìwọ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Láti ara ìdámẹ́wàá ó gbọdọ̀ mú ọrẹ OLÚWA fún Aaroni àlùfáà. Ìwọ gbọdọ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí ìpín OLÚWA èyí tí ó dára jùlọ àti tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ lára gbogbo nǹkan tí wọ́n mú wá fún ọ.’
”Kín ni ó dé tí orúkọ baba wa yóò parẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkùnrin? Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrín àwọn arákùnrin baba wa.” Nígbà náà Mose mú ọ̀rọ̀ wọn wá síwájú OLÚWA. OLÚWA sì wí fún un pé, “Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi ń sọ tọ̀nà. Ogbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀. Tí kò bá ní ọmọbìnrin, fi ohun ìní rẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Tí kò bá ní arákùnrin, fi ogún ìní rẹ̀ fún arákùnrin baba rẹ̀. Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mose.’ ”
”Nítorí náà làwa ṣe mú ọrẹ ẹbọ wá fún OLÚWA, gbogbo ọrẹ wíwà tí a ní, wúrà, ẹ̀wọ̀n, àti júfù, àti òrùka-àmi, àti òrùka etí, àti ìlẹ̀kẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ọkàn an wa níwájú OLÚWA.”
”Kò sí ogún kankan tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà òmíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà ọmọ Israẹli gbọdọ̀ tọ́jú ilẹ̀ tí ó jogún.”
”Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
”Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéji rẹ, oko rẹ̀, àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéji rẹ.”
”Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá.
”Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀, nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i, nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbéga, tí ẹ̀yin yóò sì gbàgbé OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá, nínú oko ẹrú. Òun ni ó mú un yín la aginjù ẹlẹ́rù ńlá já, ilẹ̀ tí kò sí omi tí ó sì kún fún òǹgbẹ, pẹ̀lú àwọn ejò olóró ńláńlá àti àkéekèe. Ó mú omi jáde fún un yín láti inú àpáta. Ó fún yín ní manna láti jẹ nínú aginjù, ohun tí àwọn baba yín kò mọ̀ rí, kí Òun bá à le tẹ orí yín ba kí ó sì lè dán an yín wò, kí ó bá à lè dára fún un yín. Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.” Ṣùgbọ́n ẹ rántí OLÚWA Ọlọ́run yín tí ó fún un yín ní agbára àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí.
”Torí pé OLÚWA Ọlọ́run yín, ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa. Ọlọ́run alágbára, tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, tí kì í ṣe ojúsàájú kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àjèjì, Òun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn.
”Níbẹ̀ ni kí ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ yín wá, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àwọn ẹ̀jẹ́ yín, ọrẹ àtinúwá yín, àti àwọn àkọ́bí gbogbo màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín.
”Níbi tí OLÚWA Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá: àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ sísun, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLÚWA.
”Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àkọ́bí àwọn màlúù yín, tàbí ti ewúrẹ́ ẹ yín, ohunkóhun tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ àtinúwá, tàbí ẹ̀bùn pàtàkì ní ìlú ẹ̀yin tìkára yín.
”Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń fi ìdákan nínú mẹ́wàá nínú ìre oko yín lọ́dọọdún pamọ́ sí apá kan Ẹ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àti àkọ́bí àwọn màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín, níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín, ní ibi tí yóò yàn bí ibùgbé orúkọ rẹ̀. Kí ẹ lè kọ́ bí a ṣé ń bu ọlá fún OLÚWA Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.
”Ní òpin ọdún méje méje, ẹ̀yin gbọdọ̀ máa yọ̀ǹda àwọn gbèsè. Báyìí ni kí ẹ máa ṣe é: Gbogbo ẹni tí wọ́n jẹ ní gbèsè gbọdọ̀ fojú fo gbèsè tí ó ti yá ará Israẹli ènìyàn rẹ̀. Kò gbọdọ̀ béèrè ohun náà, lọ́dọ̀ ará Israẹli ènìyàn rẹ̀ tàbí lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀: nítorí pé a ti kéde àkókò OLÚWA láti fojú fo gbèsè. Ẹ lè béèrè ìsanpadà lọ́dọ̀ àjèjì. Ṣùgbọ́n ẹ fa igi lé gbèsè yówù kó jẹ́ tí arákùnrin yín jẹ yín.
”Nítorí pé OLÚWA Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín bí ó ti ṣèlérí, ẹ̀yin yóò sì máa yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ẹ kì yóò sì tọrọ. Ẹ ó ṣàkóso ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò sí orílẹ̀-èdè tí yóò lè jẹ ọba lé e yín lórí.
”Bí tálákà kan bá wà láàrín àwọn arákùnrin yín ní èyíkéyìí àwọn ìlú, ilẹ̀ náà tí OLÚWA yín yóò fún un yín. Ẹ má ṣe ṣe àìláàánú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe háwọ́ sí arákùnrin yín tí ó jẹ́ tálákà. Ṣùgbọ́n ẹ lawọ́ kí ẹ sì fi tọkàntọkàn yá wọn ní ohun tí wọ́n nílò.
”Ẹ ṣọ́ra kí èrò búburú kan má ṣe sí nínú àyà rẹ wí pé, “Ọdún keje tí í ṣe ọdún ìyọ̀ǹda gbèsè ti súnmọ́” nípa bẹ́ẹ̀, ojú rẹ a sì burú sí arákùnrin rẹ tálákà, tí ìwọ kò sì fun ní nǹkan, o kò sì fun ní nǹkan kan. Òun a si kígbe pe Olúwa nítorí rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ. Fún un tọkàntọkàn, láìsí ìkùnsínú, nítorí èyí, OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, àti gbogbo ìdáwọ́lé rẹ. A kò lè fẹ́ tálákà kù ní ilẹ̀ náà ní ìgbà gbogbo, mo pàṣẹ fún un yín láti lawọ́ sí àwọn arákùnrin yín, sí àwọn tálákà àti sí àwọn aláìní, ní ilẹ̀ ẹ yín.
”Nígbà náà ni kí ẹ ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run yín, nípa pípèsè ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún tí OLÚWA Ọlọ́run yín fún un yín.
”Kí olúkúlùkù ó mú ọrẹ wá bí agbára rẹ̀ ti tó, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún OLÚWA Ọlọ́run rẹ tí ó fi fún un ọ̀.
”Kò gbọdọ̀ kó aya jọ, kí ọkàn rẹ̀ má bá a yapa kúrò. Kò gbọdọ̀ kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.
”Wọn kì yóò ní ìní láàrín àwọn arákùnrin wọn; Ọlọ́run ni yóò jẹ́ ìní i tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.
”Má ṣe pa òkúta ààlà aládùúgbò rẹ dà tí aṣíwájú rẹ fi lélẹ̀ nínú ogún tí ó gbà nínú ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ni ní ìní.
”Ìwọ kò gbọdọ̀ ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá. Ìwọ lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Israẹli, nítorí kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.
”Bí a bá mú ọkùnrin kan tí ó jí ọ̀kan nínú arákùnrin rẹ̀ ní Israẹli gbé àti tí ó jí ọ̀kan nínú ẹrú tàbí kí ó tà á, ẹni tí ó jí ènìyàn gbé ní láti kú. Ẹ ní láti wẹ búburú kúrò láàrín yín.
”Nígbà tí ìwọ bá kórè èso àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.
”Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ OLÚWA ti fún mi wá.” Ìwọ yóò gbé agbọ̀n náà síwájú OLÚWA Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀. Ìwọ àti àwọn ọmọ Lefi àti àjèjì láàrín yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí OLÚWA ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ.
”Nígbà tí ìwọ bá ṣetán láti ya ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí o ti mú jáde ní ọdún kẹta sọ́tọ̀ sí apá kan. Ọdún ìdámẹ́wàá, ìwọ yóò fi fún ọmọ Lefi, àjèjì, aláìní baba àti opó, kí wọn kí ó lè jẹ ní àwọn ìlú rẹ, kí wọn sì yó. Nígbà náà ní kí o wí fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ pé, “Èmi ti mú ohun mímọ́ kúrò nínú ilé mi, èmi sì ti fi fún àwọn Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó, gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tí ìwọ ti pàṣẹ. Èmi kò yípadà kúrò nínú àṣẹ rẹ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbàgbé ọ̀kankan nínú wọn.
”OLÚWA yóò fi àlàáfíà fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, fún ọmọ inú rẹ, irú ohun ọ̀sìn rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fún ọ. OLÚWA yóò ṣí ọ̀run sílẹ̀, ìṣúra rere rẹ̀ fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àsìkò rẹ àti láti bùkún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. Ìwọ yóò yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ṣùgbọ́n ìwọ kò ní í yá lọ́wọ́ ẹnìkankan.
”Gbogbo fàdákà àti wúrà àti ohun èlò idẹ àti irin jẹ́ mímọ́ fún OLÚWA, wọ́n yóò wá sínú ìṣúra OLÚWA.”
”Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yà Lefi, Mose kò fi ogún fún un; OLÚWA, Ọlọ́run Israẹli, ní ogún wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.
”OLÚWA sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀; ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè. Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo: “Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti OLÚWA ni, ó sì ti gbé ayé ka orí wọn
”OLÚWA sì rán Natani sí Dafidi òun sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin méjì ń bẹ ní ìlú kan; ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ tálákà. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà sì ní àgùntàn àti màlúù lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tálákà náà kò sì ní nǹkan bí kò ṣe àgùntàn kékeré kan èyí tí ó sì ń tọ́: ó sì dàgbà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀; a máa jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀, a sí máa mu nínú ago rẹ̀, a sì máa dùbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀, ó sì dàbí ọmọbìnrin kan fún un. “Àlejò kan sì tọ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà wá, òun kò sì fẹ́ mú nínú àgùntàn rẹ̀, àti nínú màlúù rẹ̀: láti fi ṣe àlejò fún ẹni tí ó tọ̀ ọ́ wá: o sì mú àgùntàn ọkùnrin tálákà náà fi ṣe àlejò fún ọkùnrin tí ó tọ̀ ọ́ wá.” Ìbínú Dafidi sì ru gidigidi sí ọkùnrin náà; ó sì wí fún Natani pé, “Bí OLÚWA ti ń bẹ láààyè: ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkan yìí, kíkú ni yóò kú. Òun yóò sì san àgùntàn náà padà ní mẹ́rin mẹ́rin, nítorí tí ó ṣe nǹkan yìí àti nítorí tí kò ní àánú.”
”Ọba sì wí fún Arauna pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n èmi ó rà á ní iye kan lọ́wọ́ rẹ, bí ó ti wù kí ó ṣe; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi èyí tí èmi kò náwó fún, rú ẹbọ sísun sí OLÚWA Ọlọ́run mi.” Dafidi sì ra ibi ìpakà náà, àti àwọn màlúù náà ní àádọ́ta ṣékélì fàdákà. Dafidi sì tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ sí OLÚWA, ó sì rú ẹbọ sísun àti ti ìlàjà. OLÚWA sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, ààrùn náà sì dá kúrò ní Israẹli.
”Solomoni sì fi kìkì wúrà bo inú ilé náà, ó sì tan ẹ̀wọ̀n wúrà dé ojú ibi mímọ́ jùlọ, ó sì fi wúrà bò ó. Gbogbo ilé náà ni ó fi wúrà bò títí ó fi parí gbogbo ilé náà, àti gbogbo pẹpẹ tí ó wà níhà ibi mímọ́ jùlọ, ni ó fi wúrà bò.
”Ó sì tún fi wúrà tẹ́ ilẹ̀ ilé náà nínú àti lóde.
”Solomoni sì túnṣe gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ tí ń ṣe ti ilé OLÚWA pẹ̀lú: pẹpẹ wúrà; tábìlì wúrà lórí èyí tí àkàrà ìfihàn gbé wà; Ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà, márùn-ún ní apá ọ̀tún àti márùn-ún ní apá òsì, níwájú ibi mímọ́ jùlọ; ìtànná ewéko; fìtílà àti ẹ̀mú wúrà; Ọpọ́n kìkì wúrà, alumagaji fìtílà, àti àwokòtò, àti ṣíbí àti àwo tùràrí ti wúrà dáradára; àti àgbékọ́ wúrà fún ìlẹ̀kùn inú ilé ibi mímọ́ jùlọ àti fún ìlẹ̀kùn ilé náà, àní ti tẹmpili.
”Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni ń gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta (666) ó-lé-mẹ́fà tálẹ́ǹtì wúrà,
”Gbogbo ohun èlò mímu Solomoni ọba sì jẹ́ wúrà àti gbogbo ohun èlò ààfin igbó Lebanoni sì jẹ́ kìkì wúrà. Kò sí nǹkan kan tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni. Ọba sì ní ọkọ̀ Tarṣiṣi kan pẹ̀lú ọkọ̀ Hiramu ní Òkun. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ọkọ̀ Tarṣiṣi ń dé, tí ó ń mú wúrà àti fàdákà, eyín erin àti ìnàkí àti ẹyẹ-ológe wá. Solomoni ọba sì pọ̀ ní ọrọ̀ àti ní ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba ayé lọ.
”Bí ó sì ti ń lọ bù ú wá, ó ké sí i pé, “Jọ̀ ọ́, mú òkèlè oúnjẹ díẹ̀ fún mi wá lọ́wọ́ rẹ.” Obìnrin opó náà sì dá a lóhùn wí pé, “Bí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ti wà, èmi kò ní àkàrà: bí kò ṣe ìkúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú kólòbó. Èmi ń ṣa igi díẹ̀ jọ láti kó lọ ilé, kí èmi kí ó sì pèsè rẹ̀ fún mi àti fún ọmọ mi, kí àwa lè jẹ ẹ́: kí a sì kú.” Elijah sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Lọ, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí. Ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ṣe àkàrà kékeré kan fún mi nínú rẹ̀ ná, kí o sì mú fún mi wá, lẹ́yìn náà, kí o ṣe tìrẹ àti ti ọmọ rẹ. Nítorí báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ìkòkò ìyẹ̀fun náà kì yóò ṣófo, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró náà kì yóò gbẹ, títí di ọjọ́ tí OLÚWA yóò rọ òjò sí orí ilẹ̀.’ ” Ó sì lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Elijah ti sọ fún un. Oúnjẹ sì wà fún Elijah àti obìnrin náà àti ilé rẹ̀ ní ojoojúmọ́. Nítorí ìkòkò ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, kólòbó òróró náà kò gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó ti ipa Elijah sọ.
”Eliṣa dá a lóhùn pé, “Báwo ni èmi ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Sọ fún mi; kí ni ìwọ ní ní ilé rẹ?” “Ìránṣẹ́ rẹ kò ní ohunkóhun níbẹ̀ rárá,” Ó wí pé, “àyàfi òróró kékeré.” Eliṣa wí pé, “Lọ yíká kí o sì béèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn aládùúgbò fún ìkòkò òfìfo. Má ṣe béèrè fún kékeré. Nígbà náà, lọ sí inú ilé kí o sì pa lẹ́kun dé ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, dà òróró sínú gbogbo ìkòkò, gẹ́gẹ́ bí gbogbo rẹ̀ ti kún, kó o sí apá kan.” Ó sì fi sílẹ̀ lẹ́yìn náà ó ti ìlẹ̀kùn ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n gbé ìkòkò wá fún un ó sì ń dà á. Nígbà tí gbogbo ìkòkò náà kún, ó sọ fún ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ gbé òmíràn fún mi wá.” Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Kò sí ìkòkò tí ó kù mọ́.” Nígbà náà ni òróró kò dà mọ́. Ó sì lọ ó sì lọ sọ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì wí pé, “Lọ, ta òróró náà kí o sì san gbèsè rẹ. Ìwọ àti ọmọ rẹ kí ẹ máa sinmi lórí èyí tí ó kù.”
”Hesekiah fún un ní gbogbo fàdákà tí a rí nínú ilé OLÚWA àti nínú ìṣúra ilé ọba. Ní àkókò yìí Hesekiah ọba Juda ké wúrà tí ó wà ní ẹnu ìlẹ̀kùn ilé OLÚWA, kúrò àti ti òpó tí Hesekiah ọba Juda ti gbéró ó sì fi fún ọba Asiria.
”Gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti sọ Nebukadnessari kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé OLÚWA àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún OLÚWA. Ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn gbogbo Jerusalẹmu: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárùn-ún ún, àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù.
”Jabesi sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Israẹli wí pé, “Háà, Ìwọ yóò bùkún fún, ìwọ yóò sì mú agbègbè mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mi mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.
”Àwọn aládùúgbò láti ọ̀nà jíjìn gẹ́gẹ́ bí Isakari, Sebuluni àti Naftali gbé oúnjẹ wá lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, lórí Ràkunmí, àti lórí ìbáaka àti lórí màlúù, àní oúnjẹ ti ìyẹ̀fun, èso àjàrà gbígbẹ, èso ọ̀pọ̀tọ́, àkàrà dídùn, ọtí wáìnì, òróró, màlúù àti àgùntàn, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ wà ní Israẹli.
”“Èmi ti gba ìpọ́njú ńlá láti ṣe fún ilé OLÚWA ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún tálẹ́ǹtì fàdákà, ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta. Ìwọ sì tún le fi kún wọn.
”Pẹ̀lú gbogbo ìrànlọ́wọ́ mi èmi ti pèsè fún ilé Ọlọ́run mi wúrà fún iṣẹ́ wúrà, fàdákà fún ti fàdákà, idẹ fún ti idẹ, irin fún ti irin àti igi fún ti igi àti òkúta oníyebíye fún títọ́ rẹ̀, òkúta lóríṣìíríṣìí, àwọ̀ àti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà òkúta àti òkúta dáradára kan gbogbo wọ̀nyí ní iye púpọ̀. Yàtọ̀ fún èyí, nínú ìfọkànsìn mi sí ilé Ọlọ́run mi, èmí fi ìṣúra mi tìkára mi ti wúrà àti fàdákà fún ilé Ọlọ́run mi. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, èmi ti pèsè fún ilé mímọ́ ti OLÚWA yìí:
”Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún tálẹ́ǹtì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tálẹ́ǹtì fàdákà, ẹgbẹ̀rin méjì-dínlógún tálẹ́ǹtì idẹ àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin tálẹ́ǹtì irin. Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Ọlọ́run ní abẹ́ ìtọ́jú Jehieli ará Gerṣoni. Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí OLÚWA. Dafidi ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi.
”Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ; ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan. Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti láti fi agbára fún ohun gbogbo.
”“Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ.
”OLÚWA Ọlọ́run wa tí fi gbogbo púpọ̀ yìí tí àwa ti pèsè fún kíkọ́ ilé OLÚWA fun orúkọ, mímọ́ rẹ̀, ó wá láti ọwọ́ ọ̀ rẹ, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ tirẹ̀.
”Ọlọ́run wí fún Solomoni pé, “Níwọ́n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ ọkàn rẹ nìyí, tí ìwọ kò sì béèrè, fún ọrọ̀, ọlá tàbí ọ̀wọ̀, tàbí fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, àti nígbà tí ìwọ kò ti béèrè fún ẹ̀mí gígùn, ṣùgbọ́n tí ìwọ béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti ṣàkóso àwọn ènìyàn mi tí èmi fi ọ́ jẹ ọba lé lórí, Nítorí náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ọrọ̀, ọlá àti ọ̀wọ̀, irú èyí tí ọba ti ó wà ṣáájú rẹ kò ní, tí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ kò sì ní ní irú rẹ̀.”
”Ọba náà ṣe fàdákà àti wúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti wọ́pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti kedari ó pọ̀ bí igi sikamore ní àwọn ẹsẹ̀ òkè.
”Ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Lefi, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jì fún òfin OLÚWA. Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Israẹli fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkọ́so ti ọkà wọn, ọtí tuntun, òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan wá.
”Nísinsin yìí àwọn ènìyàn àti àwọn ìyàwó wọn kígbe ńlá sókè sí àwọn Júù arákùnrin wọn. Àwọn kan ń wí pé, “Àwa àti àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wa pọ̀; kí àwa kí ó le è jẹ, kí a sì wà láààyè, a gbọdọ̀ rí oúnjẹ.” Àwọn mìíràn wí pé, “Àwa ti fi oko wa ọgbà àjàrà wa àti ilé wa dógò kí àwa kí ó lè rí oúnjẹ ní àkókò ìyàn.” Síbẹ̀ àwọn mìíràn wí pé, “Àwa ní láti yá owó láti san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba lórí àwọn oko wa àti àwọn ọgbà àjàrà wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ ẹran-ara kan àti ẹ̀jẹ̀ kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ìlú wa tí àwọn ọmọkùnrin wa sì dára bí í tiwọn, síbẹ̀ àwa ní láti fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wa sí oko ẹrú. Díẹ̀ nínú àwọn ọmọbìnrin wa ti wà lóko ẹrú náà, ṣùgbọ́n àwa kò ní agbára, nítorí àwọn oko àti ọgbà àjàrà wa ti di ti ẹlòmíràn.” Èmi bínú gidigidi nígbà tí mo gbọ́ igbe wọn àti àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí. Mo rò wọ́n wò ní ọkàn mi mo sì fi ẹ̀sùn kan ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè. Mo sọ fún wọn pé, ẹ̀yin ń gba owó èlé lọ́wọ́ àwọn ará ìlú u yín! Nítorí náà mo pe àpéjọ ńlá láti bá wọn wí. Mo sì wí fún wọn pé: “Níbi tí àwa ní agbára mọ, àwa ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí a ti tà fún àwọn tí kì í ṣe Júù padà. Nísinsin yìí ẹ̀yìn ń ta àwọn arákùnrin yín, tí àwa sì tún ní láti rà wọ́n padà!” Wọ́n dákẹ́, nítorí wọn kò rí ohunkóhun sọ. Nítorí náà, mo tẹ̀síwájú pé, “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe kò dára. Kò ha yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run bí, láti yẹra fún ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí í ṣe ọ̀tá wa? Èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú ń yá àwọn ènìyàn lówó àti oúnjẹ. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a dáwọ́ owó èlé gbígbà yìí dúró! Ẹ fún wọn ní oko wọn, ọgbà àjàrà wọn, ọgbà olifi wọn àti ilé e wọn pẹ̀lú owó èlé tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ wọn ìdá ọgọ́rùn-ún owó, oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ wọn padà kíákíá.” Wọ́n wí pé, “Àwa yóò dá a padà. Àwa kì yóò sì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wọn mọ́. Àwa yóò ṣe bí o ti wí.” Nígbà náà mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè búra láti jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ti ṣe ìlérí. Mo sì gbọn ìṣẹ́tí aṣọ mi, mo wí pé, “Báyìí ni kí Ọlọ́run gbọn olúkúlùkù ènìyàn tí kò bá pa ìlérí yìí mọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ ìní i rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí a gbọn irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kí ó sì ṣófo!” Gbogbo ìjọ ènìyàn sì wí pé “Àmín,” wọ́n sì fi ìyìn fún OLÚWA. Àwọn ènìyàn náà sì ṣe bí wọ́n ti ṣe ìlérí.
”“Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti sun lọ́ríi pẹpẹ OLÚWA Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin. “Àwa tún gbà ojúṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé OLÚWA. “Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. “Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ, ti gbogbo èso àwọn igi àti ti wáìnì tuntun wa àti ti òróró wá sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí àwọn ọmọ Lefi ni ó ń gba ìdámẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́. Àlùfáà tí o ti ìdílé Aaroni wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí inú ilé ìṣúra. Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí. “Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”
”Ó sì ti pèsè yàrá ńlá kan fún un, èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀ fún ìtọ́jú ọrẹ ọkà, tùràrí àti àwọn ohun èlò tẹmpili àti ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró ti a fi lélẹ̀ bí ìlànà fún àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà àti pẹ̀lú gbogbo ọrẹ fún àwọn àlùfáà.
”Gbogbo Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí.
”Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ. Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn.
”wí pé: “Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá, ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ. OLÚWA fi fún ni, OLÚWA sì gbà á lọ, ìbùkún ni fún orúkọ OLÚWA.”
”Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde; Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá.
”Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti kẹ́hìndà wọ́n; Nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.
”Wọ́n n lo ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà.
”Nítòótọ́ ìwọ béèrè fún ààbò ni ọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí, ìwọ sì tú oníhòhò ní aṣọ wọn. Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu, ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa.
”Nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ, àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
”Wọ́n a sún ààmì ààlà ilẹ̀, wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n a sì bọ́ wọn. Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba lọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo. Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà, àwọn tálákà ayé a fi agbára sápamọ́. Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn, wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ; ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko, wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú. Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ, tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù. Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n, wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò. Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú, wọ́n sì gbà ọmọ tálákà nítorí gbèsè. Wọ́n rìn kiri ní ìhòhò láìní aṣọ; àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà,
”Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù ńlá fún mi, àti nítorí ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró. “Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi, tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi;’ Bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀, àti nítorí ọwọ́ mi dara lọ́pọ̀lọpọ̀;
”Mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ, nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?
”OLÚWA sì yí ìgbèkùn Jobu padà, nígbà tí ó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀; OLÚWA sì bùsi ohun gbogbo ti Jobu ní rí ní ìṣẹ́po méjì ohun tí ó ní tẹ́lẹ̀ rí
”Àti ní gbogbo ilẹ̀ náà, a kò rí obìnrin tí ó ní ẹwà bí ọmọ Jobu; baba wọ́n sì pínlẹ̀ fún wọn nínú àwọn arákùnrin wọn.
”Béèrè lọ́wọ́ mi, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ, òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.
”Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé, ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.
”Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀; Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn OLÚWA
”tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí ni a kì yóò mì láéláé.
”OLÚWA, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi, ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́. Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára; nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
”Saamu ti Dafidi. OLÚWA ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
”Ẹ bẹ̀rù OLÚWA, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́, nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
”Gbogbo egungun mi yóò wí pé, “Ta ni ó dàbí ì ìwọ OLÚWA? O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ, tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”
”Gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA, kí o sì máa ṣe rere; torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀. Ṣe inú dídùn sí OLÚWA; òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.
”Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà; síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ. Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni; a sì máa bùsi i fún ni.
”Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà, yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.
”Bí ó ṣe ti èmi ni, tálákà àti aláìní ni èmi, ṣùgbọ́n Olúwa ń ṣe ìrántí mi. Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi àti ìgbàlà mi; Má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́, ìwọ Ọlọ́run mi.
”Fún adarí orin. Saamu Dafidi. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní: OLÚWA yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú. OLÚWA yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́: yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀ kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
”Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn, tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn. Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀ padà tàbí san owó ìràpadà fún Ọlọ́run. Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
”“Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀, bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé, ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”
”Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára, tàbí gbéraga nínú olè jíjà, nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i, má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn.
”Nítorí yóò gba àwọn aláìní nígbà tí ó bá ń ké, tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú.
”Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba; ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára. Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní; gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.
”Nítorí OLÚWA Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà; OLÚWA fún ni ní ojúrere àti ọlá; kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.
”Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní; kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.
”Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀; òdodo rẹ̀ sì dúró láé.
”Ènìyàn rere fi ojúrere hàn, a sì wínni; ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.
”Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá. Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.
”Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni,
”OLÚWA yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ fi ìbùkún fún OLÚWA ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
”Kí ni èmi yóò san fún OLÚWA nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?
”Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́, ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.
”Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́; yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ.
”bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́. Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù OLÚWA, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.
”Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún OLÚWA, pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.
”Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀, ẹni tí ó tún ní òye sí i Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ. Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ; kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
”Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ, nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan. Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé, “Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,” nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.
”Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ, bí ìwọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì ènìyàn, bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté, Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹ níwọ̀n bí o ti kó ṣọ́wọ́ aládùúgbò rẹ: lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀; bẹ aládùúgbò rẹ dáradára Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́, tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá. Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo èsúró kúrò lọ́wọ́ ọdẹ, bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.
”Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á. Síbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà.
”Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ. Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo, ní ojú ọ̀nà òtítọ́, Mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.
”Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. OLÚWA kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́. Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà, ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀. Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.
”Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn, ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.
”Ètè olódodo jẹ́ ààyò fàdákà ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú kò níye lórí. Ètè olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye. Ìbùkún OLÚWA ń mú ọrọ̀ wá, kì í sì í fi ìdààmú sí i.
”OLÚWA kórìíra òṣùwọ̀n èké, ṣùgbọ́n òṣùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀.
”Ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ fún àlejò yóò rí ìyọnu, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onígbọ̀wọ́ yóò wà láìléwu. Obìnrin oníwà rere gba ìyìn ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.
”Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i; òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní. Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i; ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura. Àwọn ènìyàn a ṣẹ́ èpè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́ ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà. Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere ṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú; ṣùgbọ́n olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù.
”Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan, ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣe ọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.
”Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkan kan ẹlòmíràn díbọ́n bí i tálákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀. Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.
”Owó tí a fi ọ̀nà èrú kójọ yóò ṣí lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀díẹ̀ yóò pọ̀ sí i.
”Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.
”Kódà àwọn aládùúgbò tálákà kò fẹ́ràn rẹ̀ ṣùgbọ́n, ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀. Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní. Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í ṣìnà bí? Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbèrò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́. Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá, ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni.
”Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.
”Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.
”Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù OLÚWA sì wà ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu. Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà sàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra.
”Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè.
”Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ.
”Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ àti láti yan òye dípò o fàdákà!
”Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà. Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ, yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ. Iná ni a fi fọ́ Fàdákà àti wúrà Ṣùgbọ́n OLÚWA ló ń dán ọkàn wò.
”Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra, ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.
”Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú, ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.
”Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, OLÚWA ní ó yá yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.
”Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ, nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.
”Ìwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ OLÚWA kórìíra méjèèjì.
”Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀.
”Ogún tí a kójọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.
”Ètè àwọn olóye jásí èrè bí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá. Ìṣúra tí a kójọ nípasẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́ jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹ́kùn ikú.
”Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú, òun tìkára rẹ̀ yóò ké pẹ̀lú; ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́.
”Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di tálákà: ẹni tí ó fẹ́ ọtí wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀. Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó ìràpadà fún olódodo, àti olùrékọjá fún ẹni dídúró ṣinṣin. Ó sàn láti jókòó ní aginjù ju pẹ̀lú oníjà obìnrin àti òṣónú lọ. Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n; ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn n bà á jẹ́.
”Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé; nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe. Ó ń fi ìlara ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́: ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró.
”Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ, àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ. Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀: OLÚWA ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.
”Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán: ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà. Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún; nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.
”Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀, tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ, yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí. Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.
”Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè, nítorí OLÚWA yóò gbèjà wọn, yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.
”Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀nwọ́, tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè. Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi san, nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹni rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?
”Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀: ṣíwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ. Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí? Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀, ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run.
”Nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà; ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ.
”Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́ nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀; Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.
”oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi Òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè àti àìní bí olè.
”Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ ó dàbí èso wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà.
”Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú. Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí OLÚWA yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ.
”Nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.
”Ó sàn láti jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla. Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ẹ́ jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójútì baba rẹ̀. Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù ń kó jọ fún ẹlòmíràn, tí yóò ní àánú àwọn tálákà.
”Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀.
”Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun asán yóò kún fún òsì. Olóòtítọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ láìjìyà. Ojúsàájú ṣíṣe kò dára, síbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan. Ahun ń sáré àti là kò sì funra pé òsì dúró de òun. Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojúrere ni nígbẹ̀yìn ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ. Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè tí ó sì wí pé “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀” irú kan ni òun àti ẹni tí ń pa ni run.
”Ẹni tí ó ń fi fún tálákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun, ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún.
”Olódodo ń máa ro ọ̀rọ̀ tálákà, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kò sú sí i láti rò ó.
”Ẹni tí ó ń kó ẹgbẹ́, olè kórìíra ọkàn ara rẹ̀, ó ń gbọ́ èpè olóhun kò sì le è fọhùn.
”Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi; má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀, ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan, Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ kí ń sì wí pé, ‘Ta ni OLÚWA?’ Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalè kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.
”Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.” Ta ni ó le rí aya oníwà rere? Ó níye lórí ju iyùn lọ
”O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.
”Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńláńlá: Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀. Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn. Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà. Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ. Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀. Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀. Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́. N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn. Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi, èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi. Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní: gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn; ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni.
”Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító, ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún un.
”Ìhòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀, bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀.
”Síwájú sí, nígbà tí Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni ní ọrọ̀ àti ohun ìní, tí ó sì fún un lágbára láti gbádùn wọn, láti gba ìpín rẹ̀ kí inú rẹ̀ sì dùn sí iṣẹ́ rẹ—ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí.
”Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ọlá àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohunkóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfààní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Asán ni èyí, ààrùn búburú gbá à ni.
”Ẹ̀rín rínrín ni a ṣe àsè fún, wáìnì a máa mú ayé dùn, ṣùgbọ́n owó ni ìdáhùn sí ohun gbogbo.
”Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́, nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere bóyá èyí tàbí ìyẹn tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà.
”Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà, ìṣúra wọn kò sì ní òpin. Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin, kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin. Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn, èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe.
”láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn àti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi, Wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn. Wọ́n sì ń ja àwọn aláìní baba lólè.
”Ṣùgbọ́n ọlọ́lá ènìyàn a máa pète ohun ńlá àti nípa èrò rere ni yóò dúró.
”“Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ, ẹ wá sí ibi omi; àti ẹ̀yin tí kò ní owó; ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ! Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà láìsí owó àti láìdíyelé. Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn? Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu.
”Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri. Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó, àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn?
”àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn, nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn, àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan.
”Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán, ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀; ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ, sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá. Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani. Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá, wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́ tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn OLÚWA.
”Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ, dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ, àti irin dípò òkúta. Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹ àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.
”Kí ni ò ń ṣe, ìwọ tí o ti di ìjẹ tán? Ìwọ ìbá wọ ara rẹ ní aṣọ òdodo kí o sì fi wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn olólùfẹ́ rẹ kẹ́gàn rẹ wọ́n sì ń lépa ẹ̀mí rẹ.
”“Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba nǹkan kan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ.
”Ìwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀, tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé, àní àsìkò láti ké ọ kúrò!
”Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ; wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹ láti mú wọn wà láààyè. “Wò ó, OLÚWA, kí o sì rò ó, nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”
”“ ‘Wọn yóò dà fàdákà wọn sí ojú pópó, wúrà wọn yóò sì dàbí èérí fàdákà àti wúrà wọn kò ní le gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná OLÚWA. Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.
”“ ‘Wò ó, ẹ̀ṣẹ̀ tí Sodomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin ṣẹ̀ nìyìí: Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ gbéraga, wọ́n jẹ́ alájẹjù àti aláìbìkítà; wọn kò ran tálákà àti aláìní lọ́wọ́ Nítorí náà, mo mu wọn kúrò níwájú mi lójú mi gẹ́gẹ́ bi ìwọ ti rò ó, nítorí ìgbéraga àti àwọn ohun ìríra tí wọ́n ṣe.
”Kò sì ni ẹnikẹ́ni lára, ó sì sanwó fún onígbèsè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ìlérí fún un, kò fi ipá jalè ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì fi ẹ̀wù wọ àwọn tí ó wà ní ìhòhò. Ẹni tí kò fi fún ni láti gba ẹ̀dá, tàbí kò gba èlé tó pọ̀jù. Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ òtítọ́ láàrín ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀. Tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lóòtítọ́ àti lódodo. Ó jẹ́ olódodo, yóò yè nítòótọ́, ní OLÚWA Olódùmarè wí.
”Ó ni àwọn tálákà àti aláìní lára, ó ń fipá jalè, kì í dá padà gẹ́gẹ́ bí ìlérí, o gbójú sókè sí òrìṣà, ó sì ń ṣe ohun ìríra. Ó ń fi owó ya ni pẹ̀lú èlé, ó sì tún ń gba èlé tó pọ̀jù. Ǹjẹ́ irú ọkùnrin yìí wa le è yè bí? Òun kì yóò wá láààyè! Nítorí pé òun ti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, kíkú ni yóò kú, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wá lórí rẹ̀.
”Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀; ìwọ gba èlé lọ́pọ̀pọpọ̀ láti mú aláìṣòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ. Ìwọ sì ti gbàgbé èmi; ni OLÚWA Olódùmarè wí.
”Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìninilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára; nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídìí. Kò sì ṣí ìdájọ́ òdodo. “Èmi si wá ẹnìkan láàrín wọn, tí ìbá tún odi náà mọ́, tí ìbá dúró ní ibi tí ó ya náà níwájú mi fún ilẹ̀ náà, kí èmi má bá à parun: ṣùgbọ́n èmi kò rí ẹnìkan.
”Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ, ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ, àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà, nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ. Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ, ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, ọkàn rẹ gbé sókè, nítorí ọrọ̀ rẹ. “ ‘Nítorí náà èyí yìí ní OLÚWA Olódùmarè wí: “ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n, pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run. Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ, ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè; wọn yóò yọ idà wọn sí ọ, ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ, wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.
”Ìwọ yóò wí pé, “Èmi yóò gbé Ogun ti ilẹ̀ àwọn tí a kò fi odi yíká: Èmi yóò gbé ogun ti àwọn ènìyàn àlàáfíà tí a kò funra sí gbogbo wọn ń gbé ní àìsí odi, ní àìsí ẹnu-ọ̀nà òde àti àsígbè-irin. Èmi yóò mú ohun ọdẹ, èmi yóò sì kó ìkógun, èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sí ibi ìwólulẹ̀ ti a ti tún kọ́, àwọn ènìyàn tí a kójọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó ní ọrọ̀ nínú ẹran ọ̀sìn àti ẹrú, tí ó ń gbé ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ náà.” Ṣeba, Dedani àti àwọn oníṣòwò Tarṣiṣi àti gbogbo àwọn ọmọ kìnnìún wọn, yóò sọ fún un yín pé, “Ṣé ẹ̀yin wá fún ìkógun? Ṣé ẹ̀yin ti kó àwọn ogun yín jọ pọ̀ fún ìkógun, láti kó fàdákà àti wúrà lọ, láti kó ẹran ọ̀sìn àti ẹrú àti láti gba ọ̀pọ̀ ìkógun?” ’
”Bí Belṣassari ṣe ń mu wáìnì, ó pàṣẹ pé kí wọn kó kọ́ọ̀bù wúrà àti ti fàdákà wá, èyí tí Nebukadnessari baba rẹ̀ kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu, kí ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀ kí ó ba à le fi mu wáìnì. Wọ́n sì kó kọ́ọ̀bù wúrà àti fàdákà àti fàdákà èyí tí wọ́n kó jáde láti inú tẹmpili, ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀, sì fi mu wáìnì. Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń yin òrìṣà wúrà àti fàdákà, ti idẹ, irin, igi àti òkúta.
”Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú
”Oníṣòwò ń lo òṣùwọ̀n èké o fẹ́ràn láti rẹ́ ni jẹ. Efraimu gbéraga, “Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.”
”“Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín. Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòrò ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ àwọn ogun ńlá mi tí mo rán sí àárín yín. Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó ẹ ó sì yín orúkọ OLÚWA Ọlọ́run yín, ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò; ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé.
”Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀ o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà. Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó. Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́
”Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba, tí ẹ sì ń sọ tálákà di ilẹ̀. Tí ẹ ń wí pé, “Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí kí àwa bá à lè ta ọkà kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin kí àwa bá à le ta jéró?” Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á kí a sì fi òṣùwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ Kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn tálákà kí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìní kí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀.
”Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n, àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n. Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ lára àní ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀.
”“Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé, “ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i! Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà! Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’ Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì? Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́? Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.
”Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógun, àti ilé wọn yóò sì run. Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbé nínú ilé náà, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtí wáìnì láti inú rẹ̀.”
”Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọn kì yóò sì le gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú OLÚWA.” Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi iná ìjowú rẹ̀ parun, nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sí gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ayé.
”‘Tèmi ni fàdákà àti wúrà,’ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.
”Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi. OLÚWA sì wí fún mi pé, “Sọ ọ sí amọ̀kòkò.” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owó fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìṣúra ní ilé OLÚWA.
”“Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí? Síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe jà ọ́ ní olè?’ “Nípa ìdámẹ́wàá àti ọrẹ. Ríré ni a ó fi yín ré: gbogbo orílẹ̀-èdè yìí, nítorí ẹ̀yin ti jà mi lólè. Ẹ mú gbogbo ìdámẹ́wàá wá sí ilé ìṣúra, kí oúnjẹ bá à lè wà ní ilé mi, ẹ fi èyí dán mi wò,” ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, “kí ẹ sì wò bí èmi kò bá ní sí àwọn fèrèsé ọ̀run fún yin, kí èmi sì tú ìbùkún àkúnwọ́sílẹ̀ jáde fún yín, tó bẹ́ẹ̀ tí kì yóò sì ààyè láti gbà á.
”Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Maria ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ìṣúra wọn, wọ́n sì ta Jesu lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjìá.
”“Alábùkún fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.
”Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.
”Bí ẹnìkan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú. Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì. Fi fún ẹni tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń fẹ́ wín lọ́wọ́ rẹ, má ṣe mú ojú kúrò.
”“Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe iṣẹ́ rere yín níwájú àwọn ènìyàn nítorí kí a le rí yín, Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin kò ni èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín ní ọ̀run. “Nítorí náà, nígbà ti ẹ́ bá ti ń fún aláìní, ẹ má ṣe fi fèrè kéde rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgàbàgebè ti í ṣe ní Sinagọgu àti ní ìta gbangba; kí àwọn ènìyàn le yìn wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè tí wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń fi fún aláìní, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe, kí ìfúnni rẹ má ṣe jẹ́ mí mọ̀. Nígbà náà ni Baba rẹ̀, tí ó sì mọ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo, yóò san án fún ọ.
”Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí Ẹ dárí gbèsè wa jì wá, Bí àwa ti ń dáríji àwọn ajigbèsè wa,
”“Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le bàjẹ́ àti ibi tí àwọn olè lè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ. Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti jí í lọ. Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú.
”“Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.
”“Nítorí náà, mo wí fún yín, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ ó jẹ àti èyí tí ẹ ó mu; tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ ó wọ̀. Ṣé ẹ̀mí kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ tàbí ara ni kò ha ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ? Ẹ wo àwọn ẹyẹ ojú ọrun; wọn kì í gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kójọ sínú àká, síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí? Ta ni nínú gbogbo yín nípa àníyàn ṣíṣe ti ó lè fi ìṣẹ́jú kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀? “Kí ni ìdí ti ẹ fi ń ṣe àníyàn ní ti aṣọ? Ẹ wo bí àwọn lílì tí ń bẹ ní igbó ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. Bẹ́ẹ̀ ni mo wí fún yín pé, a kò ṣe Solomoni lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ bẹ́ẹ̀, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí ti a sì gbà sínú iná lọ́la, kò ha ṣe ni ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́ tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? Nítorí náà, ẹ má ṣe ṣe àníyàn kí ẹ sì máa wí pé, ‘Kí ni àwa yóò jẹ?’ Tàbí ‘Kí ni àwa yóò mu?’ Tàbí ‘Irú aṣọ wo ni àwa yóò wọ̀?’ Nítorí àwọn kèfèrí ń fi ìwọra wá àwọn nǹkan wọ̀nyí bẹ́ẹ̀ ni Baba yín ní ọ̀run mọ̀ dájúdájú pé ẹ ní ìlò àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba Ọlọ́run ná àti òdodo rẹ̀, yóò sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín pẹ̀lú. Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn ọ̀la, ọ̀la ni yóò ṣe àníyàn ara rẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.
”“Béèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin yóò sì rí; kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà, ẹni tí ó bá sì wà kiri ń rí, ẹni bá sì kànkùn ni a yóò ṣi sílẹ̀ fún.
”Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí í ṣe ènìyàn búburú bá mọ̀ bí a ti í fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòó mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ohun rere fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?
”Jesu dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”
”“Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín; Ẹ má ṣe mú àpò fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un.
”Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ago omi tútù fún ọ̀kan nínú àwọn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mu nítorí tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”
”Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́ọ̀rún, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ti ó gbìn.
”Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e; òun sì so èso òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n.”
”“Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko. Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́. Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà. “Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà. Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó ni iye lórí, ó lọ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀ láti le rà á.
”Èrè kí ni ó jẹ́ fún ènìyàn bí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi dípò ẹ̀mí rẹ̀?
”Nígbà tí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé Kapernaumu, àwọn agbowó òde tí ń gba owó idẹ méjì tó jẹ́ owó tẹmpili tọ Peteru wá wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ olùkọ́ yín ń san owó tẹmpili?” Peteru sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san.” Nígbà tí Peteru wọ ilé láti bá Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Jesu ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, Jesu bí i pé, “Kí ni ìwọ rò, Simoni? Ǹjẹ́ àwọn ọba ayé ń gba owó orí lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí lọ́wọ́ àwọn àlejò?” Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àwọn àlejò ni.” Jesu sì tún wí pé, “Èyí jẹ́ wí pé àwọn ọmọ onílẹ̀ kì í san owó òde? Síbẹ̀síbẹ̀, àwa kò fẹ́ mú wọn bínú. Nítorí náà, ẹ lọ sí etí Òkun, kí ẹ sì sọ ìwọ̀ sí omi. Ẹ mú ẹja àkọ́kọ́ tí ẹ kọ́ fà sókè, ẹ ya ẹnu rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì rí owó idẹ kan níbẹ̀, ki ẹ fi fún wọn fún owó orí tèmi àti tirẹ̀.”
”“Nítorí náà, ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan tí ó fẹ́ ṣe ìṣirò pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bí ó ti ń ṣe èyí, a mú ajigbèsè kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ẹgbàárùn-ún (10,000) tálẹ́ǹtì. Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà. “Nígbà náà ni ọmọ ọ̀dọ̀ náà wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ. ‘Ó bẹ̀bẹ̀ pé, mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san gbogbo rẹ̀ fún ọ.’ Nígbà náà, ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbèsè náà jì í. “Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó idẹ, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé, ‘san gbèsè tí o jẹ mí lójú ẹsẹ̀.’ “Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’ “Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. “Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè ọmọ ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbèsè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi. Kò ha ṣe ẹ̀tọ́ fún ọ láti ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣàánú fún ọ?’ Ní ìbínú, olówó rẹ̀ fi í lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ láti fi ìyà jẹ ẹ́, títí tí yóò fi san gbogbo gbèsè èyí ti ó jẹ ẹ́. “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run yóò sí ṣe sì ẹnìkọ̀ọ̀kan, bí ẹ̀yin kò bá fi tọkàntọkàn dárí ji àwọn arákùnrin yín.”
”Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
”Nígbà náà, ní Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.” Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ èyí, ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n béèrè pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha le là?” Ṣùgbọ́n Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ni èyí ṣòro fún; ṣùgbọ́n fún Ọlọ́run ohun gbogbo ni ṣíṣe.”
”Peteru sì wí fún un pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀lé ọ, kí ni yóò jẹ́ èrè wa?” Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ‘Nígbà ìsọdọ̀tun ohun gbogbo, nígbà tí Ọmọ Ènìyàn yóò jókòó lórí ìtẹ́ tí ó lógo, dájúdájú, ẹ̀yin ọmọ-ẹ̀yìn mi yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ méjìlá láti ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli méjìlá. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ilé tàbí arákùnrin tàbí arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ, tàbí ohun ìní rẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mí, yóò gba ọgọọgọ́rùn-ún èrè rẹ̀ láyé, wọn ó sì tún jogún ìyè àìnípẹ̀kun.
”“Nítorí ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin tí ó jẹ́ baálé kan, tí ó jíjáde lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí ó gba àwọn alágbàṣe sínú ọgbà àjàrà rẹ̀. Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀. “Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà. Ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pàápàá, ẹ lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi, bí ó bá sì di òpin ọjọ́, èmi yóò san iye ti ó bá yẹ fún yín.’ Wọ́n sì lọ. “Ó tún jáde lọ́sàn án ní nǹkan bí wákàtí kẹfà àti wákàtí kẹsànán, ó túnṣe bákan náà. Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárín ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró. Ó bi wọ́n pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́?’ “Wọ́n sì dáhùn pé, ‘Nítorí pé kò sí ẹni tí yóò fún wa ní iṣẹ́ ṣe.’ “Ó tún sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ jáde lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú nínú ọgbà àjàrà mi.’ “Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà sọ fún aṣojú rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́ náà, kí ó san owó iṣẹ́ wọn fún wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ìkẹyìn lọ sí ti ìṣáájú.’ “Nígbà tí àwọn ti a pè ní wákàtí kọkànlá ọjọ́ dé, ẹnìkọ̀ọ̀kan gba owó dínárì kan. Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣiṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó tiwọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan. Bí wọ́n ti ń gbà á, wọ́n ń kùn sí onílẹ̀ náà, pé, ‘Wákàtí kan péré ni àwọn tí a gbà kẹ́yìn fi ṣiṣẹ́, ìwọ sì san iye kan náà fún wọn àti àwa náà ti a fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ nínú oòrùn gangan.’ “Ṣùgbọ́n ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀rẹ́, kò sí aburú nínú nǹkan tí èmi ṣe sí yín. Kì í ha ṣe pé ẹ̀yin gbà láti ṣiṣẹ́ fún owó dínárì kan. Ó ní, Gba èyí tí í ṣé tìrẹ, ki ó sì máa lọ. Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹyìn gẹ́gẹ́ bí mo ti fi fún ọ. Àbí ó lòdì sí òfin pé kí èmi fún ẹnikẹ́ni ní owó mi bí mo bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni ìdí tí ìwọ ní láti bínú nítorí èmi ṣe ohun rere?’ “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ìkẹyìn yóò di ẹni ìṣáájú, ẹni ìṣáájú yóò sì di ẹni ìkẹyìn.”
”Jesu sì wọ inú tẹmpili, Ó sì lé àwọn ti ń tà àti àwọn tí ń rà níbẹ̀ jáde. Ó yí tábìlì àwọn onípàṣípàrọ̀ owó dànù, àti tábìlì àwọn tí ó ń ta ẹyẹlé. Ó wí fún wọn pé, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi,’ ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà.”
”Nísinsin yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó orí fún Kesari tàbí kò tọ́?” Ṣùgbọ́n Jesu ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò? Ẹ fi owó ẹyọ tí a fi ń san owó orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un, ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán ta ni èyí? Àkọlé tà sì ní?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Kesari ni.” “Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Kesari fún Kesari, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
”“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin ń gba ìdámẹ́wàá minti, dili àti kumini, ẹ̀yin sì ti fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú òfin sílẹ̀ láìṣe, ìdájọ́, àánú àti ìgbàgbọ́: Wọ̀nyí ni ó tọ́ tí ẹ̀yin ìbá ṣe, ẹ̀yin kò bá fi wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ láìṣe.
”“A sì tún fi ìjọba ọ̀run wé ọkùnrin kan tí ó ń lọ sí ìrìnàjò. Ó pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì kó ohun ìní rẹ̀ fún wọn. Ó fún ọ̀kan ni tálẹ́ǹtì márùn-ún, ó fún èkejì ni tálẹ́ǹtì méjì, ó sì fún ẹ̀kẹta ni tálẹ́ǹtì kan, ó fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti mọ, ó sì lọ ìrìnàjò tirẹ̀. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti fi owó náà ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè márùn-ún mìíràn. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì náà fi tirẹ̀ ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ò gba tálẹ́ǹtì kan, ó wa ihò ní ilẹ̀, ó sì bo owó ọ̀gá mọ́ ibẹ̀. “Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, olúwa àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ dé láti àjò rẹ̀. Ó pè wọ́n jọ láti bá wọn ṣírò owó rẹ̀. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún, mú márùn-ún mìíràn padà wá, ó wí pé, ‘olúwa, ìwọ ti fi tálẹ́ǹtì márùn-ún fún mi, mo sì ti jèrè márùn-ún mìíràn pẹ̀lú rẹ̀.’ “Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́: ìwọ ṣe olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’ “Èyí tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì wí pé ‘Olúwa, ìwọ fún mi ní tálẹ́ǹtì méjì láti lò, èmi sì ti jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn.’ “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́. Ìwọ ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ ṣe olórí ohun púpọ̀. Ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’ “Níkẹyìn, ọkùnrin tí a fún ní tálẹ́ǹtì kan wá, ó wí pé, ‘Olúwa, mo mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni ìwọ ń ṣe ìwọ ń kórè níbi tí ìwọ kò gbìn sí, ìwọ ń kójọ níbi tí ìwọ kò ó ká sí. Èmi bẹ̀rù, mo sì lọ pa tálẹ́ǹtì rẹ mọ́ sínú ilẹ̀. Wò ó, nǹkan rẹ nìyìí.’ “Ṣùgbọ́n olúwa rẹ̀ dáhùn pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé èmi ń kórè níbi tí èmi kò fúnrúgbìn sì, èmi sì ń kójọ níbi tí èmi kò fọ́nká ká sí. Nígbà náà ìwọ ìbá kúkú fi owó mi sí ilé ìfowópamọ́ tí èmi bá dé èmi ìbá le gba owó mi pẹ̀lú èrè. “ ‘Ó sì pàṣẹ kí a gba tálẹ́ǹtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí a sì fún ọkùnrin tí ó ní tálẹ́ǹtì mẹ́wàá. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní a ó fún sí i, yóò sí tún ní sí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n láti ọwọ́ ẹni tí kò ní ni a ó ti gbà èyí tí ó ní. Nítorí ìdí èyí, gbé aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀, jù ú sínú òkùnkùn lóde, ibẹ̀ ni ẹ̀kún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.’
”“Nígbà náà ni ọba yóò wí fún àwọn tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún fún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òǹgbẹ gbẹ mí, ẹ̀yin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’ “Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò fèsì pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì fún ọ ní oúnjẹ? Tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́ tí a sì fún ọ ní ohun mímu? Tàbí tí o jẹ́ àlejò tí a gbà ó sínú ilé wa? Tàbí tí o wà ní ìhòhò, tí a sì daṣọ bò ọ́? Nígbà wo ni a tilẹ̀ rí i tí o ṣe àìsàn, tàbí tí o wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, tí a bẹ̀ ọ́ wò?’ “Ọba náà yóò sì dáhùn yóò sì wí fún wọn pé, ‘lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin ṣe nǹkan wọ̀nyí fún àwọn arákùnrin mi yìí tí o kéré jú lọ, ẹ̀ ń ṣe wọn fún mi ni.’
”“Nígbà náà ni yóò sọ fún àwọn tí ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún, sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti tọ́jú fún èṣù àti àwọn angẹli rẹ̀. Nítorí tí ebi pa mi, ẹ̀yin kò tilẹ̀ bọ́ mi, òrùngbẹ gbẹ mi, ẹ kò tilẹ̀ fún mi ní omi láti mu. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mi sílé. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin kò fi aṣọ bò mi. Mo ṣàìsàn, mo sì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ẹ̀yin kò bẹ̀ mí wò.’ “Nígbà náà àwọn pẹ̀lú yóò dáhùn pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ, tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́, tàbí tí o ṣàìsàn, tàbí tí o wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, tí a kò sí ràn ọ́ lọ́wọ́?’ “Nígbà náà àwọn yóò dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún pé, Nígbà tí ẹ̀yin ti kọ̀ láti ran ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ́wọ́ nínú arákùnrin mi ẹ̀yin tí kọ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi ni.’
”Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú alabasita òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, inú bí wọn. Wọ́n wí pé, “Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí? Èéha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní.” Jesu ti mọ èrò ọkàn wọn, ó wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dá obìnrin yìí lẹ́bi? Ó ṣe ohun tí ó dára fún mi Ẹ̀yin yóò ní àwọn aláìní láàrín yín nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n, ẹ̀yin kò le rí mi nígbà gbogbo.
”Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jesu lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á. Láti ìgbà náà lọ ni Judasi ti bẹ̀rẹ̀ sí i wá ọ̀nà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.
”Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù. Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.” Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!” Nígbà náà ni Judasi da owó náà sílẹ̀ nínú tẹmpili. Ó jáde, ó sì lọ pokùnso. Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà. Wọ́n wí pé, “Àwa kò lè fi owó yìí sínú owó ìkójọpọ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.” Wọ́n sì gbìmọ̀, wọ́n sì fi ra ilẹ̀ amọ̀kòkò, láti máa sin òkú àwọn àjèjì nínú rẹ̀. Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní. Èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wí pé, “Wọ́n sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí àwọn ènìyàn Israẹli díye lé e. Wọ́n sì fi ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn amọ̀kòkò gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ.”
”Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, o sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”
”Àwọn tí ó bọ́ sáàrín ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí àti ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà á lóòtítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”
”Ṣùgbọ́n Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí fún pé, “Èyí yóò ná wa tó owó iṣẹ́ ọya oṣù mẹ́jọ, Ṣe kí a lọ fi èyí ra àkàrà fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí láti jẹ.” Jesu tún béèrè pé, “Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ni lọ́wọ́? Ẹ lọ wò ó.” Wọ́n padà wá jíṣẹ́ pé, “Ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì.” Nígbà náà ni Jesu sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn náà kí a mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ lórí koríko. Lẹ́sẹ̀kan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó, ní àádọ́ta tàbí ọgọọgọ́rùn-ún. Nígbà tí ó sì mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run. Ó dúpẹ́ fún oúnjẹ náà, ó bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé e kalẹ̀ síwájú àwọn ènìyàn náà àti àwọn ẹja méjì náà ni ó pín fún gbogbo wọn. Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì kó agbọ̀n méjìlá tí ó kún fún àjẹkù àkàrà àti ti ẹja pẹ̀lú. Àwọn tí ó sì jẹ́ àkàrà náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin.
”ọ̀kánjúwà, odì yíyàn, ìtànjẹ, ìmọtaraẹni, ìlara, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀. Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.”
”Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìhìnrere, òun náà ni yóò gbà á là. Nítorí èrè kí ni ó jẹ́ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàṣípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀?
”Jesu wò ó tìfẹ́tìfẹ́. Ó wí fún un pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan ló kù fún ọ láti ṣe, lọ nísinsin yìí, ta gbogbo nǹkan tí o ní, kí o sì pín owó náà fún àwọn aláìní ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Nígbà tí ọkùnrin yìí gbọ́ èyí, ojú rẹ̀ korò, ó sì lọ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí pé ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
”Jesu wò ó bí ọkùnrin náà ti ń lọ. Ó yípadà, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àní, ohun ìṣòro ni fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!” Ọ̀rọ̀ yìí ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu. Jesu tún sọ fún wọn pé, “Ẹyin ọmọ yóò tí ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run. Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ kan láti wọ ìjọba ọ̀run.” Ẹnu túbọ̀ ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sí i. Wọ́n béèrè wí pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni nínú ayé ni ó lè ní ìgbàlà?” Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ní èyí kò ṣe é ṣe fún ṣùgbọ́n kì í ṣe fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ni ṣíṣe fún Ọlọ́run.”
”Nígbà náà ni Peteru kọjú sí Jesu, ó wí pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ohunkóhun sílẹ̀ bí: ilé, tàbí àwọn arákùnrin, tàbí àwọn arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí baba, tàbí àwọn ọmọ tàbí ohun ìní nítorí mi àti nítorí ìhìnrere, tí a kì yóò fún padà ní ọgọọgọ́rùn-ún àwọn ilé, tàbí arákùnrin, tàbí arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí ọmọ, tàbí ilẹ̀, àti inúnibíni pẹ̀lú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ tirẹ̀ ní ayé yìí àti pé ní ayé tó ń bọ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun.
”Nígbà ti wọ́n padà sí Jerusalẹmu, ó wọ inú tẹmpili. Ó bẹ̀rẹ̀ sí nílé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbàárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹmpili ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀. Kò sì gba ẹnikẹ́ni láààyè láti gbé ẹrù ọjà títà gba inú tẹmpili wọlé. Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, “Ṣé a kò ti kọ ọ́ pé: ‘Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi, ní gbogbo orílẹ̀-èdè?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà.”
”Bí wọn ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Nísinsin yìí, sọ fún wa, ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Kesari?” Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un? Ṣùgbọ́n Jesu mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi n fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.” Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?” Wọ́n dáhùn pé, “Àwòrán àti orúkọ Kesari ni.” Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari. Ṣùgbọ́n ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀.
”Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìí sọ sínú àpótí ìṣúra ju gbogbo àwọn ìyókù to sọ sínú rẹ lọ. Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”
”Nígbà tí ó sì wà ní Betani ni ilé Simoni adẹ́tẹ̀ bí ó ti jókòó ti oúnjẹ, obìnrin kan wọlé, ti òun ti alabasita òróró ìkunra olówó iyebíye, ó ṣí ìgò náà, ó sì da òróró náà lé Jesu lórí. Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́. Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, “Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò? Òun ìbá ta òróró ìkunra yìí ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn tálákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára. Ṣùgbọ́n Jesu wí fún pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi? Nígbà gbogbo ni àwọn tálákà wà ní àárín yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkúgbà tí ẹ bá fẹ́.
”Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.
”Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”
”Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.” Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”
”Nígbà tí ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Alábùkún fún ni ẹ̀yin òtòṣì, nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ebi ń pa nísinsin yìí; nítorí tí ẹ ó yóò. Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ń sọkún nísinsin yìí: nítorí tí ẹ̀yin ó rẹ́rìn-ín.
”“Ègbé ni fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀ nítorí ẹ ti gba ìtùnú yín. Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ó yó, nítorí ebi yóò pa yín, Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń rẹ́rìn-ín nísinsin yìí, nítorí tí ẹ̀yin ó ṣọ̀fọ̀, ẹ̀yin ó sì sọkún.
”Ẹni tí ó bá sì lù ọ́ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan, yí kejì sí i pẹ̀lú; àti ẹni tí ó gba agbádá rẹ, má ṣe dá a dúró láti gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú. Sì fi fún gbogbo ẹni tí ó tọrọ lọ́dọ̀ rẹ; lọ́dọ̀ ẹni tí ó sì kó ọ ní ẹrù, má sì ṣe padà béèrè.
”“Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin bá fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ yín, ọpẹ́ kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ wọn. Bí ẹ̀yin sì ṣoore fún àwọn tí ó ṣoore fún yín, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
”Bí ẹ̀yin bá fi fún ẹni tí ẹ̀yin ń retí láti rí gbà padà, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń yá ‘ẹlẹ́ṣẹ̀,’ kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú.
”Ẹ fi fún ni, a ó sì fi fún yín; òṣùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ́n si àyà yín: nítorí òṣùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ́n, òun ni a ó padà fi wọ́n fún yín.”
”Jesu sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jeriko, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n sá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán.
”Nígbà tí ó sì lọ ní ọjọ́ kejì, ó fi owó idẹ méjì fún olórí ilé èrò ó sì wí fún un pé, ‘Máa tọ́jú rẹ̀; ohunkóhun tí ìwọ bá sì ná kún un, nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san án fún ọ.’
”Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lójoojúmọ́.
”Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ó jẹ́ ènìyàn búburú bá mọ bí a ti í fi ẹ̀bùn dáradára fún àwọn ọmọ yín: mélòó mélòó ha ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tí ó béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀!”
”Nípa ohun ti inú yin, ki ẹ̀yin kúkú máa ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsi i, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín. “Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá minti àti irúgbìn, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsí fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe.
”Ọ̀kan nínú àwùjọ wí fún un pé, “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín mi ní ogún.” Ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin yìí, ta ni ó fi mí jẹ onídàájọ́ tàbí olùpíngún fún yín?” Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsára kí o sì máa ṣọ́ra nítorí ojúkòkòrò: nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kò dúró lé ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.”
”Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.’ “Ó sì wí pé, ‘Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èso àti ọrọ̀ mi jọ sí. Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, máa yọ̀.’ “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti ta ni nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?’ “Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
”Jesu sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Nítorí náà mo wí fún yín pé, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nítorí ẹ̀mí yín pé, kín ni ẹ̀yin yóò jẹ tàbí nípa ara yin pe kín ni ẹyin o fi bora. Ẹ̀mí sá à ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ. Ẹ kíyèsi àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sá à ń bọ́ wọn: mélòó mélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ! Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀? Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù? “Ẹ kíyèsi àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Solomoni pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónìí, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòó mélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣe àníyàn nínú ọkàn. Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń wá kiri: Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ́ nǹkan wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.
”Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́.
”Nítorí ní ibi tí ìṣúra yín gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yóò gbé wà pẹ̀lú.
”Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládùúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkún ara, àwọn amúnkùn ún, àti àwọn afọ́jú: Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítorí wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ: ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòtítọ́.”
”Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó ṣe nínú yín, tí kò kọ ohun gbogbo tí ó ní sílẹ̀, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
”“Tàbí obìnrin wo ni ó ní owó fàdákà mẹ́wàá bí ó bá sọ ọ̀kan nù, tí kì yóò tan fìtílà, kí ó fi gbá ilé, kí ó sì wá a gidigidi títí yóò fi rí i? Nígbà tí ó sì rí i, ó pe àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, ó wí pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀; nítorí mo rí owó fàdákà tí mo ti sọnù.’ Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ń bẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”
”Ó sì wí pé ọkùnrin kan ní ọmọ méjì: “Èyí àbúrò nínú wọn wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Baba, fún mi ní ìní tí ó kàn mí.’ Ó sì pín ohun ìní rẹ̀ fún wọn. “Kò sì tó ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, èyí àbúrò kó ohun gbogbo tí ó ní jọ, ó sì mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ òkèrè, níbẹ̀ ni ó sì gbé fi ìwà wọ̀bìà ná ohun ìní rẹ̀ ní ìnákúnàá. Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní. Ó sì fi ara rẹ sọfà fun ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìlú náà; òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ láti tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀. Ayọ̀ ni ìbá fi jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ ní àjẹyó: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò sì fi fún un. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní ‘Mélòó mélòó àwọn alágbàṣe baba mí ni ó ní oúnjẹ àjẹyó, àti àjẹtì, èmi sì ń kú fún ebi níhìn-ín. Èmi ó dìde, èmi ó sì tọ baba mi lọ, èmi ó sì wí fún un pé: Baba, èmí ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ; Èmi kò sì yẹ, ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́; fi mí ṣe ọ̀kan nínú àwọn alágbàṣe rẹ.’ Ó sì dìde, ó sì tọ baba rẹ̀ lọ. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ó sì wà ní òkèrè, baba rẹ̀ rí i, àánú ṣe é, ó sì súré, ó rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu. “Ọmọ náà sì wí fún un pé, Baba, èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ, èmi kò yẹ ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́! “Ṣùgbọ́n baba náà wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, Ẹ mú ààyò aṣọ wá kánkán, kí ẹ sì fi wọ̀ ọ́; ẹ sì fi òrùka bọ̀ ọ́ lọ́wọ́, àti bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ̀: Ẹ sì mú ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa wá, kí ẹ sì pa á; kí a máa ṣe àríyá: Nítorí ọmọ mi yìí ti kú, ó sì tún yè; ó ti nù, a sì rí i. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àríyá.
”Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan; òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun ìní rẹ̀ ṣòfò. Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? Ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mi mọ́.’ “Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò le ṣiṣẹ́ oko, bẹ́ẹ̀ ni ojú ń tì mí láti ṣagbe. Mo mọ èyí tí èmi yóò ṣe, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi iṣẹ́ ìríjú, kí àwọn ènìyàn le gbà mí sínú ilé wọn.’ “Ó sì pe àwọn ajigbèsè olúwa rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún èkínní pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ olúwa mi?’ “Ó sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n òróró.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta.’ “Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ?’ “Òun sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún òṣùwọ̀n alikama.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, kí o sì kọ ọgọ́rin.’ “Olúwa rẹ̀ sì yin aláìṣòótọ́ ìríjú náà, nítorí tí ó fi ọgbọ́n ṣe é: àwọn ọmọ ayé yìí sá à gbọ́n ní Ìran wọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ. Èmi sì wí fún yín, ẹ fi ọrọ̀ ayé yìí yan ọ̀rẹ́ fún ara yín pé, nígbà tí o ba lọ, kí wọn kí ó le gbà yín sí ibùjókòó wọn títí ayé.
”“Ẹni tí ó bá ṣe olóòtítọ́ nínú ohun kínkínní, ó ṣe olóòtítọ́ ní púpọ̀ pẹ̀lú: ẹni tí ó bá sì ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun kínkínní, ó ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun púpọ̀ pẹ̀lú. Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò bá ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ọrọ̀ ayé yìí, ta ni yóò fi ọ̀rọ̀ tòótọ́ fún yín? Bí ẹ̀yin kò bá sì ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun tí í ṣe ti ẹlòmíràn, ta ni yóò fún yín ní ohun tí í ṣe ti ẹ̀yin tìkára yín?
”“Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.” Àwọn Farisi, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ ṣùtì sí i.
”“Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ aṣọ elése àlùkò àti aṣọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójoojúmọ́: Alágbe kan sì wà tí à ń pè ní Lasaru, tí wọ́n máa ń gbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fún ooju, Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun: àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá. “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn angẹli gbé e lọ sí oókan àyà Abrahamu: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín; Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀. Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’ “Ṣùgbọ́n Abrahamu wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lasaru ohun búburú: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró. Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má ba á le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’ “Ó sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ mo bẹ̀ ọ́, baba, kí ìwọ kí ó rán Lasaru lọ sí ilé baba mi: Nítorí mo ní arákùnrin márùn-ún; kí ó lè rò fún wọn kí àwọn kí ó má ba á wá sí ibi oró yìí pẹ̀lú.’ “Abrahamu sì wí fún un pé, ‘Wọ́n ní Mose àti àwọn wòlíì; kí wọn kí ó gbọ́ tiwọn.’ “Ó sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, Abrahamu baba; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ti inú òkú tọ̀ wọ́n lọ, wọn ó ronúpìwàdà.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mose àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde.’ ”
”Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá àti gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóò sọ ọ́ nù; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ nù yóò gbà á là.
”Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì ní ọ̀sẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’
”Nígbà tí Jesu sì gbọ́ èyí, ó wí fún un pé, “Ohun kan ni ó kù fún ọ síbẹ̀: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn tálákà, ìwọ ó sì ní ìṣúra ní ọ̀run: sì wá, kí o máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Nígbà tí ó sì gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi: nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
”Nígbà tí Jesu rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi, ó wí pé, “Yóò ti ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run! Nítorí ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run lọ.” Àwọn tí ó sì gbọ́ wí pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha lè là?” Ó sì wí pé, “Ohun tí ó ṣòro lọ́dọ̀ ènìyàn kò ṣòro lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
”Peteru sì wí pé, “Sá wò ó, àwa ti fi ilé wa sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!” Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí aya, tàbí ará, tàbí òbí, tàbí ọmọ sílẹ̀, nítorí ìjọba Ọlọ́run, Tí kì yóò gba ìlọ́po púpọ̀ sí i ní ayé yìí, àti ní ayé tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”
”Sakeu sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, “Wò ó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fi fún tálákà; bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin!”
”Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà. Ó sì pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mina mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ máa ṣòwò títí èmi ó fi dé!’ “Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jẹ ọba lórí wa.’ “Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́ òwò wọn. “Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina mẹ́wàá sí i.’ “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere! Nítorí tí ìwọ ṣe olóòtítọ́ ní ohun kínkínní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’ “Èyí èkejì sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina márùn.’ “Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ pẹ̀lú joyè ìlú márùn-ún!’ “Òmíràn sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, wò ó owó mina rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ pélébé kan; Nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn: ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn!’ “Olúwa rẹ sì wí fún un pé, ‘Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn; Èéha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowópamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, Èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’ “Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó mina náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó minas mẹ́wàá.’ “Wọ́n sì wí fún un pé, ‘Olúwa, ó ní owó mina mẹ́wàá.’ “Mo wí fún yín pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fi fún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.
”Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde; Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọsa.”
”Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?” Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ fi owó idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti ta ni ó wà níbẹ̀?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.” Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Kesari fún Kesari, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
”Nígbà tí ó sì gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àpótí ìṣúra. Ó sì rí tálákà opó kan pẹ̀lú, ó ń sọ owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì síbẹ̀. Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, tálákà opó yìí fi sí i ju gbogbo wọn lọ: Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí fi sínú ẹ̀bùn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní wọn; ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ní sínú rẹ̀.”
”Ó sì rí àwọn tí n ta màlúù, àti àgùntàn, àti àdàbà, àti àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nínú tẹmpili wọ́n jókòó: Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹmpili, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó si ti tábìlì wọn ṣubú. Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, “Ìtara ilé rẹ jẹ mí run.”
”Ẹ má ṣe ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún oúnjẹ tí ó wà títí di ayé àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọmọ ènìyàn yóò fi fún yín: nítorí pé òun ni, àní Ọlọ́run Baba ti fi èdìdì dì í.”
”Jesu wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè: ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á; ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé.
”Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun: èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀. “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.
”Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, “Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́. Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi. Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin sá à ní tálákà pẹ̀lú yín; ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.”
”Àti ní ọjọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín. Títí di ìsinsin yìí ẹ kò tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi: ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.
”Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn; Wọn si ń ta ohun ìní àti ẹrù wọn, wọn sì ń pín wọn fún olúkúlùkù, gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni tí í ṣe aláìní sí. Wọ́n fi ọkàn kan dúró lójoojúmọ́ nínú tẹmpili. Wọ́n ń bu àkàrà ní ilé wọn, wọn ń fi inú dídùn àti ọkàn òtítọ́ jẹ oúnjẹ wọn.
”Peteru wí pé, “Wúrà àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fi fún ọ: Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, dìde kí o sì máa rìn.”
”Ìjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan; kò sì ṣí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìṣọ̀kan. Agbára ńlá ni àwọn aposteli sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jesu Olúwa, oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn. Nítorí kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ṣe aláìní, nítorí iye àwọn tí ó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n, wọ́n sì mú owó ohun tí wọn tà wá. Wọ́n sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli, wọn sì ń pín fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe aláìní sí.
”Àti Josẹfu, tí a ti ọwọ́ àwọn aposteli sọ àpèlé rẹ̀ ní Barnaba (ìtumọ̀ èyí tí ń jẹ Ọmọ-Ìtùnú), ẹ̀yà Lefi, àti ará Saipurọsi. Ó ní ilẹ̀ kan, ó tà á, ó mú owó rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli.
”Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Anania, pẹ̀lú Safira aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan, Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apá kan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apá kan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli. Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Anania, Èéṣe ti Satani fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apá kan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà? Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? Èéha ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣèké sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?”
”Nígbà tí Simoni rí i pé nípa gbígbé ọwọ́ lé ni ni a ń ti ọwọ́ àwọn aposteli fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n, ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.” Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run!
”Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pinnu, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti tó, láti rán ìrànlọ́wọ́ sí àwọn arákùnrin tí ó wà ní Judea.
”Èmí kò ṣe ojúkòkòrò fàdákà, tàbí wúrà, tàbí aṣọ ẹnikẹ́ni. Ẹ̀yin tìkára yín sá à mọ̀ pé, ọwọ́ mi wọ̀nyí ni mo fi ṣiṣẹ́ láti fi pèsè fún àìní mi, àti tí àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi. Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ”
”Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí?
”Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu. Ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí.”
”Nítorí ìdí èyí, ẹ san owó òde pẹ̀lú, nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n, èyí náà ni wọ́n ń bojútó nígbà gbogbo. Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo: owó òde fún ẹni tí owó òde í ṣe tirẹ̀: owó bodè fún ẹni tí owó bodè í ṣe tirẹ̀: ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù í ṣe tirẹ̀; ọlá fún ẹni tí ọlá í ṣe tirẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ni nígbésè ohun kan, bí kò ṣe pé kí a fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já. Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ ṣọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ẹnìkéjì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.”
”Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìṣòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.
”Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi.
”Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí wí fún àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé.
”Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá.
”Níwọ́n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.
”Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run.
”Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn. Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́. Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnrawọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run.
”Nítorí ẹ̀yin mọ oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi, pé bí òun ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ rí ṣùgbọ́n nítorí yín ó di tálákà kí a lè sọ yín di ọlọ́rọ̀ nípa àìní rẹ̀.
”Nítorí bí ìpinnu bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní. Nítorí èmi kò fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín, ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba, Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àníṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú ba à lè ṣe déédé àìní yín: kí ìmúdọ́gba ba à lè wà. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù.”
”Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ́bi ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti a fi ìkùnsínú ṣe.
”Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé: Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kín ún, kín ún ni yóò ká; ẹni tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká. Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ. Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore-ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé: “Ó tí fọ́nká; ó ti fi fún àwọn tálákà; Òdodo rẹ̀ dúró láéláé.”
”Ǹjẹ́ ẹni tí ń fi irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa. Nítorí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run. Nítorí ìdúró yin lábẹ́ ìdánwò iṣẹ́ ìsìn yìí, wọn yóò yin Ọlọ́run lógo fún ìgbọ́ràn yín ní gbígba ìhìnrere Kristi àti nípa ìlawọ́ ìdáwó yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn.
”Ohun gbogbo tí wọ́n béèrè fún ni wí pé, kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan an tí mo ń làkàkà láti ṣe.
”Nítorí pé a kó gbogbo òfin já nínú èyí pé, “Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”
”Kí a má ṣe tàn yín jẹ; a kò lè gan Ọlọ́run: nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òhun ni yóò sì ká. Nítorí ẹni tí ó bá ń fúnrúgbìn sípa ti ara yóò ká ìdíbàjẹ́ ti ara ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn sípa ti ẹ̀mí yóò ti inú ẹ̀mí ká ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ má sì jẹ́ kí àárẹ̀ ọkàn mú wa ní ṣíṣe rere, nítorí tí a ó kórè nígbà tí àkókò bá dé, bí a kò bá ṣe àárẹ̀. Ǹjẹ́ bí a ti ń rí àǹfààní gba, ẹ jẹ́ kí a máa ṣoore fún gbogbo ènìyàn, àti pàápàá fún àwọn tí í ṣe ará ilé ìgbàgbọ́.
”Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídìí ọ̀rọ̀ Kristi fún àwọn aláìkọlà;
”Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dára, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní.
”Kí olúkúlùkù yín má ṣe ro ohun ti ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ti ẹlòmíràn pẹ̀lú.
”Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kristi. Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi,
”Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọpọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábápín nínú ìpọ́njú mi. Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Filipi, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere, nígbà tí mo kúrò ni Makedonia, kò sí ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábápín ní ti gbígbà àti fífún ni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo. Nítorí ní Tẹsalonika ẹ̀yin fi nǹkan ránṣẹ́, lẹ́ẹ̀kan fún àìní mi. Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà: ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín Ṣùgbọ́n mo ní ohun gbogbo, mo sì ti di púpọ̀: mo sì tún ni lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà ti mo tí gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Epafiroditu tí a ti rán wá láti lọ́dọ̀ yín, ọrẹ olóòórùn dídùn, ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà, tì í ṣe inú dídùn gidigidi sí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kristi Jesu.
”Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lókè kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé.
”Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nínú ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kristi Jesu nítòótọ́.
”Nítorí nígbà tí àwa wà lọ́dọ̀ yín, a ṣe àwọn òfin wọ̀nyí fún un yín pé, “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”
”Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe ara wọn ní ọ̀ṣọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye,
”Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ará ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ.
”Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni. Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ. Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn. Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹ̀kùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa ni lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀.
”Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ láti lò;
”Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́.
”Alábojútó jẹ́ ẹni tí a gbé iṣẹ́ Ọlọ́run lé lọ́wọ́, nítorí náà, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kankan tàbí agbéraga, oníjà, kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí tàbí alágídí tàbí olójúkòkòrò.
”Nítorí Melkisedeki yìí, ọba Salẹmu, àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹni tí ó pàdé Abrahamu bí ó ti ń padà bọ̀ láti ibi pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un, ẹni tí Abrahamu sì pín ìdámẹ́wàá ohun gbogbo fún. Ní ọ̀nà èkínní orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “ọba òdodo,” àti lẹ́yìn náà pẹ̀lú, “ọba Salẹmu,” tí í ṣe “ọba àlàáfíà.” Láìní baba, láìní ìyá, láìní ìtàn ìran, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọjọ́ ayé; ṣùgbọ́n a ṣe é bí ọmọ Ọlọ́run; ó wà ní àlùfáà títí. Ǹjẹ́ ẹ gbà á rò bí ọkùnrin yìí ti pọ̀ tó, ẹni tí Abrahamu baba ńlá fi ìdámẹ́wàá nínú àwọn àṣàyàn ìkógun fún. Àti nítòótọ́ àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Lefi, tí o gba oyè àlùfáà, wọ́n ní àṣẹ láti máa gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí òfin, èyí yìí, lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí ó tilẹ̀ ti jẹ́ pé, wọn ti inú Abrahamu jáde. Ṣùgbọ́n òun ẹni tí a kò tilẹ̀ pìtàn ìran rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn wá, gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ Abrahamu, ó sì súre fún ẹni tí ó gba ìlérí, láìsí ìjiyàn rárá ẹni kò tó ẹni tí à ń súre fún láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ju ni. Ni apá kan, àwọn ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá; ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láààyè nì. Àti bí a ti lè wí, Lefi pàápàá tí ń gba ìdámẹ́wàá, ti san ìdámẹ́wàá nípasẹ̀ Abrahamu. Nítorí o sá à sì ń bẹ ní inú baba rẹ̀, nígbà ti Melkisedeki pàdé rẹ̀.
”Nípa ìgbàgbọ́ ni Mose, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọbìnrin Farao; o kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ: Nítorí tí ó ń wo èrè náà.
”Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé, “Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”
”Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín fun ni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.
”Ṣùgbọ́n jẹ́ kí arákùnrin tí ó ń ṣe onírẹ̀lẹ̀ máa ṣògo ní ipò gíga. Àti ọlọ́rọ̀, ní ìrẹ̀sílẹ̀, nítorí bí ìtànná koríko ni yóò kọjá lọ. Nítorí oòrùn là ti òun ti ooru gbígbóná yóò gbẹ́ koríko, ìtànná rẹ̀ sì rẹ̀ dànù, ẹwà ojú rẹ̀ sì parun: bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣègbé ní ọ̀nà rẹ̀.
”Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà.
”Nítorí bí ọkùnrin kan bá wá sí ìpéjọpọ̀ yín, pẹ̀lú òrùka wúrà àti aṣọ dáradára, tí tálákà kan sì wá pẹ̀lú nínú aṣọ èérí; tí ẹ̀yin sì bu ọlá fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára” tí ẹ sì wí fún tálákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi,” ẹyin kò ha ń dá ara yín sí méjì nínú ara yín, ẹ̀yin kò sì di onídàájọ́ tí ó ní èrò búburú bí? Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn tálákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu tálákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́? Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí?
”Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń mú olú òfin nì ṣẹ gẹ́gẹ́ bí Ìwé mímọ́, èyí tí ó wí pé, “Ìwọ fẹ́ ẹni kejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ,” ẹ̀yin ń ṣe dáradára.
”Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́ láti fihan? Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí? Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní àìní aṣọ, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́, Tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́? Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀.
”Ẹ̀yin béèrè, ẹ kò sì rí gbà, nítorí tí ẹ̀yin ṣì béèrè, kí ẹ̀yin kí ó lè lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín.
”Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, “Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè.” Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la. Kí ni ẹ̀mí yín? Ìkùùkuu sá à ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ. Èyí tí ẹ̀ bá fi wí pé, “Bí Olúwa bá fẹ́, àwa yóò wà láààyè, àwa ó sì ṣe èyí tàbí èyí i nì.”
”Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùnréré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín. Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín. Wúrà òun fàdákà yín díbàjẹ́; ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran-ara yín bí iná. Ẹ̀yin tí kó ìṣúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn.
”Kíyèsi i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara; àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ; ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa.
”Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi.
”Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín padà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín.
”Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀; Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.
”Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀. Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó ṣe: kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé. Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé.
”Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀? Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́.
”Ǹjẹ́ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi. Nítorí tí ìwọ wí pé, Èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò sì ṣe aláìní ohunkóhun; tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ìkáàánú, tálákà, afọ́jú, àti ẹni ìhòhò: Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran.
”Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òṣùwọ̀n alikama kan fún owó idẹ kan, àti òṣùwọ̀n ọkà barle mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsi i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára.
”Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè; Wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà:
”Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti tálákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba ààmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn; àti kí ẹnikẹ́ni má lè rà tàbí tà, bí kò ṣe ẹni tí o bá ní ààmì náà, èyí ni orúkọ ẹranko náà, tàbí ààmì orúkọ rẹ̀.
”“Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́: Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti Pearli, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti ṣẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabu. Àti ti Kinamoni, àti ti onírúurú ohun olóòórùn dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti òróró, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti alikama, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹṣin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn. “Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé.
”Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn o máa sọkún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀, wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá nì, tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe ní ọ̀ṣọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti peali! Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’ “Àti olúkúlùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú Òkun dúró ní òkèrè réré,
”Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.
”Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, “Máa bọ!” Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, “Máa bọ̀!” Àti ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́.
”