27 – Ìjìyà
Awọn wọnyi ni awọn ọrọ mimọ ti Ọlọrun Olodumare.
A ko nifẹ si awọn ọrọ ti awọn eniyan.
Fun ẹnikẹni ti o ba fẹràn Ọlọrun ... Eyi ni ohun ti Ọlọrun sọ nipa: Ìjìyà.
Awọn wọnyi ni awọn ọrọ mimọ ti Ọlọrun Olodumare.
A ko nifẹ si awọn ọrọ ti awọn eniyan.
Fun ẹnikẹni ti o ba fẹràn Ọlọrun ... Eyi ni ohun ti Ọlọrun sọ nipa: Ìjìyà.
Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!” Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn aṣiwèrè obìnrin ti í sọ̀rọ̀; há bà! Àwa yóò ha gba ìre lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi?” Nínú gbogbo èyí, Jobu kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.
”A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù. A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run. Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jesu Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jesu hàn pẹ̀lú lára wa. Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fi àwa tí ó wà láààyè fún ikú nítorí Jesu, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú. Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.
”Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́. Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa. Níwọ́n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.
”ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti èso igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kùú.”
”Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé: “Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ; ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ. Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí, òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.” Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’ “Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ; nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èṣùṣú fún ọ, ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ. Nínú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò máa jẹun títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá; erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ, ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”
”Ọlọ́run si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára. Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, igbe àwọn ará Israẹli ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Ejibiti ti ṣe ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà.
”OLÚWA yóò jà fún un yín; kí ẹ̀yin kí ó sá à mu sùúrù.”
”Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí òfin OLÚWA Ọlọ́run, ti ìwọ sì ṣe ohun tí ó tọ́ ni ojú rẹ̀, ti ìwọ sì tẹ̀lé ohun tí ó pàṣẹ, ti ìwọ si pa ìlànà rẹ̀ mọ́. Èmi kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn ààrùn wọ̀n-ọn-nì ti mo mú wá sórí àwọn ará Ejibiti wá sí ara rẹ, nítorí èmi ni OLÚWA ti ó mú ọ láradá.”
”Bí ìwọ bá ṣe bẹ́ẹ̀, bí wọn bá ké pè mi. Èmi yóò sì gbọ́ ohùn igbe wọn.
”Ẹ̀yin yóò sí máa sin OLÚWA Ọlọ́run yin, òun yóò si bùsi oúnjẹ rẹ. Èmi yóò mú àìsàn kúrò láàrín rẹ.
”“ ‘Bí arákùnrin yín kan bá tálákà tí kò sì le è pèsè fún àìní ara rẹ̀: ẹ pèsè fún un bí ẹ ti ń ṣe fún àwọn àlejò tàbí àwọn tí ẹ gbà sílé: kí ó ba à le è máa gbé láàrín yín.
”“ ‘Èmi yóò fún yín ní àlàáfíà ní ilẹ̀ yín, ẹ̀yin yóò sì sùn láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Èmi yóò mú kí gbogbo ẹranko búburú kúrò ní ilẹ̀ náà: bẹ́ẹ̀ ni idà kì yóò la ilẹ̀ yín já.
”Bí ẹ̀yin bá kọ àṣẹ mi tí ẹ̀yin sì kórìíra òfin mi, tí ẹ̀yin sì kùnà láti pa ìlànà mi mọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ sí májẹ̀mú mi. Èmi yóò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí yín: Èmi yóò mú ìpayà òjijì bá yín: àwọn ààrùn afiniṣòfò, àti ibà afọ́nilójú, tí í pa ni díẹ̀díẹ̀. Ẹ̀yin yóò gbin èso ilẹ̀ yín lásán: nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ gbogbo ohun tí ẹ̀yin ti gbìn. Èmi yóò dojúkọ yín títí tí ẹ̀yin ó fi di ẹni ìkọlù; àwọn tí ó kórìíra yín ni yóò sì ṣe àkóso lórí yín. Ìbẹ̀rù yóò mú yín dé bi pé ẹ̀yin yóò máa sá káàkiri nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé yín.
”Bí ẹ bá wà nínú wàhálà, bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀ sí yín, láìpẹ́ ẹ ó tún padà tọ OLÚWA Ọlọ́run yín wá, ẹ ó sì gbọ́ tirẹ̀. Nítorí pé OLÚWA Ọlọ́run yín aláàánú ni, kò ní gbàgbé tàbí pa yín rẹ́ tàbí kó gbàgbé májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín, èyí tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ìbúra.
”OLÚWA yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ààrùn gbogbo, kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí ààrùn búburú tí ẹ mọ̀ ní Ejibiti wá sára yín, ṣùgbọ́n yóò fi wọ́n lé ara gbogbo àwọn tí ó kórìíra yín.
”Aṣọ yín kò gbó mọ́ ọn yín lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ní ẹsẹ̀ yín kò sì wú, ní ogójì ọdún náà. Ẹ mọ̀ ní ọkàn an yín pé, bí baba ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA Ọlọ́run yín ń kọ́ ọ yín. Nítorí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin OLÚWA Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀.
”Ó máa ń gbẹjọ́ aláìní baba àti opó rò, Ó fẹ́ràn àjèjì, Òun fi aṣọ àti oúnjẹ fún wọn.
”Ẹ kíyèsi i, mo fi ìbùkún àti ègún lélẹ̀ níwájú u yín lónìí: ìbùkún ni, bí ẹ bá pa òfin OLÚWA Ọlọ́run yín, tí mo ń fún un yín lónìí mọ́. Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tí ì mọ̀.
”Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀tá rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, yóò wà pẹ̀lú rẹ.
”Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ.
”Èmi pe ọ̀run àti ilẹ̀ láti jẹ́rìí tì yín ní òní pé, èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ, kí ìwọ kí ó le máa fẹ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ, fetísílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. Nítorí OLÚWA ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.
”Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú rẹ; Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”
”OLÚWA fúnrarẹ̀ ń lọ níwájú rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ; kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù má sì ṣe fòyà.”
”“Wò ó báyìí pé: èmi fúnra à mi, èmi ni! Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi. Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè, Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná, kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.
”Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé OLÚWA à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
”Joṣua sì sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ ṣe gírí, kí ẹ sì mú àyà le. Báyìí ni OLÚWA yóò ṣe sí gbogbo àwọn ọ̀tá yín, tí ẹ̀yin yóò bá jà.”
”“OLÚWA pa ó sì sọ di ààyè; ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde. OLÚWA sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀; ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè. Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo: “Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti OLÚWA ni, ó sì ti gbé ayé ka orí wọn
”Dafidi sì tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ sí OLÚWA, ó sì rú ẹbọ sísun àti ti ìlàjà. OLÚWA sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, ààrùn náà sì dá kúrò ní Israẹli.
”Ní ayé ìgbà wọ̀n-ọn-nì Hesekiah ṣe àìsàn ó sì wà ní ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ: tún ilé rẹ ṣe, ṣùgbọ́n ìwọ yóò kú; o kò ní í gbádùn.” Hesekiah yí ojú rẹ̀ padà sí ògiri ó sì gbàdúrà sí OLÚWA pé, “Rántí, OLÚWA mi, bí èmi ṣe rìn níwájú rẹ àti pẹ̀lú bí èmi ṣe jẹ́ olóòtítọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn ìfọkànsìn mi tí èmi sì ti ṣe ohun tí ó dára níwájú rẹ.” Hesekiah sọkún kíkorò. Kí ó tó di wí pé Isaiah jáde kúrò ní àárín àgbàlá ààfin, ọ̀rọ̀ OLÚWA wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé. “Lọ padà kí o sì sọ fún Hesekiah, olórí àwọn ènìyàn mi pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA, Ọlọ́run baba rẹ Dafidi sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ: Èmi yóò wò ọ́ sàn. Ní ọjọ́ kẹta láti ìsinsin yìí, ìwọ yóò lọ sókè ilé tí a kọ́ fún OLÚWA. Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. Èmi yóò sì gbà ọ́ àti ìlú ńlá yìí láti ọwọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí ti èmi tìkára mi àti nítorí ti Dafidi ìránṣẹ́ mi.’ ”
”Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́; jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin OLÚWA kí ó yọ̀. Ẹ wá OLÚWA àti agbára rẹ̀; E wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo. Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe, iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti ìdájọ́ tí Ó ti sọ.
”tí àwọn ènìyàn, tí a fi orúkọ mi pè, tí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì rí ojú mi, tí wọ́n sì yí kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn, nígbà náà, èmi yóò gbọ́ láti ọ̀run, èmi yóò sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n èmi yóò sì wo ilẹ̀ wọn sàn. Nísinsin yìí, ojú mi yóò sì là etí mi yóò sì là, sí àdúrà ọrẹ níbí yìí.
”Agbára ẹran-ara nìkan ni ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ṣùgbọ́n, Ọlọ́run wa pẹ̀lú wa láti ràn wá lọ́wọ́ àti láti ja ìjà wa.” Àwọn ènìyàn sì ní ìgboyà láti ara ohun tí Hesekiah ọba Juda wí.
”oníṣẹ́ kan sì tọ Jobu wá wí pé: “Àwọn ọ̀dá màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn; Àwọn ará Sabeani sì kọlù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ pẹ̀lú, wọ́n ti fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa, èmi nìkan ṣoṣo ní ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ.” Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi nìkan ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.” Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, “Àwọn ará Kaldea píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọlù àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lúpẹ̀lú wọ́n sì fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ!” Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n. Sì kíyèsi i, ẹ̀fúùfù ńláńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ. Nígbà náà ni Jobu dìde, ó sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà
”wí pé: “Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá, ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ. OLÚWA fi fún ni, OLÚWA sì gbà á lọ, ìbùkún ni fún orúkọ OLÚWA.”
”Satani sì dá OLÚWA lóhùn wí pé, “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀. Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.” OLÚWA sì wí fún Satani pé, “Wò ó, ó ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.” Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú OLÚWA, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń họ ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú.
”Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!” Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn aṣiwèrè obìnrin ti í sọ̀rọ̀; há bà! Àwa yóò ha gba ìre lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi?” Nínú gbogbo èyí, Jobu kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.
”Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀; Elifasi, ara Temani àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama: nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a ṣọ̀fọ̀, àti láti ṣìpẹ̀ fún un. Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún: olúkúlùkù sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jókòó tì í ní inú erùpẹ̀ ní ọjọ́ méje ti ọ̀sán ti òru, ẹnikẹ́ni kò sì bá a sọ ọ̀rọ̀ kan, nítorí tí wọ́n ti rí i pé ìbànújẹ́ rẹ̀ pọ̀ jọjọ.
”“Kíyèsi i, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí, nítorí náà, má ṣe gan ìbáwí Olódùmarè. Nítorí pé òun a máa pa ni lára, síbẹ̀ òun a sì tún dì í ní ìdì ìtura, ó sá lọ́gbẹ́, a sì fi ọwọ́ rẹ̀ di ojú ọgbẹ̀ náà jiná.
”Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀, àní, èmi ìbá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí: nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí. “Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí? Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?
”“Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá, kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀?
”Kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ, awọ ara mi bù, o sì di bíbàjẹ́.
”títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu, àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀,
”“Agara ìwà ayé mi dá mi tán, èmi yóò tú àròyé mi sókè lọ́dọ̀ mi, èmi yóò máa sọ̀rọ̀ nínú kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi.
”Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ, ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ. Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ, bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísinsin yìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀. Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà; àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà. Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́, àní ènìyàn yóò máa wá ojúrere rẹ.
”Ẹ̀yin fi irọ́ bá mi sọ̀rọ̀, oníṣègùn lásán ni gbogbo yín.
”Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e; Ṣùgbọ́n èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.
”“Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn ń ṣègbé bí ohun ìdíbàjẹ́, Bi aṣọ tí kòkòrò jẹ.
”Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí ìrora. Ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”
”Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran-ara mi, mo sì yọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.
”Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáǹdè mi ń bẹ láààyè àti pe òun ni yóò dìde dúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn; Àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ ara mi run, síbẹ̀ láìsí ẹran-ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run,
”“Àti nísinsin yìí, ayé mi n yòrò lọ díẹ̀díẹ̀; ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mímú. Òru gún mi nínú egungun mi, èyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.
”Ikùn mí n ru kò sì sinmi; Ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bá mi. Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn; èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́. Èmi ti di arákùnrin ìkookò, èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò. Àwọ̀ mi di dúdú ní ara mi; egungun mi sì jórun fún ooru.
”“A sì nà án lórí ibùsùn ìrora rẹ̀; pẹ̀lúpẹ̀lú a fi ìjà egungun rẹ̀ ti ó dúró pẹ́ nà án, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí rẹ kọ oúnjẹ, ọkàn rẹ̀ sì kọ oúnjẹ dídùn. Ẹran-ara rẹ̀ run, títí a kò sì fi lè rí i mọ́ egungun rẹ̀ tí a kò tí rí sì ta jáde. Àní, ọkàn rẹ̀ sì súnmọ́ isà òkú, ẹ̀mí rẹ̀ sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ ikú.
”“Nítorí pé ẹnìkan ha lè wí fún Ọlọ́run pé, èmi jẹ̀bi, èmi kò sì ní ṣẹ̀ mọ́? Èyí tí èmi kò rí ìwọ fi kọ́ mi bi mo bá sì dẹ́ṣẹ̀ èmi kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
”OLÚWA sì yí ìgbèkùn Jobu padà, nígbà tí ó gbàdúrà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀; OLÚWA sì bùsi ohun gbogbo ti Jobu ní rí ní ìṣẹ́po méjì ohun tí ó ní tẹ́lẹ̀ rí Nígbà náà ní gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀, àti gbogbo àwọn tí ó ti ṣe ojúlùmọ̀ rẹ̀ rí; wọ́n bá a jẹun nínú ilé rẹ̀. Wọ́n sì ṣe ìdárò rẹ̀, wọ́n sì ṣìpẹ̀ fún un nítorí ibi gbogbo tí OLÚWA ti mú bá a: Olúkúlùkù ènìyàn pẹ̀lú sì fún un ní ẹyọ owó kọ̀ọ̀kan àti olúkúlùkù ni òrùka wúrà etí kọ̀ọ̀kan.
”Àwọn ọba ayé péjọpọ̀ àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀ sí OLÚWA àti sí Ẹni ààmì òróró rẹ̀. Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já, kí a sì ju ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.” Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín; Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
”Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, OLÚWA; ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè. OLÚWA ni mo kígbe sókè sí, ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela. Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn; mo sì tún padà jí, nítorí OLÚWA ni ó ń gbé mi ró. Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
”Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà, nítorí ìwọ nìkan, OLÚWA, ni o mú mi gbé láìléwu.
”Ṣàánú fún mi, OLÚWA, nítorí èmi ń kú lọ; OLÚWA, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira. Ọkàn mi wà nínú ìrora. Yóò ti pẹ́ tó, OLÚWA, yóò ti pẹ́ tó? Yípadà, OLÚWA, kí o sì gbà mí; gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.
”OLÚWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú. Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ, nítorí, OLÚWA, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.
”OLÚWA, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi! Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,
”Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora; Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ. Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ; Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.
”Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà, àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi? Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi? Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, OLÚWA Ọlọ́run mi. Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú;
”Mo ti gbé Ọlọ́run síwájú mi ní ìgbà gbogbo. Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí. Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀; ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò, nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú, tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́. Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí; Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ, pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
”Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ; fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ, lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi, kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.
”Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ OLÚWA tí ó kọ sí OLÚWA, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí OLÚWA fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé Mo fẹ́ ọ, OLÚWA, agbára mi. OLÚWA ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi. Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi. Mo ké pe OLÚWA, ẹni tí ìyìn yẹ fún, a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi. Ìrora ikú yí mi kà, àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí. Okùn isà òkú yí mi ká, ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. Nínú ìpọ́njú mo ké pe OLÚWA; Mo sọkún sí OLÚWA mi fún ìrànlọ́wọ́. Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi; ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.
”Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra ìpọ́njú àwọn tí a ni lára; kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.
”Saamu ti Dafidi. OLÚWA ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní. Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́; Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀. Bí mo tilẹ̀ ń rìn Láàrín àfonífojì òjìji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan; nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ wọ́n ń tù mí nínú. Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi ní ojú àwọn ọ̀tá à mi; ìwọ ta òróró sí mi ní orí; ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀. Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo, èmi yóò sì máa gbé inú ilé OLÚWA títí láéláé.
”Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi; nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú. Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi; kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi. Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.
”Ti Dafidi. OLÚWA ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi; ta ni èmi yóò bẹ̀rù? OLÚWA ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóò bà mí? Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi láti jẹ ẹran-ara mi, àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi, wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú. Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi, ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù; bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi, nínú èyí ni ọkàn mi yóò le. Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ OLÚWA, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé OLÚWA ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà OLÚWA, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀. Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀; níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́; yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.
”Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀, OLÚWA yóò tẹ́wọ́ gbà mí.
”OLÚWA ni agbára mi àti asà mi; nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́. Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀ àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.
”OLÚWA Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́ ìwọ sì ti wò mí sàn. OLÚWA, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú, mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò. Kọ orin ìyìn sí OLÚWA, ẹ̀yin olódodo; kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́. Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀, ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé; Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́, Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.
”“Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi, nínú lílọ sí ihò mi? Eruku yóò a yìn ọ́ bí? Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ? Gbọ́, OLÚWA, kí o sì ṣàánú fún mi; ìwọ OLÚWA, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.” Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi; ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí, nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́. Ìwọ OLÚWA Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.
”Tẹ́ etí rẹ sí mi, gbà mí kíákíá; jẹ́ àpáta ààbò mi, jẹ́ odi alágbára láti gbà mí. Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi, nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.
”Ṣàánú fún mi, ìwọ OLÚWA, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú; ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn, ọkàn àti ara mi pẹ̀lú. Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn; agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi, egungun mi sì ti rún dànù. Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo, pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi, mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi; àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi. Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú; Èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.
”Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi àti àwọn onínúnibíni.
”Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi di gbígbó dànù nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́. Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára; agbára mi gbẹ tán gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.
”Wò ó, ojú OLÚWA wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin. Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.
”Angẹli OLÚWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká ó sì gbà wọ́n.
”Ojú OLÚWA ń bẹ lára àwọn olódodo; etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn. Ojú OLÚWA korò sí àwọn tí ń ṣe búburú; láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀. Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́, OLÚWA a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn. OLÚWA súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là. Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀, ṣùgbọ́n OLÚWA gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀. Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́; kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.
”Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni, nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn, mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀; mo fi àwẹ̀ pọ́n ara mi lójú. Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríba ní oókan àyà mi; èmí ń lọ kiri bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀ bí i ẹni wí pé fún ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́n mi ni. Èmí tẹríba nínú ìbànújẹ́ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ìyà rẹ̀.
”Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run! Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ. Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi; ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ. Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà: nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
”ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú, nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀. Ènìyàn búburú fa idà yọ, wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn, láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀, láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin. Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ, àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.
”Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin; nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
”Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ; kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀; wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi. Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́ nítorí òmùgọ̀ mi. Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́. Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi, Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ; mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi. OLÚWA, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ; ìmí ẹ̀dùn mi kò sápamọ́ fún ọ. Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀; bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.
”Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi; èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ. Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀ fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ a mú ẹwà rẹ parun bí kòkòrò aṣọ; nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo. “Gbọ́ àdúrà mi, OLÚWA, kí o sì fetí sí igbe mi; kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.
”Ó fà mí yọ gòkè láti inú ihò ìparun, láti inú ẹrẹ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta, ó sì jẹ́ kí ìgbésẹ̀ mi wà láìfòyà. Ó fi orin tuntun sí mi lẹ́nu, àní orin ìyìn sí Ọlọ́run wa. Ọ̀pọ̀ yóò rí i wọn yóò sì bẹ̀rù, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA.
”Ìwọ má ṣe, fa àánú rẹ tí ó rọ́nú sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; OLÚWA jẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ kí ó máa pa mi mọ́ títí ayérayé.
”OLÚWA yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀ yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀. Ní ti èmi, mo wí pé “OLÚWA, ṣàánú fún mi; wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
”Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi? Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi? Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run, nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín, Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi. Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi: nítorí náà, èmi ó rántí rẹ láti ilẹ̀ Jordani wá, láti Hermoni láti òkè Mibsari.
”Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run, sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi, èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù, ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi. Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí? Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi? Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run, nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
”Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. b Orin. Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú. Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí, tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
”Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run. A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè A ó gbé mi ga ní ayé. Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.
”Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé, Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.
”Kí o sì pè mí ní ọjọ́ ìpọ́njú, èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.”
”Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn; jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.
”Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.
”Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé, “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀, bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé, ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”
”Ó rà mí padà láìléwu kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.
”Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ OLÚWA yóò sì mú ọ dúró; òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.
”Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí, èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ. Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ, nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi? Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́, wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi. Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba Wọ́n ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.
”Kọ ẹkún mi sílẹ̀; kó omijé mi sí ìgò rẹ, wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?
”Nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi: ẹ̀rù kì yóò bà mí. Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi? Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ rẹ Ọlọ́run: èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ. Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú, kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.
”Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta. Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi, nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà. Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.
”Ṣùgbọ́n ìwọ, OLÚWA, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín Ìwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ; nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,
”Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára rẹ, n ó kọrin ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀; nítorí ìwọ ni ààbò mi, ibi ìsádi mi ní ìgbà ìpọ́njú. Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ; ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi.
”Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi. Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run; Tẹ́tí sí àdúrà mi. Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́, mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀; mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ. Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi, ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá. Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
”Fún adarí orin. Fun Jedutuni. Saamu Dafidi. Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi; ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà.
”Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi. Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ. Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò. Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run; Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi. Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn; tú ọkàn rẹ jáde sí i, nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.
”Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda. Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ, òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi, ara mi fà sí ọ, ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀ níbi tí kò sí omi. Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́, mo rí agbára àti ògo rẹ. Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ, ètè mi yóò fògo fún ọ. Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè, èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ. A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ; pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́. Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi; èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru. Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi, mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ. Ọkàn mí fà sí ọ: ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.
”Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́ Ọlọ́run gbé aláìlera kalẹ̀ nínú ìdílé, ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.
”Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú, Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi, títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀, àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn. Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run, ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run? Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá. Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀ Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo. Èmi yóò fi dùùrù mi yìn fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi; èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli. Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ: èmi, ẹni tí o rà padà.
”Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo; ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ? Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ. Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi àti ìpín mi títí láé.
”Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba; ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
”Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́ ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá OLÚWA àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọ́run alààyè. Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé, ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀, níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí: ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi. Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ; wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.
”Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́, nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.
”Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi; ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.
”Rántí bí ọjọ́ mi ti kúrú tó nítorí asán ha ni ìwọ fi ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn! Ta ni yóò wà láààyè tí kò ní rí ikú rẹ̀? Ta ló lè sá kúrò nínú agbára isà òkú?
”Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run OLÚWA, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
”Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè. Èmi yóò sọ nípa ti OLÚWA pé, “Òun ni ààbò àti odi mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”. Nítòótọ́ òun yóò gbà mí nínú ìdẹ̀kùn àwọn pẹyẹpẹyẹ àti nínú àjàkálẹ̀-ààrùn búburú. Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí, àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò; òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi. Ìwọ kì yóò bẹ̀rù nítorí ẹ̀rù òru, tàbí fún ọfà tí ń fò ní ọ̀sán, Tàbí fún àjàkálẹ̀-ààrùn tí ń rìn kiri ní òkùnkùn, tàbí fún ìparun tí ń rìn kiri ní ọ̀sán gangan. Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, ẹgbàárùn-ún ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣùgbọ́n kì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ
”Nítorí ìwọ fi OLÚWA ṣe ààbò rẹ, ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ. Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́ Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ. Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ; Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn, nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta. Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀; ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́; èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi. Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn; èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú, èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”
”Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi, ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.
”Ṣùgbọ́n, OLÚWA ti di odi alágbára mi, àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni tí mo ti ń gba ààbò.
”Saamu. Fún ọpẹ́ Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLÚWA, gbogbo ayé Ẹ fi ayọ̀ sin OLÚWA: Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn OLÚWA Ọlọ́run ni ó dá wa, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀ àti àgùntàn pápá rẹ̀. Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn; ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀. Nítorí tí OLÚWA pọ̀ ní oore ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé; àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.
”Àdúrà olùpọ́njú tí àárẹ̀ mú, tí ó sí ọkàn rẹ̀ payá níwájú OLÚWA Gbọ́ àdúrà mi, OLÚWA: Jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú. Dẹ etí rẹ sí mi; nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá. Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín; egungun mi sì jóná bí ààrò Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko; mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi. Nítorí ohùn ìkérora mi, egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.
”Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́ èmi sì rọ bí koríko. Ṣùgbọ́n ìwọ, OLÚWA, ni yóò dúró láéláé; ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.
”Ti Dafidi. Yin OLÚWA, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́. Yin OLÚWA, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀ Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́ tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn, Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
”Nítorí tí ó mọ dídá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá. Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko, ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó; Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀, kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́ OLÚWA ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ
”Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n, Síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn; Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn. Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn ó mú wọn rí àánú.
”Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n, ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn. Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè sí OLÚWA nínú ìdààmú wọn, ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn
”Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa. Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin, Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo, Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀; wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́. Ní ìgbà náà wọ́n ké pe OLÚWA nínú ìdààmú wọn, ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn Ó mú wọn jáde kúrò nínú òkùnkùn àti òjìji ikú, ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.
”Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú. Nígbà náà wọ́n kígbe sí OLÚWA nínú ìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú.
”Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ, nítorí OLÚWA ṣe dáradára sí ọ. Nítorí ìwọ, OLÚWA, ti gba ọkàn mi kúrò lọ́wọ́ ikú, ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé, àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú, Nítorí èmi yóò máa rìn níwájú OLÚWA ní ilẹ̀ alààyè.
”Iyebíye ní ojú OLÚWA àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
”Nínú ìrora mi, mo sọkún sí OLÚWA, ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀. OLÚWA ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
”Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ. Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ.
”Èmi kì yóò kú, ṣùgbọ́n èmi yóò yè, èmi yóò pòkìkí ohun tí OLÚWA ṣe.
”OLÚWA bá mi wí gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.
”Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀; ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
”Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́; fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
”Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí: ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
”Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà, ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.
”Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
”Èmi mọ, OLÚWA, nítorí òfin rẹ òdodo ni, àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú. Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ. Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè, nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi.
”Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi, èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi. Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé, nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́
”A pọ́n mi lójú gidigidi; OLÚWA, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ
”Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi, ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi,
”Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ OLÚWA wá Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
”OLÚWA yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo yóò pa ọkàn rẹ mọ́ OLÚWA yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́ láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.
”Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn yóò fi ayọ̀ ka. Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí rẹ̀.
”Èmi dúró de OLÚWA, ọkàn mi dúró, àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí Ọkàn mi dúró de OLÚWA, ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ, àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.
”Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. OLÚWA, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì, yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì; Ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn; nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi. Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò, oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.
”Èmi mọ̀ pé, OLÚWA yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró, yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà
”Maskili ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú ihò òkúta. Àdúrà. Èmi kígbe sókè sí OLÚWA; Èmi gbé ohùn mi sókè sí OLÚWA fún àánú. Èmi tú àròyé mí sílẹ̀ níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀. Nígbà tí ẹ̀mí mi ṣàárẹ̀ nínú mi, ìwọ ni ẹni tí ó mọ ọ̀nà mi. Ní ipa ọ̀nà tí èmi ń rìn ènìyàn ti dẹ okùn fún mi ní ìkọ̀kọ̀ Wo ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó sì rì i kò sí ẹni tí ó ṣe àníyàn mi èmi kò ní ààbò; kò sí ẹni tí ó náání ọkàn mi. Èmi kígbe sí ọ, OLÚWA: èmi wí pé, “ìwọ ni ààbò mi, ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.” Fi etí sí igbe mi, nítorí tí èmi wà nínú àìnírètí gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi, nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ Mú ọkàn mi jáde kúrò nínú túbú, kí èmi lè máa yin orúkọ rẹ. Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò yí mi káàkiri nítorí ìwọ yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ba mi ṣe.
”Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ: òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela. Dá mi lóhùn kánkán, OLÚWA; ó rẹ ẹ̀mí mi tán. Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi kí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò
”OLÚWA wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́. Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ; ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n. OLÚWA dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni búburú ní yóò parun. Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn OLÚWA. Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.
”Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa OLÚWA, tú àwọn oǹdè sílẹ̀ (ẹlẹ́wọ̀n) OLÚWA mú àwọn afọ́jú ríran, OLÚWA, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga, OLÚWA fẹ́ràn àwọn olódodo. OLÚWA ń dá ààbò bo àwọn àlejò ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
”Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
”Gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ; Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ. Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ bẹ̀rù OLÚWA kí o sì kórìíra ibi. Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ àti okun fún àwọn egungun rẹ.
”Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.
”Inú dídùn máa ń mú kí ojú túká ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run.
”Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi, ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.
”Orúkọ OLÚWA, ilé ìṣọ́ agbára ni; olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.
”Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.
”Ikú àti ìyè ń bẹ nípa ahọ́n wọn, àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹ ẹ́.
”Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó! Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là; fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà.
”Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora; Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́. “Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnrawọn fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun
”Àsìkò wà fún ohun gbogbo, àti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run. Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú, ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu. Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú láradá ìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́. Ìgbà láti sọkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rín ìgbà láti ṣọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó
”Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju ibi àsè nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn kí alààyè ní èyí ní ọkàn. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ, ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le. Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá.
”Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn, ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó Ọlọ́run tí ó dá èkínní náà ni ó dá èkejì nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀.
”Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́? Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe? Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́, gbogbo ọkàn yín sì ti pòruurù. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dé àtàrí yín kò sí àlàáfíà rárá, àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa àti ojú egbò, tí a kò nù kúrò tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.
”Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà, wọ́n bú sí orin.
”OLÚWA yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn kan bá Ejibiti jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí OLÚWA, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.
”Pẹ̀lú èyí, ìrora mu mi lára gírígírí, ìrora gbá mi mú, gẹ́gẹ́ bí i ti obìnrin tí ń rọbí, Mo ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́, ọkàn mi pòruurù nípa ohun tí mo rí.
”Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì sá, ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un, àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́; wọ́n ti pa àwọn òfin run wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́. Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run; àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn. Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù, àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.
”Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣì ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀ ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru. Nítorí pé èémí àwọn ìkà dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri
”Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. OLÚWA Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù, kúrò ní ojú gbogbo wọn; Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLÚWA ni ó ti sọ ọ́.
”Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin, nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ. Gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA títí láé, nítorí OLÚWA, OLÚWA ni àpáta ayérayé náà.
”OLÚWA, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa; ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ ni ó ṣe é fún wa.
”Síbẹ̀síbẹ̀ OLÚWA sì fẹ́ ṣíjú àánú wò ọ́; ó dìde láti ṣàánú fún ọ. Nítorí OLÚWA jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é! Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò fi ara sin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn. Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsì, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.”
”Fún ọwọ́ àìlera lókun, mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun: Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù; Ọlọ́run yín yóò wá, òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san; pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́ òun yóò wá láti gbà yín là.” Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́. Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀. Odò yóò tú jáde nínú aginjù àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.
”Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀: a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà Mímọ́. Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà; yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà, àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá. Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀, tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀; a kì yóò rí wọn níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀, àwọn ẹni ìràpadà OLÚWA yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin; ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí. Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn, ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.
”Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú, ni Ọlọ́run yín wí. Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu kí o sì kéde fún un pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí, pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ OLÚWA ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
”Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn: Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀. Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀; ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní.
”Ìwọ kò tí ì mọ̀? Ìwọ kò tí ì gbọ́? OLÚWA òun ni Ọlọ́run ayérayé, Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé. Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀, àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀. Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀ ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá. Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú; ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun. Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì; wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn, wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.
”Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.
”“Àwọn tálákà àti aláìní wá omi, ṣùgbọ́n kò sí; ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n Èmi OLÚWA yóò dá wọn lóhùn; Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
”Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí OLÚWA wí nìyìí ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Israẹli: “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè; Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe. Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ; àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá, kò ní jó ọ; ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
”Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn mo mú àlàáfíà wá, mo sì dá àjálù; Èmi OLÚWA ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.
”Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró. Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ; Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.
”Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bí i fàdákà; Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.
”Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n. Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn, tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi.
”Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run; yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé; bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá! Nítorí OLÚWA tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni tí a ń pọ́n lójú.
”Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.
”Dájúdájú, OLÚWA yóò tu Sioni nínú yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀; Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni, àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà OLÚWA. Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.
”Àwọn ẹni ìràpadà OLÚWA yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ; ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn. Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò. “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú. Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara, àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,
”Ta ni ó ti gba ìròyìn in wa gbọ́ àti ta ni a ti fi apá OLÚWA hàn fún? Òun dàgbàsókè níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ irúgbìn, àti gẹ́gẹ́ bí i gbòǹgbò tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀. Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀ tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́rí i rẹ̀. A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí. Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá. Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú, síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù, tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú. Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa; ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀, àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá. Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; OLÚWA sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀ gbogbo àìṣedéédéé wa. A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀; a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà, àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀. Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ, ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀? Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè; nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú. A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan, tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀. Síbẹ̀, ó wu OLÚWA láti pa á lára àti láti mú kí ó jìyà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLÚWA fi ayé rẹ̀ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé rẹ̀ yóò pẹ́ títí, àti ète OLÚWA ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀, òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre, Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn. Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára, nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú, tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá. Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.
”“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́. Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù. Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.
”Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀ ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun Ìpayà la ó mú kúrò pátápátá; kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
”Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan, àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́ ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi. Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ OLÚWA, èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,” ni OLÚWA wí.
”Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀ a ó sì darí i yín lọ ní àlàáfíà; òkè ńláńlá àti kéékèèkéé yóò bú sí orin níwájú yín àti gbogbo igi inú pápá yóò máa pàtẹ́wọ́.
”Gbogbo àwọn tí ń rìn déédé ń wọ inú àlàáfíà; wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn nínú ikú.
”Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́: “Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.
”Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn; Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá, ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli. Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,” ni OLÚWA wí, “Àti pé Èmi yóò wo wọ́n sàn.”
”Ǹjẹ́ èyí ha ni irú àwẹ̀ tí mo yàn bí, ọjọ́ kan ṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀? Ó ha jẹ pe kí ènìyàn tẹ orí rẹ̀ ba bí i koríko lásán ni bí àti sísùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú? Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní àwẹ̀ nìyí, ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún OLÚWA? “Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí: láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo àti láti tú gbogbo okùn àjàgà, láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀ àti láti fọ́ gbogbo àjàgà? Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri. Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó, àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn?
”Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀ àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá; nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ, ògo OLÚWA yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ. Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí OLÚWA yóò sì dáhùn; ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé: Èmi nìyí. “Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára, nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ, àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn, nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn, àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan. OLÚWA yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo; òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀ yóò sì fún egungun rẹ lókun. Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára, àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.
”Ẹ̀mí OLÚWA Olódùmarè wà lára mi nítorí OLÚWA ti fi ààmì òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn tálákà. Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́ láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n, Láti kéde ọdún ojúrere OLÚWA àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa, láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú, àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú, òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo, irúgbìn OLÚWA láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.
”Nínú gbogbo ìpọ́njú wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́ àti angẹli tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là. Nínú ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà; ó gbé wọn sókè ó sì pọ̀n wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì.
”“Kíyèsi i, Èmi yóò dá àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́, tàbí kí wọn wá sí ọkàn. Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá, nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀. Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi; ariwo ẹkún àti igbe ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́.
”Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”
”“Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA, tí ó sì fi OLÚWA ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀. Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru, gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”
”Wò mí sàn OLÚWA, èmi yóò di ẹni ìwòsàn, gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà, nítorí ìwọ ni ìyìn mi.
”Nítorí mo mọ èrò tí mo rò sí yín,” ni OLÚWA wí, “àní èrò àlàáfíà, kì í sì ṣe fún ibi, èrò láti fún un yín ní ìgbà ìkẹyìn àti ìrètí ọjọ́ iwájú. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín. Ẹ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi: ẹ̀yin yóò rí mi ni OLÚWA Ọlọ́run wí.
”Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín, èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni OLÚWA wí, ‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’
”Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káàánú lọ́rùn.” Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.
”“ ‘Wò ó, èmi ó mú ọ̀já àti oògùn ìmúláradá dì í; èmi ó wo àwọn ènìyàn mi sàn. Èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó jẹ ìgbádùn lọ́pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́.
”Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́. Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
”Nítorí ìfẹ́ OLÚWA tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀. Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni OLÚWA; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́. Dídára ni OLÚWA fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a. Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà OLÚWA.
”Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀. Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.
”O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́, o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.” OLÚWA, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò, o ra ẹ̀mí mi padà.
”Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò, ebi sì yó wa bí àárẹ̀.
”Èmi yóò ṣe ìtọ́jú wọn ní pápá oko tútù dáradára, àní orí àwọn òkè gíga ti Israẹli ni yóò jẹ́ ilẹ̀ ìjẹ koríko wọ́n. Níbẹ̀ wọn yóò dùbúlẹ̀ ní ilẹ̀ ìjẹ koríko dídára, níbẹ̀ wọn yóò jẹun ní pápá oko tútù tí ó dara ní orí òkè ti Israẹli. Èmi fúnra mi yóò darí àgùntàn mi, èmi yóò mú wọn dùbúlẹ̀, ni OLÚWA Olódùmarè wí. Èmi yóò ṣe àwárí àwọn tí ó nú, èmi yóò mú àwọn tí ó ń rin ìrìn àrè kiri padà. Èmi yóò di ọgbẹ́ àwọn tí ó fi ara pa, èmi yóò sì fún àwọn aláìlágbára ni okun, ṣùgbọ́n àwọn tí ó sanra tí ó sì ni agbára ní èmi yóò parun. Èmi yóò ṣe olùṣọ́ àwọn agbo ẹran náà pẹ̀lú òdodo.
”Nígbà náà, ni Nebukadnessari sọ wí pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ẹni tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àṣẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn.
”Ọlọ́run mi rán angẹli i rẹ̀, ó sì dí àwọn kìnnìún lẹ́nu. Wọn kò le è pa mí lára, nítorí a rí mi gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀ ní iwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò hu ìwà ìbàjẹ́ kan níwájú rẹ ìwọ ọba.” Inú ọba dùn gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a mú Daniẹli jáde wá láti inú ihò. Nígbà tí a mú Daniẹli jáde nínú ihò, kò sí ojú ọgbẹ́ kan ní ara rẹ̀, nítorí tí ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.
”Ó ń yọ ni, ó sì ń gbani là; ó ń ṣe iṣẹ́ ààmì àti ìyanu ní ọ̀run àti ní ayé. Òun ló gba Daniẹli là kúrò lọ́wọ́ agbára kìnnìún.”
”“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ OLÚWA ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá Ó ti pa wá lára ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀
”“Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú. Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú Ikú, àjàkálẹ̀-ààrùn rẹ dà? Isà òkú, ìparun rẹ dà? “Èmi kò ní ṣàánú mọ́.
”“Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín. Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòrò ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ àwọn ogun ńlá mi tí mo rán sí àárín yín. Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó ẹ ó sì yín orúkọ OLÚWA Ọlọ́run yín, ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò; ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé.
”Ó sì wí pé: “Nínú ìpọ́njú mi ni mo kígbe sí OLÚWA, òun sì gbọ́ ohùn mi. Mo kígbe láti inú ipò òkú, mo pè fún ìrànwọ́, ìwọ sì gbọ́ ohùn mi.
”OLÚWA Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là. Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀; Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”
”Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, oòrùn òdodo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúláradá ni ìyẹ́ apá rẹ̀. Ẹ̀yin yóò sì jáde lọ, ẹ̀yin yóò sì máa fò fún ayọ̀ bi àwọn ẹgbọrọ màlúù tí a tú sílẹ̀ lórí ìso.
”Nígbà tí Herodu rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà. Nígbà náà ni èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wá ṣẹ pé: “A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ohùn réré ẹkún àti ọ̀fọ̀ ńlá, Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kọ̀ láti gbìpẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”
”Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn. Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn.
”“Alábùkún fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run. Alábùkún fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a ó tù wọ́n nínú.
”Alábùkún fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí, nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run. “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, tiwọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ̀, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.
”Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.
”“Nítorí náà, mo wí fún yín, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ ó jẹ àti èyí tí ẹ ó mu; tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ ó wọ̀. Ṣé ẹ̀mí kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ tàbí ara ni kò ha ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ? Ẹ wo àwọn ẹyẹ ojú ọrun; wọn kì í gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kójọ sínú àká, síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí? Ta ni nínú gbogbo yín nípa àníyàn ṣíṣe ti ó lè fi ìṣẹ́jú kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀? “Kí ni ìdí ti ẹ fi ń ṣe àníyàn ní ti aṣọ? Ẹ wo bí àwọn lílì tí ń bẹ ní igbó ti ń dàgbà. Wọn kì í ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú. Bẹ́ẹ̀ ni mo wí fún yín pé, a kò ṣe Solomoni lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ bẹ́ẹ̀, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí ti a sì gbà sínú iná lọ́la, kò ha ṣe ni ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́ tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? Nítorí náà, ẹ má ṣe ṣe àníyàn kí ẹ sì máa wí pé, ‘Kí ni àwa yóò jẹ?’ Tàbí ‘Kí ni àwa yóò mu?’ Tàbí ‘Irú aṣọ wo ni àwa yóò wọ̀?’ Nítorí àwọn kèfèrí ń fi ìwọra wá àwọn nǹkan wọ̀nyí bẹ́ẹ̀ ni Baba yín ní ọ̀run mọ̀ dájúdájú pé ẹ ní ìlò àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba Ọlọ́run ná àti òdodo rẹ̀, yóò sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín pẹ̀lú. Nítorí náà, ẹ má ṣe àníyàn ọ̀la, ọ̀la ni yóò ṣe àníyàn ara rẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.
”“Béèrè, a ó sì fi fún yín; wá kiri, ẹ̀yin yóò sì rí; kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó béèrè ń rí gbà, ẹni tí ó bá sì wà kiri ń rí, ẹni bá sì kànkùn ni a yóò ṣi sílẹ̀ fún.
”Sì wò ó, adẹ́tẹ̀ kan wà, ó wá ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ ó wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mi di mímọ́.” Jesu sì nà ọwọ́ rẹ̀, ó fi bà á, ó wí pé, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́.” Lójúkan náà, ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sì mọ́!
”Nígbà tí Jesu sì wọ̀ Kapernaumu, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ ààrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.” Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.” Balógun ọ̀rún náà dáhùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹni kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.” Nígbà tí Jesu gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Israẹli tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí. Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Abrahamu àti Isaaki àti Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.” Nítorí náà Jesu sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ náà láradá ní wákàtí kan náà.
”Nígbà tí Jesu sì dé ilé Peteru, ìyá ìyàwó Peteru dùbúlẹ̀ àìsàn ibà. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
”Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn ọlọ́kùnrùn láradá. Kí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé: “Òun tìkára rẹ̀ gbà àìlera wa, ó sì ń ru ààrùn wa.”
”Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì líle dìde lórí Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jesu ń sùn. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, “Olúwa, gbà wá! Àwa yóò rì!” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú Òkun náà wí, gbogbo rẹ̀ sì parọ́rọ́.
”Nígbà ti ó sì dé apá kejì ní ilẹ̀ àwọn ara Gadara, àwọn ọkùnrin méjì ẹlẹ́mìí èṣù ti inú ibojì wá pàdé rẹ̀. Wọn rorò gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò le kọjá ní ọ̀nà ibẹ̀. Wọ́n kígbe lóhùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tàwa tìrẹ, Ìwọ Ọmọ Ọlọ́run? Ìwọ ha wá láti dá wa lóró ṣáájú ọjọ́ tí a yàn náà?” Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá tí ń jẹ ń bẹ ní ọ̀nà jíjìn díẹ̀ sí wọn Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ Jesu wí pé, “Bí ìwọ bá lé wa jáde, jẹ́ kí àwa kí ó lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ yìí.” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ!” Nígbà tí wọn sì jáde, wọn lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà; sì wò ó, gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ bèbè odò bọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé nínú omi.
”Àwọn ọkùnrin kan gbé arọ kan tọ̀ ọ́ wá lórí àkéte rẹ̀. Nígbà tí Jesu rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ tújúká, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Nígbà yìí ni àwọn olùkọ́ òfin wí fún ara wọn pé, “Ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀-òdì!” Jesu sì mọ̀ èrò inú wọn, ó wí pé, “Nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe ń ro búburú nínú yín? Èwo ni ó rọrùn jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ;’ tàbí wí pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn?’ Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ni.” Ó sì wí fún arọ náà pé, “Dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ.” Ọkùnrin náà sì dìde, ó sì lọ ilé rẹ̀.
”Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́ èyí, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá.
”Sì kíyèsi i, obìnrin kan ti ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá, ó wá lẹ́yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀. Nítorí ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à le fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” Nígbà tí Jesu sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradà.” A sì mú obìnrin náà láradá ni wákàtí kan náà.
”Nígbà tí Jesu sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afunfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń pariwo. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà. Ṣùgbọ́n nígbà tí a ti àwọn ènìyàn jáde, ó wọ ilé, ó sì fà ọmọbìnrin náà ní ọwọ́ sókè; bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin náà sì dìde.
”Nígbà tí Jesu sì jáde níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n ń kígbe sókè wí pé, “Ṣàánú fún wa, ìwọ ọmọ Dafidi.” Nígbà tí ó sì wọ̀ ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ wá, Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo le ṣe èyí?” Wọn sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ìwọ lè ṣe é.” Ó sì fi ọwọ́ bà wọ́n ní ojú, ó wí pé, “Kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.” Ojú wọn sì là; Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi, wí pé, “Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan kí ó mọ̀ nípa èyí.”
”Bí wọ́n tí ń jáde lọ, wò ó wọ́n mú ọkùnrin odi kan tí ó ní ẹ̀mí èṣù tọ Jesu wá. Nígbà tí a lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin tí ó ya odi sì fọhùn. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, wọ́n wí pé, “A kò rí irú èyí rí ní Israẹli.”
”Jesu sì rìn yí gbogbo ìlú ńlá àti ìletò ká, ó ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn, ó sì ń wàásù ìhìnrere ìjọba ọrun, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn àti gbogbo àìsàn ní ara àwọn ènìyàn.
”Jesu sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn ààrùn àti àìsàn gbogbo.
”Ẹ máa ṣe ìwòsàn fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn òkú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fi fún ni.
”Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa Ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run àpáàdì. Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin. Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé. Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà; ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.
”Ẹni tí ó bá wa ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i.
”Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì.
”“Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wíwúwo lé lórí, èmi yóò sì fún yín ní ìsinmi. Ẹ gbé àjàgà mi wọ̀. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi nítorí onínútútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi, ẹ̀yin yóò sì ri ìsinmi fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mi sì fúyẹ́.”
”ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ wà níbẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ènìyàn láradá ní ọjọ́ ìsinmi?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ wí pé bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ní àgùntàn kan ṣoṣo, tí ó sì bọ́ sínú kòtò ní ọjọ́ ìsinmi, ǹjẹ́ kì yóò dìímú, kí ó sì fà á jáde. Ǹjẹ́ mélòó mélòó ní ènìyàn ní iye lórí ju àgùntàn kan lọ! Nítorí náà ó yẹ láti ṣe rere ní ọjọ́ ìsinmi.” Nígbà náà, ó sì wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ,” bí òun sì ti nà án, ọwọ́ rẹ̀ sì bọ̀ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ èkejì.
”Nígbà tí Jesu sì mọ̀, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá.
”Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹ̀mí èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jesu sì mú un láradá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran.
”Ẹni tí ó sì gba irúgbìn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ orí àpáta, ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, lọ́gán, ó sì fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà. Ṣùgbọ́n nítorí kò ní gbòǹgbò, ó wà fún ìgbà díẹ̀; nígbà tí wàhálà àti inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà ní ojú kan náà yóò sì kọsẹ̀.
”Nígbà ti Jesu gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ó sì mú àwọn aláìsàn láradá.
”Nígbà tiwọn mọ̀ pé Jesu ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká. Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá. Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.
”Obìnrin kan láti Kenaani, tí ó ń gbé ibẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ó ń bẹ̀bẹ̀, ó sì kígbe pé, “Olúwa, ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi; ọmọbìnrin mi ní ẹ̀mí èṣù ti ń dá a lóró gidigidi.” Ṣùgbọ́n Jesu kò fún un ní ìdáhùn, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á níyànjú pé, “Lé obìnrin náà lọ, nítorí ó ń kígbe tọ̀ wá lẹ́yìn.” Ó dáhùn pé, “Àgùntàn ilẹ̀ Israẹli tí ó nù nìkan ni a rán mi sí.” Obìnrin náà wá, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ sí i pé, “Olúwa ṣàánú fún mi.” Ó sì dáhùn wí pé, “Kò tọ́ kí a gbé oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.” Obìnrin náà sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ajá a máa jẹ èrúnrún tí ó ti orí tábìlì olówó wọn bọ́ sílẹ̀.” Jesu sì sọ fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ ńlá ni tìrẹ! A sì ti dáhùn ìbéèrè rẹ.” A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ láradá ní wákàtí kan náà.
”Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, àti àwọn arọ, afọ́jú, amúnkùn ún, odi àti ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn mìíràn. Wọ́n gbé wọn kalẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. Òun sì mú gbogbo wọn láradá. Ẹnu ya ọ̀pọ̀ ènìyàn nígbà tí wọ́n rí àwọn odi tó ń sọ̀rọ̀, amúnkùn ún tó di alára pípé, arọ tí ó ń rìn àti àwọn afọ́jú tí ó ríran. Wọ́n sì ń fi ìyìn fún Ọlọ́run Israẹli.
”Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ ìjọ ènìyàn, ọkùnrin kan tọ̀ Jesu wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa, ṣàánú fún ọmọ mi, nítorí tí ó ní wárápá. Ó sì ń joró gidigidi, nígbà púpọ̀ ni ó máa ń ṣubú sínú iná tàbí sínú omi. Mo sì ti mú un tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn.” Jesu sì dáhùn wí pé, “A! Ẹ̀yìn alágídí ọkàn àti aláìgbàgbọ́ ènìyàn, èmi yóò ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi ó sì ti fi ara dà á fún yín tó? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín yìí.” Nígbà náà ni Jesu bá ẹ̀mí èṣù tí ó ń bẹ nínú ọmọkùnrin náà wí, ó sì fi í sílẹ̀, à mú ọmọkùnrin náà láradá láti ìgbà náà lọ.
”Jesu sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí hóró musitadi, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Sípò kúrò níhìn-ín yìí,’ òun yóò sì ṣí ipò. Kò sì ní sí ohun tí kò ní í ṣe é ṣe fún yín.”
”Nítorí náà, bí ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ rẹ yóò bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀, gé e kúrò, kí o sì jù ú nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run ní akéwọ́ tàbí akésẹ̀ ju pé kí o ni ọwọ́ méjì àti ẹsẹ̀ méjì ki a sì sọ ọ́ sínú iná ayérayé. Bí ojú rẹ yóò bá sì mú kí o dẹ́ṣẹ̀, yọ ọ́ kúrò kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti lọ sínú ìyè pẹ̀lú ojú kan, ju pé kí o ní ojú méjì, kí a sì jù ọ́ sí iná ọ̀run àpáàdì.
”Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ni kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, pé ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kí ó ṣègbé.
”Àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì sì jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, nígbà tí wọ́n sí gbọ́ pé Jesu ń kọjá lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé, “Olúwa, Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún wa!” Àwọn ènìyàn sí bá wọn wí pé kí wọn dákẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n kígbe sókè sí i. “Olúwa, ọmọ Dafidi, ṣàánú fún wa!” Jesu dúró lójú ọ̀nà, ó sì pè wọ́n, Ó béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ṣe fún yín?” Wọ́n dáhùn pé, “Olúwa, àwa fẹ́ kí a ríran.” Àánú wọn sì ṣe Jesu, ó fi ọwọ́ kan ojú wọn. Lójúkan náà, wọ́n sì ríran, wọ́n sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
”A sì mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní tẹmpili, ó sì mú wọ́n láradá
”Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin bá lè ní ìgbàgbọ́ láìṣiyèméjì, nígbà náà ẹ̀yin yóò lè ṣe irú ohun tí a ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́, Ẹ̀yin yóò lè sọ fún òkè yìí pé, ‘Yí ipò padà sínú Òkun,’ yóò sì rí bẹ́ẹ̀. Bí ẹ̀yin bá gbàgbọ́, ẹ̀yin lè rí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè nínú àdúrà gbà.”
”“Nígbà náà ni a ó sì dá a yín lóró. A ó pa yín, a ó sì kórìíra yín ni gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ tèmi. Àti pé, ọ̀pọ̀ nínú yín yóò kọsẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣòfófó ara yín, ẹ̀yin yóò kórìíra ara yín pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ àwọn èké wòlíì yóò farahàn, wọn yóò tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ yóò wà níbi gbogbo, yóò sì sọ ìfẹ́ ọ̀pọ̀ di tútù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbàlà.
”Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí. “Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé. Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú.
”Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’
”Peteru wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ láti kú pẹ̀lú, èmi kò jẹ́ sẹ́ ọ.” Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí.
”Ó sì mú Peteru àti àwọn ọmọ Sebede méjèèjì Jakọbu àti Johanu pẹ̀lú rẹ̀, ìrora àti ìbànújẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí gba ọkàn rẹ̀. Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi gbọgbẹ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́ títí dé ojú ikú, ẹ dúró níhìn-ín yìí, kí ẹ máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.” Òun lọ sí iwájú díẹ̀ sí i, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ó bá ṣe é ṣe, jẹ́ kí a mú ago yìí ré mi lórí kọjá, ṣùgbọ́n ìfẹ́ tìrẹ ni mo fẹ́ kí ó ṣẹ, kì í ṣe ìfẹ́ tèmi.”
”Nígbà náà ni Pilatu dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí òun ti na Jesu tán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti mú un lọ kàn mọ́ àgbélébùú.
”Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti kàn án mọ́ àgbélébùú, wọ́n dìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn.
”Níwọ̀n wákàtí kẹsànán ní Jesu sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Eli, Eli, Lama Sabakitani” (ní èdè Heberu). Ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”
”Ní àsìkò náà gan an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú Sinagọgu wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jesu ti Nasareti? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!” Jesu si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúrò lára rẹ̀.” Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e ṣánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà.
”Ìyá ìyàwó Simoni tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jesu nípa rẹ̀. Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójúkan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
”Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí oòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá. Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà. Jesu sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú ààrùn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í ṣe.
”Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbègbè Galili, ó ń wàásù nínú Sinagọgu. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Ọkùnrin adẹ́tẹ̀ kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìmúláradá. Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè mú mi láradá.” Jesu kún fún àánú, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó fi ọwọ́ rẹ̀ bà a, ó wí pé, “Èmí fẹ́. Di mímọ́.” Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ náà fi sílẹ̀ lọ, ọkùnrin náà sì rí ìwòsàn.
”Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé. Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jesu, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jesu wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu. Nígbà tí Jesu sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé, “Èéṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? Ó ń sọ̀rọ̀-òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?” Lójúkan náà bí Jesu tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yìn fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín? Èwo ni ó rọrùn jù láti wí fún arọ náà pé: ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ,’ tàbí wí pé, ‘Dìde sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?’ Ṣùgbọ́n kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ji ni.” Ó wí fún ọkùnrin arọ náà pé, “Mo wí fún ọ, dìde, gbé àkéte rẹ kí ó sì máa lọ ilé rẹ.” Lójúkan náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀. Ó gbé àkéte rẹ̀. Ó sì jáde lọ lójú gbogbo wọn. Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, “Àwa kò rí irú èyí rí!”
”Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún wọn wí pé, “Àwọn tí ara wọ́n dá kò wa oníṣègùn, bí ko ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá láti sọ fún àwọn ènìyàn rere láti ronúpìwàdà, bí kò ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
”Nígbà tí Jesu wá sí Sinagọgu. Sì kíyèsi i ọkùnrin kan wà níbẹ̀, tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Àwọn kan nínú wọn sì ń wa ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu, Nítorí náà, wọ́n ń ṣọ́ Ọ bí yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi. Jesu wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé, “Dìde dúró ní iwájú ìjọ ènìyàn.” Nígbà náà ni Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì. Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá.
”Nítorí tí ó mú ọ̀pọ̀ ènìyàn láradá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aláìsàn ló bí ara wọn lù ú láti fi ọwọ́ kàn án. Ìgbàkúgbà tí àwọn tí ó ni ẹ̀mí àìmọ́ bá ti fojú ri, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọn a sì kígbe lóhùn rara wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”
”Ó yan àwọn méjìlá, kí wọn kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí ó lè rán wọn lọ láti wàásù àti láti lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí Èṣù jáde.
”Bákan náà, àwọn tí ó bọ́ sórí àpáta, ni àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kò ni gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n á wà fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà nígbà ti wàhálà tàbí inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà, wọ́n á kọsẹ̀.
”Ìjì líle ńlá kan sì dìde, omi sì ń bù sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í kún fún omi, ó sì fẹ́rẹ rì. Jesu ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i lóhùn rara wí pé, “Olùkọ́ni, tàbí ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ rì?” Ó dìde, ó bá ìjì líle náà wí, ó sì wí fún òkun pé, “Dákẹ́! Jẹ́ẹ́!” Ìjì náà sì dá, ìparọ́rọ́ ńlá sì wà. Lẹ́yìn náà, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣojo bẹ́ẹ̀? Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ì ní ìgbàgbọ́ síbẹ̀síbẹ̀?”
”Bí Jesu sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀. Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ibojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é. Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọ́n ti ń fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹsẹ̀ rẹ̀. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀. Tọ̀sán tòru láàrín àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀. Nígbà tí ó sì rí Jesu látòkèrè, ó sì sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tèmi tìrẹ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” Nítorí tí Ó wí fún un pé, “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!” Jesu sì bi í léèrè pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì dáhùn wí pé, “Ligioni, nítorí àwa pọ̀.” Nígbà náà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jesu gidigidi, kí ó má ṣe rán àwọn jáde kúrò ní agbègbè náà. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan sì ń jẹ lẹ́bàá òkè. Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ Jesu pé, “Rán wa lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọ̀n-ọn-nì kí àwa le è wọ inú wọn lọ.” Jesu fún wọn láààyè, àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà tí ó tó ìwọ̀n ẹgbàá sì túká lọ́gán, wọ́n sì sáré lọ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè rọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé.
”Obìnrin kan sì wà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá. Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i. Nígbà tí ó sì gbúròó iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì gbẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun sì mọ̀ lára rẹ̀ pé, a mú òun láradá kúrò nínú ààrùn náà.
”Bí Jesu sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jairu olórí Sinagọgu wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jesu lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù. Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.” Nígbà náà, Jesu dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jairu, bí kò ṣe Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin Jakọbu. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jesu rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún. Ó wọ inú ilé lọ, o sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohùnréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.” Wọ́n sì fi í rẹ́rìn-ín. Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí. Ó gbá a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Talita kuumi” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, dìde dúró). Lẹ́sẹ̀kan náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì bà wọ́n, ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi.
”Nítorí àìgbàgbọ́ wọn, òun kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá láàrín wọn, àfi àwọn aláìsàn díẹ̀ tí ó gbé ọwọ́ lé lórí, tí wọ́n sì rí ìwòsàn.
”Wọ́n lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. Wọ́n sì ń fi òróró kun orí àwọn tí ara wọn kò dá, wọ́n sì mú wọn láradá.
”Wéré, wọ́n ròyìn dídé rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn sáré gbé gbogbo àwọn aláìsàn lórí àkéte wọn wá pàdé rẹ̀. Ní ibi gbogbo tí ó sì dé, yálà ní abúlé, ìlú ńlá tàbí àrọ́ko, ń ṣe ni wọ́n ń kó àwọn aláìsàn pàdé rẹ̀ ní àárín ọjà. Wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí wọn fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ kàn án ni a mú láradá.
”Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jesu, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. Giriki ní obìnrin náà, Siro-Fonisia ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ó bẹ Jesu kí ó bá òun lé ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ọmọbìnrin òun. Jesu sọ fún obìnrin yìí pé, “Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí a fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ lọ́rùn ná. Nítorí kò tọ́ kí a mú oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.” Obìnrin náà dáhùn wí pé, “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yín Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ajá pàápàá a máa ní àǹfààní láti jẹ èérún oúnjẹ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tábìlì.” “Ó sì wí fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.” Nígbà tí ó padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀.
”Níbẹ̀ ọkùnrin kan tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Jesu, àwọn ènìyàn sì bẹ Jesu pé kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e. Jesu sì mú ọkùnrin náà kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sì fi àwọn ìka rẹ̀ sí etí ọkùnrin náà, ó tu itọ́ ṣọ́wọ́. Ó sì fi kan ahọ́n rẹ̀. Nígbà náà ni Jesu wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, “Efata!” (èyí ni, “Ìwọ ṣí!”). Lójúkan náà, etí rẹ̀ sì ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì ń sọ̀rọ̀ ketekete. Jesu pàṣẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà níbẹ̀ pé kí wọn má ṣe tan ìròyìn náà ká. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń pa wọ́n lẹ́nu mọ́ tó, náà ni wọ́n ń tan ìròyìn náà káàkiri tó. Àwọn ènìyàn sì kún fún ìyanu, wọ́n wí pé, “Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, Ó mú kí adití gbọ́rọ̀, odi sì sọ̀rọ̀.”
”Nígbà tí wọ́n dé Betisaida, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ kàn án, kí ó sì wò ó sàn. Jesu fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yìn ìlú. Ó tu itọ́ sí i lójú. Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú náà. Ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lè rí ohunkóhun nísinsin yìí?” Ọkùnrin náà wo àyíká rẹ̀, ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, mo rí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n n kò rí wọn kedere, wọ́n n rìn kiri bí àgékù igi.” Nígbà náà, Jesu tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere.
”Ọkùnrin kan láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, “Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn. Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́. Àti pé, nígbàkúgbà tí ó bá mú un, á gbé e ṣánlẹ̀, a sì máa hó itọ́ lẹ́nu, a sì máa lọ́ eyín rẹ̀. Òun pàápàá a wá le gbàgìdì. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kí wọn lé ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, ṣùgbọ́n wọ́n kò lè ṣe é.” Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí pé, “Ẹ̀yin ìran aláìgbàgbọ́ yìí, Èmi yóò ti bá a yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti mú sùúrù fún un yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá sọ́dọ̀ mi.” Wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ rẹ̀: nígbà tí ó sì rí i, lójúkan náà ẹ̀mí náà nà án tàntàn ó sì ṣubú lu ilẹ̀, ó sì ń fi ara yílẹ̀, ó sì ń yọ ìfófó lẹ́nu. Jesu béèrè lọ́wọ́ baba ọmọ náà pé, “Ó tó ìgbà wo tí ọmọ rẹ̀ ti wà nínú irú ipò báyìí?” Baba ọmọ náà dáhùn pé, “Láti kékeré ni.” Nígbàkúgbà ni ó sì máa ń gbé e sínú iná àti sínú omi, láti pa á run, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣàánú fún wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́. “Jesu sì wí fún un pé, ‘Bí ìwọ bá le gbàgbọ́: ohun gbogbo ni ó ṣe é ṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.’ ” Lójúkan náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.” Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń péjọ sọ́dọ̀ wọn, ó bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí pé, “Ìwọ ẹ̀mí àìmọ́, adití àti odi, mo pàṣẹ fún ọ, kí ó jáde kúrò lára ọmọ yìí, kí ó má ṣe padà sí ibẹ̀ mọ́.” Òun sì kígbe ńlá, ó sì nà án tàntàn, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀: ọmọ náà sì dàbí ẹni tí ó kú tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ké wí pé, “Hé è, ọmọ náà ti kú.” Ṣùgbọ́n Jesu fà á lọ́wọ́, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó dìde dúró.
”Bí ọwọ́ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o ṣe akéwọ́ lọ sí ibi ìyè, ju o ní ọwọ́ méjèèjì kí o lọ sí ọ̀run àpáàdì, sínú iná àjóòkú. Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú tí iná nà án kì í kú. Bí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé é sọnù, ó sàn kí ó di akesẹ̀, kí o sì gbé títí ayé àìnípẹ̀kun ju kí o ní ẹsẹ̀ méjì tí ó gbé ọ lọ sí ọ̀run àpáàdì. Níbi tí kòkòrò wọn kì í kú, tí iná nà án kì í sì í ku. Bí ojú rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn kí o wọ ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ojú kan ju kí ó ní ojú méjì kí ó sì lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì. Níbi ti “ ‘kòkòrò wọn kì í kú, tí iná kì í sì í kú.’
”Wọ́n dé Jeriko, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fẹ́ kúrò ní ìlú Jeriko, ọkùnrin afọ́jú kan, Bartimeu, ọmọ Timeu jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ó ń ṣagbe. Nígbà tí Bartimeu gbọ́ pé Jesu ti Nasareti wà nítòsí, o bẹ̀rẹ̀ sí kígbe lóhùn rara pé, “Jesu ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi.” Àwọn tó wà níbẹ̀ kígbe mọ́ ọn pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́.” Ṣùgbọ́n dípò kí ó pa ẹnu mọ́, ṣe ló ń kígbe lóhùn rara pé, “Jesu ọmọ Dafidi ṣàánú fún mi.” Nígbà tí Jesu gbọ́ igbe rẹ̀, ó dẹ́sẹ̀ dúró lójú ọ̀nà, ó sì wí pé, “Ẹ pè é kí ó wá sọ́dọ̀ mi.” Nítorí náà wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n wí pé, “Tújúká! Dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ! Ó ń pè ọ́.” Lẹ́sẹ̀kan náà, Bartimeu bọ́ agbádá rẹ̀ sọnù, ó fò sókè, ó sì wá sọ́dọ̀ Jesu. Jesu béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ìwọ fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún ọ?” Afọ́jú náà dáhùn pé, “Rabbi, jẹ́ kí èmi kí ó ríran.” Jesu wí fún un pé, “Máa lọ, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọkùnrin afọ́jú náà ríran ó sì ń tẹ̀lé Jesu lọ ní ọ̀nà.
”Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣídìí, gbé ara rẹ sọ sínú Òkun’ ti kò sì ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un. Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ tiyín.
”“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyèsára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú Sinagọgu wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn baálẹ̀ àti níwájú àwọn ọba nítorí orúkọ mi, fún ẹ̀rí fún wọn. Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń fà yín lọ, tí wọ́n bá sì ń fi yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn ṣáájú ohun tí ẹ ó sọ. Ṣùgbọ́n ohun tí bá fi fún yín ní wákàtí náà, òun ni kí ẹ̀yin kí ó wí. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń wí, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́. “Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣe ikú pa òbí wọn. Àwọn ènìyàn yóò kórìíra yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fi ara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà.
”Ṣùgbọ́n Peteru fa ara ya, ó wí pé, “Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́n rí.” Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.
”Ó sì mú Peteru àti Jakọbu àti Johanu lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi. Ó sì wí fún wọn pé, “ọkàn mi ń káàánú gidigidi títí dé ojú ikú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ sì máa bá mi ṣọ́nà.” Ó sì lọ síwájú díẹ̀, ó dojúbo ilẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá. Ó sì wí pé, “Ábbà, Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò ṣe èyí tí ìwọ fẹ́.”
”Pilatu sì ń fẹ́ ṣe èyí tí ó wu àwọn ènìyàn, ó dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Nígbà tí ó sì na Jesu tan o fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn an mọ́ àgbélébùú.
”Wọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn bá à lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù. Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú.
”Ní wákàtí kẹsànán ni Jesu kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “Eli, Eli, Lama Sabakitani?” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”).
”Ààmì wọ̀nyí yóò sì máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ. Ní orúkọ mi ni wọ́n yóò máa lé ẹ̀mí èṣù jáde. Wọn yóò máa fi èdè tuntun sọ̀rọ̀. Wọn yóò sì gbé ejò lọ́wọ́, bí wọ́n bá sì jẹ májèlé kò nípa wọ́n lára rárá. Wọ́n yóò gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóò sì dá.”
”“Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi, Nítorí tí ó fi ààmì òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì. Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti ìmúnríran fún àwọn afọ́jú, àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,
”Ọkùnrin kan sì wà nínú Sinagọgu, ẹni tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó kígbe ní ohùn rara, “Ó wí pé, kín ni ṣe tàwa tìrẹ, Jesu ará Nasareti? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.” Jesu sì bá a wí gidigidi, ó wí fun pe, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì jáde lára rẹ̀.” Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà sì gbé e ṣánlẹ̀ ní àwùjọ, ó jáde kúrò lára rẹ̀, kò sì pa á lára. Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “irú ẹ̀kọ́ kín ni èyí? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.”
”Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú Sinagọgu, ó sì wọ̀ ilé Simoni lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Simoni dùbúlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀. Ó sì súnmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí; ibà sì náà sì fi sílẹ̀. O sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
”Nígbà tí oòrùn sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn gbe àwọn aláìsàn, tó ní onírúurú àìsàn wá sọ́dọ̀ Jesu; ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá.
”Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu wọ ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà, kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò wa síbẹ̀: nígbà tí ó rí Jesu, ó wólẹ̀, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mí di mímọ́.” Jesu sì na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́!” Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.
”Ṣùgbọ́n òkìkí rẹ̀ ń kàn kálẹ̀: tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì jùmọ̀ pàdé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìwòsàn lọ́dọ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìlera wọn.
”Ní ọjọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisi àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Galili gbogbo, àti Judea, àti Jerusalẹmu wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá. Sá à sì kíyèsi i, àwọn Ọkùnrin kan gbé ẹnìkan tí ó ní ààrùn ẹ̀gbà wà lórí àkéte: wọ́n ń wá ọ̀nà àti gbé e wọlé, àti láti tẹ́ ẹ síwájú Jesu. Nígbà tí wọn kò sì rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi gbé e wọlé nítorí ìjọ ènìyàn, wọ́n gbé e gun òkè àjà ilé lọ, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí àárín èrò ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu. Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé, “Ọkùnrin yìí, a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀-òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.” Jesu sì mọ èrò inú wọn, ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín? Èwo ni ó yá jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tàbí láti wí pé, ‘Dìde kí ìwọ sì máa rìn’? Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ọmọ ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni.” Ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, “Mo wí fún ọ, dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé!” Ó sì dìde lọ́gán níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo.
”Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹni tí ara rẹ̀ le kò nílò oníṣègùn, bí kò ṣe ẹni tí ara rẹ̀ kò dá. Èmí kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.”
”Ní ọjọ́ ìsinmi mìíràn, ó wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì ń kọ́ni, ọkùnrin kan sì ń bẹ níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ. Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi ń ṣọ́ ọ, bóyá yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi; kí wọn lè rí ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kàn án. Ṣùgbọ́n ó mọ èrò inú wọn, ó sì wí fún ọkùnrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde, kí o sì dúró láàrín.” Ó sì dìde dúró. Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Èmi bi yín léèrè, Ó ha tọ́ láti máa ṣe rere ni ọjọ́ ìsinmi, tàbí láti máa ṣe búburú? Láti gba ọkàn là, tàbí láti pa á run?” Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká, ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀: ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí èkejì.
”Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀, ó sì dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn, láti gbogbo Judea, àti Jerusalẹmu, àti agbègbè Tire àti Sidoni, tí wọ́n wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìmúláradá kúrò nínú ààrùn wọn; Àti àwọn tí ara wọn kún fún ẹ̀mí àìmọ́; ni ó sì mú láradá. Gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń fẹ́ láti fọwọ́ kàn án, nítorí tí àṣẹ ń jáde lára rẹ̀, ó sì mú gbogbo wọn láradá.
”Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ebi ń pa nísinsin yìí; nítorí tí ẹ ó yóò. Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ń sọkún nísinsin yìí: nítorí tí ẹ̀yin ó rẹ́rìn-ín. Alábùkún fún ni ẹ̀yin, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kórìíra yín, tí wọ́n bá yà yín kúrò nínú ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n bá gàn yín, tí wọ́n bá ta orúkọ yín nù bí ohun búburú, nítorí ọmọ ènìyàn. “Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, kí ẹ sì fò fún ayọ̀, nítorí púpọ̀ ní èrè yín ni ọ̀run. Báyìí ni àwọn baba yín ṣe ṣe sí àwọn wòlíì.
”Ọmọ ọ̀dọ̀ balógun ọ̀rún kan, tí ó ṣọ̀wọ́n fún un, ṣàìsàn, ó sì ń kú lọ. Nígbà tí ó sì gbúròó Jesu, ó rán àwọn àgbàgbà Júù sí i, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá mú ọmọ ọ̀dọ̀ òun láradá. Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n fi ìtara bẹ̀ ẹ́, pé, “Ó yẹ ní ẹni tí òun ìbá ṣe èyí fún: Nítorí tí ó fẹ́ràn orílẹ̀-èdè wa, ó sì ti kọ́ Sinagọgu kan fún wa.” Jesu sì ń bá wọn lọ. Nígbà tí kò sì jìn sí etí ilé mọ́, balógun ọ̀rún náà rán àwọn ọ̀rẹ́ sí i, pé, “Olúwa, má ṣe yọ ara rẹ lẹ́nu: nítorí tí èmi kò yẹ tí ìwọ ìbá fi wọ abẹ́ òrùlé mi: Nítorí náà èmi kò sì rò pé èmi náà yẹ láti tọ̀ ọ́ wá: ṣùgbọ́n sọ ní gbólóhùn kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. Nítorí èmi náà pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí abẹ́ àṣẹ, tí ó ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi, mo sì wí fún ọ̀kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ; àti fún òmíràn pé, ‘Wá,’ a sì wá; àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.” Nígbà tí Jesu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Israẹli.” Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ ọ̀dọ̀ náà tí ń ṣàìsàn, ara rẹ̀ ti dá.
”Bí ó sì ti súnmọ́ ẹnu ibodè ìlú náà, sì kíyèsi i, wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, ọmọ kan ṣoṣo náà tí ìyá rẹ̀ bí, ó sì jẹ́ opó: ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ìlú náà sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí Olúwa sì rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé, “Má sọkún mọ́.” Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́. Ó sì wí pé, “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde!” Ẹni tí ó kú náà sì dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fọhùn. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
”Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti ààrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú. Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yin rí, tí ẹ̀yin sì gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòṣì ni à ń wàásù ìhìnrere.
”Àti àwọn obìnrin kan, tí a ti mú láradá kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú àti nínú àìlera wọn, Maria tí a ń pè ní Magdalene, lára ẹni tí ẹ̀mí èṣù méje ti jáde kúrò.
”Bí wọ́n sì ti ń lọ, ó sùn; ìjì ńlá sì dé, ó ń fẹ́ lójú adágún; omi si wọ inú ọkọ, wọ́n sì wà nínú ewu. Wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá wọ́n sì jí i, wí pé, “Olùkọ́, Olùkọ́, àwa yóò ṣègbé!” Nígbà náà ni ó dìde, ó sì bá ìjì líle àti ríru omi wí; wọ́n sì dúró, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì dé. Ó sì wí fún wọn pé, “Ìgbàgbọ́ yín dà?” Bí ẹ̀rù ti ń ba gbogbo wọn, tí hà sì ń ṣe wọ́n, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni èyí, nítorí ó bá ìjì líle àti ríru omi wí, wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀?”
”Wọ́n sì gúnlẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Gadara, tí ó kọjú sí Galili. Nígbà tí ó sì sọ̀kalẹ̀, ọkùnrin kan pàdé rẹ̀ lẹ́yìn ìlú náà, tí ó ti ní àwọn ẹ̀mí èṣù fún ìgbà pípẹ́, tí kì í wọ aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í jókòó ní ilé kan, bí kò ṣe ní ibojì. Nígbà tí ó rí Jesu, ó ké, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí lóhùn rara, pé, “Kí ni mo ní í ṣe pẹ̀lú rẹ, Jesu, ìwọ ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Èmi bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” (Nítorí tí ó ti wí fún ẹ̀mí àìmọ́ náà pé, kí ó jáde kúrò lára ọkùnrin náà. Nígbàkúgbà ni ó ń mú un: wọn a sì fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é; a sì ja gbogbo ìdè náà, ẹ̀mí èṣù náà a sì darí rẹ̀ sí ijù). Jesu sì bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó sì dáhùn pé, “Légíónì,” nítorí ẹ̀mí èṣù púpọ̀ ni ó wa nínú rẹ. Wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe rán wọn lọ sínú ọ̀gbun. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ púpọ̀ sì ń bẹ níbẹ̀ tí ń jẹ lórí òkè: wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí àwọn wọ inú wọn lọ. Ó sì gba fún wọn. Nígbà tí àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ sì tú ka, wọ́n sí súré rọ́ gììrì sọ̀kalẹ̀ sì bèbè odò bọ́ sínú adágún náà, wọ́n sì rì sínú rẹ̀.
”Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá, Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ.
”Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lẹ́nu, ẹnìkan ti ilé olórí Sinagọgu wá, ó wí fún un pé, “Ọmọbìnrin rẹ kú; má yọ olùkọ́ni lẹ́nu mọ́.” Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́, ó dá a lóhùn, pé, “Má bẹ̀rù: sá gbàgbọ́ nìkan, a ó sì mú un láradá.” Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu sì wọ ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé, bí kò ṣe Peteru, àti Jakọbu, àti Johanu, àti baba àti ìyá ọmọbìnrin náà. Gbogbo wọn sì sọkún, wọ́n pohùnréré ẹkún rẹ̀: ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má sọkún mọ́; kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi í ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sá mọ̀ pé ó kú. Nígbà tí ó sì sé gbogbo wọn mọ́ òde, ó mú un lọ́wọ́, ó sì wí pé, “Ọmọbìnrin, dìde!” Ẹ̀mí rẹ̀ sì padà bọ̀, ó sì dìde lọ́gán: ó ní kí wọn fún un ní oúnjẹ.
”Ó sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù gbogbo, àti láti wo ààrùn sàn. Ó sì rán wọn lọ wàásù ìjọba Ọlọ́run, àti láti mú àwọn ọlọkùnrùn láradá.
”Wọ́n sì lọ, wọ́n ń la ìletò kọjá wọ́n sì ń wàásù ìhìnrere, wọ́n sì ń mú ènìyàn láradá níbi gbogbo.
”Nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì mọ̀, wọ́n tẹ̀lé e: ó sì gbà wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún wọn; àwọn tí ó fẹ́ ìmúláradá, ni ó sì mú láradá.
”Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan nínú ìjọ ènìyàn kígbe sókè, pé “Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi: nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni. Sì kíyèsi i, ẹ̀mí èṣù a máa mú un, a sì máa kígbe lójijì; a sì máa nà án tàntàn títí yóò fi yọ ìfófó lẹ́nu, a máa pa á lára, kì í tilẹ̀ ń fẹ́ fi í sílẹ̀ lọ. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde: wọn kò sì lè ṣe é.” Jesu sì dáhùn pé, “Ìran aláìgbàgbọ́ àti àrékérekè, èmi ó ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti ṣe sùúrù fún yín pẹ́ tó? Fa ọmọ rẹ wá níhìn-ín yìí.” Bí ó sì ti ń bọ̀, ẹ̀mí èṣù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì nà án tàntàn. Jesu sì bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sì mú ọmọ náà láradá, ó sì fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́.
”Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín!’
”Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára.
”Jesu sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jeriko, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n sá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán. Ní kòńgẹ́ àkókò yìí ni àlùfáà kan sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ lọ́nà náà. Nígbà tí ó sì rí i ó kọjá lọ níhà kejì. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọmọ Lefi kan pẹ̀lú, nígbà tí ó dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó kọjá lọ níhà kejì. Ṣùgbọ́n ará Samaria kan, bí ó ti ń re àjò, ó dé ibi tí ó gbé wà; nígbà tí ó sì rí i, àánú ṣe é. Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì di ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí i, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti òun tìkára rẹ̀, ó sì mú un wá sí ilé èrò, a sì ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
”Ó sì ń lé ẹ̀mí èṣù kan jáde, tí ó sì yadi. Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà jáde, odi sọ̀rọ̀; ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn.
”Ológoṣẹ́ márùn-ún sá à ni a ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run? Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán. Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù: ẹ̀yin ní iye lórí ju ológoṣẹ́ púpọ̀ lọ.
”Jesu sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Nítorí náà mo wí fún yín pé, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nítorí ẹ̀mí yín pé, kín ni ẹ̀yin yóò jẹ tàbí nípa ara yin pe kín ni ẹyin o fi bora. Ẹ̀mí sá à ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ. Ẹ kíyèsi àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sá à ń bọ́ wọn: mélòó mélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ! Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀? Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù? “Ẹ kíyèsi àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Solomoni pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónìí, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòó mélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣe àníyàn nínú ọkàn. Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń wá kiri: Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ́ nǹkan wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín. “Má bẹ̀rù, agbo kékeré; nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fi ìjọba fún yín.
”Ẹ ta ohun tí ẹ̀yin ní, kí ẹ sì tọrẹ àánú kí ẹ sì pèsè àpò fún ara yín, tí kì í gbó, ìṣúra ní ọ̀run tí kì í tán, ní ibi tí olè kò lè súnmọ́, àti ibi tí kòkòrò kì í bà á jẹ́. Nítorí ní ibi tí ìṣúra yín gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yóò gbé wà pẹ̀lú.
”Sì kíyèsi i, obìnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ní ẹ̀mí àìlera, láti ọdún méjì-dínlógún wá, ẹni tí ó tẹ̀ tán, tí kò le gbé ara rẹ̀ sókè bí ó ti wù kí ó ṣe. Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é sí ọ̀dọ̀, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, a tú ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ àìlera rẹ.” Ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé e: Lójúkan náà a sì ti sọ ọ́ di títọ́, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo.
”Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í ṣe ọmọbìnrin Abrahamu sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí Satani ti dè, sá à wò ó láti ọdún méjì-dínlógún yìí wá?”
”Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsi i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lónìí àti lọ́la, àti ní ọjọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’
”Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ó ní ara wíwú níwájú rẹ̀. Jesu sì dáhùn ó wí fún àwọn amòfin àti àwọn Farisi pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, tàbí kò tọ́?” Wọ́n sì dákẹ́. Ó sì mú un, ó mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ.
”Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkún ara, àwọn amúnkùn ún, àti àwọn afọ́jú:
”“Ǹjẹ́ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ń wọ aṣọ elése àlùkò àti aṣọ àlà dáradára, a sì máa jẹ dídùndídùn lójoojúmọ́: Alágbe kan sì wà tí à ń pè ní Lasaru, tí wọ́n máa ń gbé wá kalẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà ilé rẹ̀, ó kún fún ooju, Òun a sì máa fẹ́ kí a fi èérún tí ó ti orí tábìlì ọlọ́rọ̀ bọ́ sílẹ̀ bọ́ òun: àwọn ajá sì wá, wọ́n sì fá a ní ooju lá. “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn angẹli gbé e lọ sí oókan àyà Abrahamu: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín; Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀. Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’ “Ṣùgbọ́n Abrahamu wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lasaru ohun búburú: ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró. Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má ba á le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’ “Ó sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ mo bẹ̀ ọ́, baba, kí ìwọ kí ó rán Lasaru lọ sí ilé baba mi: Nítorí mo ní arákùnrin márùn-ún; kí ó lè rò fún wọn kí àwọn kí ó má ba á wá sí ibi oró yìí pẹ̀lú.’ “Abrahamu sì wí fún un pé, ‘Wọ́n ní Mose àti àwọn wòlíì; kí wọn kí ó gbọ́ tiwọn.’ “Ó sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, Abrahamu baba; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ti inú òkú tọ̀ wọ́n lọ, wọn ó ronúpìwàdà.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mose àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde.’ ”
”Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè: Wọ́n sì kígbe sókè, wí pé, “Jesu, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.” Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́. Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú Òun láradá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo.
”Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá àti gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóò sọ ọ́ nù; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ nù yóò gbà á là.
”Bí ó ti súnmọ́ Jeriko, afọ́jú kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà ó ń ṣagbe: Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó béèrè pé, kín ni ìtumọ̀ èyí. Wọ́n sì wí fún un pé, “Jesu ti Nasareti ni ó ń kọjá lọ.” Ó sì kígbe pé, “Jesu, ìwọ ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!” Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!” Jesu sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í, Wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?” Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.” Jesu sì wí fún un pé, “Ríran; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.” Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.
”Nítorí Ọmọ Ènìyàn dé láti wá àwọn tí ó nù kiri, àti láti gbà wọ́n là.”
”Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn angẹli dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde.
”“Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí Sinagọgu, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi. Ẹ o si jẹ́rìí nípa mi. Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ ní ọkàn yín pé ẹ ko ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn. Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú. A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀rẹ́; on ó sì mú kì a pa nínú yín. A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi. Ṣùgbọ́n irun orí yín kan kì yóò ṣègbé.
”Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi.
”Olúwa sì wí pé, “Simoni, Simoni, wò ó, Satani fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí alikama: Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀ sípò, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú.”
”Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀.
”Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì. Jesu sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn.
”Jesu sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Paradise!”
”Nígbà tí Jesu sì kígbe lóhùn rara, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!” Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.
”“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.
”Bẹ́ẹ̀ ni Jesu tún wá sí Kana ti Galili, níbi tí ó gbé sọ omi di wáìnì. Ọkùnrin ọlọ́lá kan sì wá, ẹni tí ara ọmọ rẹ̀ kò dá ní Kapernaumu. Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti Judea wá sí Galili, ó tọ̀ ọ́ wá, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, kí ó lè sọ̀kalẹ̀ wá kí ó mú ọmọ òun láradá: nítorí tí ó wà ní ojú ikú. Nígbà náà ni Jesu wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá rí ààmì àti iṣẹ́ ìyanu, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́ láé.” Ọkùnrin ọlọ́lá náà wí fún un pé, “Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá kí ọmọ mi tó kú.” Jesu wí fún un pé, “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ; ọmọ rẹ yóò yè.” Ọkùnrin náà sì gba ọ̀rọ̀ Jesu gbọ́, ó sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Bí ó sì ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pàdé rẹ̀, wọ́n sì wí fún un pé, ọmọ rẹ ti yè. Nígbà náà ni ó béèrè wákàtí tí ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yá lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì wí fún un pé, “Ní àná, ní wákàtí keje ni ibà náà fi í sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni baba náà mọ̀ pé ní wákàtí kan náà ni, nínú èyí tí Jesu wí fún un pé “Ọmọ rẹ̀ yè.” Òun tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́, àti gbogbo ilé rẹ̀.
”Ní ẹ̀gbẹ́ odò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn abirùn ènìyàn máa ń gbé dùbúlẹ̀ sí, àwọn afọ́jú, arọ àti aláàrùn ẹ̀gbà, wọ́n sì ń dúró de rírú omi. Nítorí angẹli a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sínú adágún náà, a sì máa rú omi rẹ̀: lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti rú omi náà tan ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ wọ inú rẹ̀ a di alára dídá kúrò nínú ààrùnkárùn tí ó ní. Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjì-dínlógójì. Bí Jesu ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?” Abirùn náà dá a lóhùn wí pé, “Arákùnrin, èmi kò ní ẹni tí ìbá gbé mi sínú adágún, nígbà tí a bá ń rú omi náà: bí èmi bá ti ń bọ̀ wá, ẹlòmíràn a sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀ síwájú mi.” Jesu wí fún un pé, “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.” Lọ́gán, a sì mú ọkùnrin náà láradá, ó sì gbé àkéte rẹ̀, ó sì ń rìn. Ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ ìsinmi.
”Lẹ́yìn náà, Jesu rí i nínú tẹmpili ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!”
”Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.
”Jesu wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè: ẹnikẹ́ni tí ó bá tọ̀ mí wá, ebi kì yóò pa á; ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Ẹ̀yin ti rí mi, ẹ kò sì gbàgbọ́. Gbogbo èyí tí Baba fi fún mi, yóò tọ̀ mí wá; ẹni tí ó bá sì tọ̀ mí wá, èmi kì yóò tà á nù, bí ó tí wù kó rí.
”Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”
”Bí ó sì ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí rẹ̀ wá. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Rabbi, ta ní ó dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yìí tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?” Jesu dáhùn pé, “Kì í ṣe nítorí pé ọkùnrin yìí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí a ba à lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lára rẹ̀. Èmi ní láti ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ ọ̀sán: òru ń bọ̀ wá nígbà tí ẹnìkan kì yóò lè ṣe iṣẹ́. Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” Nígbà tí ó ti wí bẹ́ẹ̀ tan, ó tutọ́ sílẹ̀, ó sì fi itọ́ náà ṣe amọ̀, ó sì fi amọ̀ náà ra ojú afọ́jú náà. Ó sì wí fún un pé, “Lọ wẹ̀ nínú adágún Siloamu!” (Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni “rán”). Nítorí náà ó gba ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó wẹ̀, ó sì dé, ó ń ríran.
”Láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, a kò ì tí ì gbọ́ pé ẹnìkan la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú rí.
”Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun: èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀. “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.
”Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì ṣí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi.
”Jesu wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè: Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”
”Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.” Nígbà tí Jesu rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́. Ó sì wí pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Olúwa, wá wò ó.” Jesu sọkún. Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”
”Jesu wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!” Marta, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí: nítorí pé ó di ọjọ́ kẹrin tí ó tí kú.” Jesu wí fún un pé, “Èmi kò ti wí fún ọ pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?” Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jesu sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi. Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo: ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn ba à lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.” Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lasaru, jáde wá.” Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ!”
”“Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú: ẹ gba Ọlọ́run gbọ́, kí ẹ sì gbà mí gbọ́ pẹ̀lú. Nínú ilé Baba mi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùgbé ni ó wà: ìbá má ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ìbá tí sọ fún yín. Èmi ń lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún yín.
”Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, òun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ. Bí ẹ̀yin bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi ó ṣe é.
”Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, àlàáfíà mi ni mo fi fún yin, kì í ṣe bí ayé ti fi fún ni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì.
”Bí ẹ̀yin bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi bá sì gbé inú yín, ẹ ó béèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, a ó sì ṣe é fún yín. Nínú èyí ní a yìn Baba mi lógo pé, kí ẹ̀yin kí ó máa so èso púpọ̀; ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.
”Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí ayọ̀ mi kí ó lè wà nínú yín, àti kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.
”Nítorí náà ẹ̀yin ní ìbànújẹ́ nísinsin yìí: ṣùgbọ́n èmi ó tún rí yín, ọkàn yín yóò sì yọ̀, kò sì sí ẹni tí yóò gba ayọ̀ yín lọ́wọ́ yín. Àti ní ọjọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín. Títí di ìsinsin yìí ẹ kò tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi: ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.
”“Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”
”Nítorí náà ni Pilatu mú Jesu, ó sì nà án.
”Nítorí náà ni Pilatu fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́ àgbélébùú. Àwọn ológun gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu. Nítorí náà, wọ́n mú Jesu, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnrarẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Heberu tí à ń pè ní Gọlgọta: Níbi tí wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn méjì mìíràn pẹ̀lú rẹ̀, níhà ìhín àti níhà kejì, Jesu sì wà láàrín.
”Nígbà tí Jesu sì ti gba ọtí kíkan náà, ó wí pé, “Ó parí!” Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.
”Ìwé mímọ́ mìíràn pẹ̀lú sì wí pé, “Wọn ó máa wo ẹni tí a gún lọ́kọ̀.”
”Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.’
”Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀: pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí. Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà òkú, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́. Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè, ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’
”Peteru wí pé, “Wúrà àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fi fún ọ: Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, dìde kí o sì máa rìn.” Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkan náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun. Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹmpili lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run. Gbogbo ènìyàn sì rí i, ó ń rìn, ó sì yin Ọlọ́run:
”Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí ibùsùn àti àkéte kí òjìji Peteru ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerusalẹmu ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá.
”Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sadusi wọ̀. Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn aposteli wọn sì fi wọ́n sínú túbú. Ṣùgbọ́n ní òru, angẹli Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde. Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹmpili kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fún àwọn ènìyàn.”
”Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀; wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀.
”Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú. Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo ń wàásù ọ̀rọ̀ náà.
”Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ́, tí wọn sì rí iṣẹ́ ààmì tí Filipi ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkàn kan fiyèsí ohun tí ó ń sọ. Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá. Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.
”Àní Jesu ti Nasareti, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti da Ẹ̀mí Mímọ́ àti agbára le lórí; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
”Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ. Herodu ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrékọjá fún ìdájọ́. Nítorí náà wọn fi Peteru pamọ́ sínú túbú; ṣùgbọ́n ìjọ ń fi ìtara gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un. Ní òru náà gan an ti Herodu ìbá sì mú un jáde, Peteru ń sùn láàrín àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀ṣọ́ sí wà ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà. Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru. Angẹli náà sì wí fún un pé, “Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ!” Peteru sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn!” Peteru sì jáde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ angẹli náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe bí òun wà lójú ìran. Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ èkínní àti èkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tìkára rẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
”wọn sì ń mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú láti dúró nínú ìgbàgbọ́, àti pé nínú ìpọ́njú púpọ̀, ni àwa ó fi wọ ìjọba Ọlọ́run.
”Ọ̀pọ̀ ènìyàn sí jùmọ̀ dìde sì Paulu àti Sila. Àwọn olórí sí fà wọ́n ní aṣọ ya, wọ́n sí pàṣẹ pé, ki a fi ọ̀gọ̀ lù wọ́n. Nígbà tí wọ́n sì lù wọ́n púpọ̀, wọ́n sọ wọ́n sínú túbú, wọ́n kìlọ̀ fún onítúbú kí ó pa wọ́n mọ́ dáradára:
”Nígbà tí ó gbọ́ irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ̀ wọ́n sínú túbú tí inú lọ́hùn, ó sí kan àbà mọ wọ́n lẹ́sẹ̀. Ṣùgbọ́n láàrín ọ̀gànjọ́ Paulu àti Sila ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run: àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn. Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tó bẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ìlẹ̀kùn sì ṣí, ìdè gbogbo wọn sì tú sílẹ̀. Nígbà tí onítúbú si tají, tí o sì ri pé, àwọn ìlẹ̀kùn túbú tí ṣí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣe bí àwọn ara túbú ti sálọ. Ṣùgbọ́n Paulu gbé ohun rẹ̀ sókè, wí pé, “Má ṣe pa ara rẹ lára: nítorí gbogbo wa ń bẹ níhìn-ín yìí!” Nígbà tí ó sì béèrè iná, ó bẹ́ wọ inú ilé, ó ń wárìrì, ó wólẹ̀ níwájú Paulu àti Sila. Ó sì mú wọn jáde, ó ní, “Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là?”
”Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Paulu ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyanu, tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti aṣọ ìnuwọ́ rẹ̀ tọ àwọn ọlọkùnrùn lọ, ààrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn.
”Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù:
”“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, ẹ̀mí mi ń fà sì Jerusalẹmu, láìmọ̀ ohun tí yóò bá mi níbẹ̀: Bí kò ṣe bí Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń sọ ní ìlú gbogbo pé, ìdè àti ìyà ń bẹ fún mi. Ṣùgbọ́n èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jesu Olúwa, láti máa ròyìn ìhìnrere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
”Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, bí òun tìkára rẹ̀ tí wí pé, ‘láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ”
”Nígbà náà ni Paulu dáhùn wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í ṣe fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerusalẹmu, nítorí orúkọ Jesu Olúwa.” Nígbà tí a kò lè pa á ní ọkàn dà, a dákẹ́ wí pé, “Ìfẹ́ tí Olúwa ni kí ó ṣe!”
”Ó sì ṣe, baba Pọbiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá. Nígbà tí èyí sì ṣetán, àwọn ìyókù tí ó ni ààrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá.
”Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú: bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí: Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.
”Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa. Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀. Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀. Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.
”Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́ṣẹ̀:
”Tàbí ẹyin kò mọ pé gbogbo wa ti a ti bamitiisi wa sínú Jesu Kristi ni a ti bamitiisi sínú ikú rẹ. Nítorí náà, a sin wa pẹ̀lú Kristi nípa ìtẹ̀bọmi si ikú, kí ó bá le jẹ́ pe bí a ti jí Kristi dìde pẹ̀lú ògo Baba, àwa pẹ̀lú gbé ìgbé ayé tuntun. Nítorí pé ẹ̀yin ti di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde. Gbogbo èrò búburú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́.
”Nísinsin yìí, bí àwa bá kú pẹ̀lú Kristi àwa gbàgbọ́ pé àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí àwa mọ̀ pé Kristi ti jí dìde kúrò nínú òkú. Òun kò sì ní kú mọ́. Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́. Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, láti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láààyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ ka ara yín bí òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n bí alààyè sí Ọlọ́run nínú Kristi Jesu. Nítorí náà kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ọba lórí ara kíkú yín kí ó lè ba à máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ara yín kan di ohun èlò ohun búburú, nípa ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Ṣùgbọ́n ẹ fi wọn fún Ọlọ́run pátápátá. Wọ́n ti di ààyè, ẹ jẹ́ kí wọn di ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí ó lè lò wọ́n fún àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó dára.
”Àti pé, kín ni ìyọrísí rẹ̀? Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára. Níwọ́n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsin yìí láti ronú nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń ṣe nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé. Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun.
”Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àìnípẹ̀kun nínú Kristi Jesu Olúwa wa.
”Èmi ẹni òsì! Ta ni yóò ha gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ara kíkú yìí?
”Nítorí náà, kò sí ìdálẹ́bi nísinsin yìí fún àwọn tí ó wà nínú Kristi Jesu, àwọn tí kò rìn nípa ti ara, bí kò ṣe nípa ti Ẹ̀mí. Nítorí nípasẹ̀ òfin ti ẹ̀mí ìyè nínú Kristi Jesu ti sọ mí di òmìnira kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Nítorí ohun tí òfin kò lè ṣe, bí ó ti jẹ aláìlera nítorí ara, Ọlọ́run rán ọmọ òun tìkára rẹ̀ ní àwòrán ara ẹ̀ṣẹ̀, ó sì di ẹ̀ṣẹ̀; àti bi ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ara, kí a lè mú òdodo òfin ṣẹ, nínú wa, nítorí tí àwa yé gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí. Àwọn tí ń gbe nípa ti ara, wọn a máa ronú ohun ti ara; ṣùgbọ́n àwọn ti ń gbe nípa ti Ẹ̀mí, wọn a máa ronú ohun ti Ẹ̀mí. Nítorí èrò ti ara ikú ni; ṣùgbọ́n èrò ti ẹ̀mí ni ìyè àti àlàáfíà. Nítorí èrò ti ara ọ̀tá ni sí Ọlọ́run, nítorí kì í tẹríba fún òfin Ọlọ́run, òun kò tilẹ̀ le ṣe e. Ìdí nìyìí tí àwọn tí ó wà lábẹ́ àkóso ara ẹ̀ṣẹ̀, kò le è tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn.
”Ṣùgbọ́n ẹyin kò sí nínú ti ara, bí kò ṣe nínú ti Ẹ̀mí, bí ó bá ṣe pé Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín, Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá ní Ẹ̀mí Kristi, òun kò sí nínú ẹni tirẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristi ń gbé inú yín síbẹ̀síbẹ̀, ara yín jẹ́ òkú nítorí ẹ̀ṣẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú yín yóò fún yín ní ìyè, nítorí ó ti fún un yín ní òdodo. Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jesu kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, ẹni tí ó jí Kristi Jesu dìde kúrò nínú òkú, yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ tí ń gbé inú yín sọ ara kíkú yín di ààyè pẹ̀lú.
”Nítorí náà ará a ni ojúṣe láti ṣe, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa nǹkan tí ara, tí a ó fi máa gbé nípa ti ara. Nítorí pé bí ẹ̀yin bá ń tẹ̀lé, ẹ̀ṣẹ̀ ti ara ẹ̀yin yóò sọnù, ẹ ó sì ṣègbé, ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ń gbé nípa ti ara, ẹ̀yin yóò kú, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yín bá ń gbé nípa ti Ẹ̀mí, ẹ ó pa iṣẹ́ ti ara run, ẹ̀yin yóò yè. Nítorí pé, iye àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run. Nítorí ẹ̀yin kò tún gba ẹ̀mí ẹrú láti máa bẹ̀rù mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, nípa èyí tí àwa fi ń ké pé “Ábbà, Baba.” Nítorí ẹ̀mí mímọ́ ń sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn wa, ó sì ń sọ fún wa pé, nítòótọ́, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Níwọ́n ìgbà tí a jẹ́ ọmọ rẹ̀, ǹjẹ́ ajogún ni àwa, ajogún Ọlọ́run, àti àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, bí ó bá ṣe àwa jìyà, kí a sì le ṣe wá lógo pẹ̀lú rẹ̀.
”Síbẹ̀síbẹ̀, ìyà tí a ń jẹ nísinsin yìí kò jámọ́ nǹkan nígbà tí a bá fiwé ògo tí yóò fún wa ní ìkẹyìn. Nítorí ẹ̀dá ń dúró ní ìfojúsọ́nà de ìfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nítorí a tẹrí ẹ̀dá ba fún asán, kì í ṣe bí òun ti fẹ́, ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ẹni tí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní ìrètí. Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkára rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdíbàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ẹ̀dá ni ó jùmọ̀ ń kérora tí ó sì ń rọbí pọ̀ títí di ìsinsin yìí. Kì í ṣe àwọn nìkan, ṣùgbọ́n àwa tìkára wa pẹ̀lú, a ni àkóso ẹ̀mí, àní àwa tìkára wa ń kérora nínú ara wa, àwa ń dúró de ìsọdọmọ àní ìdáǹdè ara wa. Nítorí nípa ìrètí ni a fi gbà wá là: ṣùgbọ́n ìrètí tí a bá rí kì í ṣe ìrètí nítorí ta ni ń retí ohun tí ó bá rí? Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é.
”Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́: nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ: ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa. Ẹni tí ó sì ń wá inú ọkàn wò, ó mọ ohun ti ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.
”Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀. Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn arákùnrin púpọ̀ Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di “aláìjẹ̀bi” lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kristi kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa.
”Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa? Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le ṣòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí? Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dáríjì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀. Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Kò sí. Kristi Jesu tí ó kú, kí a sá à kúkú wí pé tí a ti jí dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí ó sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, tó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa?
”Ta ni yóò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ìyàn, tàbí ìhòhò, tàbí ewu tàbí idà? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́; À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”
”Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ju ẹni tí ó ṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Kristi ẹni tí ó fẹ́ wa. Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.
”Òtítọ́ ni èmi ń sọ nínú Kristi, èmi kò ṣèké, ọkàn mi sì ń jẹ́ mi ní ẹ̀rí nínú Ẹ̀mí Mímọ́. Pé mo ní ìbìnújẹ́ púpọ̀, àti ìkáàánú ìgbà gbogbo ni ọkàn mi. Nítorí mo fẹ́rẹ lè gbàdúrà pé kí èmi tìkára mi kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn ará mi, àwọn ìbátan mi nípa ti ara.
”Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ ní Sioni àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú, ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”
”Nítorí ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.” Nítorí kò si ìyàtọ̀ nínú Júù àti Helleni: nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, o si pọ̀ ni ọrọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń ké pe e. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”
”Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́ ìsìn yín tí ó tọ̀nà.
”Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gbọingbọin nínú àdúrà. Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò ṣíṣe. Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè. Àwọn tí ń yọ̀, ẹ máa bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkún, ẹ máa bá wọn sọkún.
”Bí a bá wà láààyè, a wà láààyè fún Olúwa; bí a bá sì kú, a kú fún Olúwa. Nítorí náà, bí a wà láààyè, tàbí bí a kú, ti Olúwa ni àwa i ṣe. Nítorí ìdí èyí náà ni Kristi ṣe kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààyè.
”Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.
”Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi ba à lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí.
”Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, láti ọwọ́ Olúwa ni a ti nà wá, kí a má ba à dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé.
”Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn. Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀.
”Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ìjọ ènìyàn mímọ́.
”Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Adamu, bẹ́ẹ̀ ní a ó sì sọ gbogbo ènìyàn dí alààyè nínú Kristi.
”Ikú ní ọ̀tá ìkẹyìn tí a ó parun
”Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé ara àìkú wọ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí ará ìdíbàjẹ́ yìí bá ti gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, ti ara kíkú yìí bá sí ti gbé àìkú wọ̀ bẹ́ẹ̀ tan, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ ti a kọ yóò ṣẹ pé, “A gbé ikú mí ní ìṣẹ́gun.” “Ikú, oró rẹ dà? Ikú, ìṣẹ́gun rẹ́ dà?”
”Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo; Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa pẹ̀lú lè máa tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Nítorí pé bí àwa ti pín nínú ìjìyà Kristi, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ̀ pẹ̀lú nípa Kristi. Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbí bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù láti mú yin ní irú ìfaradà ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́. Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹ̀yin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú.
”Arákùnrin àti arábìnrin, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Asia, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́. Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde: Ẹni tí ó gbà wá kúrò nínú irú ikú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀, yóò sí tún gbà wá; òun ní àwa gbẹ́kẹ̀lé pé yóò sí máa gbà wá síbẹ̀síbẹ̀,
”Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá. A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù. A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run. Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jesu Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jesu hàn pẹ̀lú lára wa. Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fi àwa tí ó wà láààyè fún ikú nítorí Jesu, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú. Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.
”Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́. Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa. Níwọ́n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.
”Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run. Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá.
”Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa. Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rí rí. Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa.
”Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú. Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde. Nítorí náà láti ìsinsin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ara, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́.
”Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé.
”Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fi ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà, nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsàn, nínú ìgbààwẹ̀. Nínú ìwà mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mí Mímọ́, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn.
”bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a ṣì wà láààyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá, bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí tálákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.
”Èmi kò sọ èyí láti dá a yín lẹ́bi; nítorí mo tí wí ṣáájú pé, ẹ̀yin wà nínú ọkàn wa kí a lè jùmọ̀ kú, àti kí a lè jùmọ̀ wà láààyè. Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa.
”Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedonia, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú. Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé;
”Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run a máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá: ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú. Kíyèsi i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúraṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ńkọ́, ìbànújẹ́ ńkọ́, ìpayà ńkọ́, ìfojúṣọ́nà ńkọ́, ìtara ńkọ́, ìjẹ́ni-níyà ńkọ́. Nínú ohun ààmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà.
”Bí ó ti jẹ́ pé a dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti àìlódiwọ̀n àìní wọn ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn.
”Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore-ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé: “Ó tí fọ́nká; ó ti fi fún àwọn tálákà; Òdodo rẹ̀ dúró láéláé.” Ǹjẹ́ ẹni tí ń fi irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa.
”Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkúgbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú. Ní ìrìnàjò nígbàkúgbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní aginjù, nínú ewu lójú Òkun, nínú ewu láàrín àwọn èké arákùnrin. Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́ òru nígbàkúgbà, nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú àwẹ̀ nígbàkúgbà, nínú òtútù àti ìhòhò. Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọn n dúró tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ. Ta ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera? Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná? Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi.
”Nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni èmi ó máa ṣògo: ṣùgbọ́n nípa ti èmi tìkára mi èmi kì yóò ṣògo, bí kò ṣe nínú àìlera mi.
”àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣípayá, kí èmi má ba à gbé ara mi ga rékọjá, a sì ti fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ìránṣẹ́ Satani láti pọ́n mi lójú, kí èmi má bá a gbéraga rékọjá. Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi. Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi. Nítorí náà èmi ní inú dídùn nínú àìlera gbogbo, nínú ẹ̀gàn gbogbo, nínú àìní gbogbo, nínú inúnibíni gbogbo, nínú wàhálà gbogbo nítorí Kristi. Nítorí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.
”Kò le sí Júù tàbí Giriki, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí obìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kristi Jesu. Bí ẹ̀yin bá sì jẹ́ ti Kristi, ǹjẹ́ ẹ̀yin ní irú-ọmọ Abrahamu, àti àrólé gẹ́gẹ́ bí ìlérí.
”Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́,
”Ẹ máa ru ẹrù ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì fi bẹ́ẹ̀ mú òfin Kristi ṣẹ.
”Ọlọ́run sì ti jí wa dìde pẹ̀lú Kristi, ó sì ti mú wa jókòó pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run nínú Kristi Jesu.
”Nítorí èyí náà ni èmi Paulu ṣe di òǹdè Jesu Kristi nítorí ẹ̀yin aláìkọlà.
”Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí. Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín.
”Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró.
”Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ni kí ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo nínú Ẹ̀mí, kí ẹ sì máa ṣọ́ra sí i nínú ìdúró ṣinṣin gbogbo àti ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ènìyàn mímọ́. Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún mí pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè fún mí ní ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí èmi lè máa fì ìgboyà sọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìhìnrere náà. Nítorí èyí tí èmí jẹ́ ikọ̀ nínú ẹ̀wọ̀n: kí èmi lè máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mí láti máa sọ.
”Nítorí, ní ti èmi, láti wa láààyè jẹ́ Kristi, láti kú pẹ̀lú sì jẹ́ èrè fún mi. Ṣùgbọ́n bí èmi bá le è ṣe iṣẹ́ ti ó ni àpẹẹrẹ nípa wíwà láààyè nínú ara, ṣùgbọ́n ohun ti èmi ó yàn, èmi kò mọ̀. Ṣùgbọ́n èmi n ṣiyèméjì, nítorí ti èmi fẹ́ láti lọ kúrò nínú ayé yìí, láti wà lọ́dọ̀ Kristi; nítorí ó dára púpọ̀ jù:
”Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú:
”Nítòótọ́ ni ó ti ṣe àìsàn títí dé ojú ikú, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ṣàánú fún un; kì í sì í ṣe fún òun nìkan, ṣùgbọ́n fún èmi pẹ̀lú kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lórí ìbànújẹ́.
”Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kristi Jesu, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran-ara.
”Èmi mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá fi ara mọ́ ọn nínú ikú rẹ̀;
”Nítorí ìlú ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ ní ọ̀run: láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jesu Kristi Olúwa. Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.
”Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀. Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí. Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.
”Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọpọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábápín nínú ìpọ́njú mi.
”Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kristi Jesu.
”pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀. Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀. Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn.
”Nísinsin yìí èmi ń yọ̀ nínú ìjìyà fún un yín. Inú mi sì dùn, nítorí mo ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti jẹ ìyà tó ṣẹ́kù nínú ìyà Kristi fún ara rẹ̀, èyí tí ì ṣe ìjọ.
”Níwọ́n ìgbà tí a ti jí yín dìde pẹ̀lú Kristi ẹ máa ṣàfẹ́rí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbi tí Kristi gbé wà tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lókè kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé. Nítorí ẹ̀yin ti kú, a sì fi ìyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kristi nínú Ọlọ́run. Nígbà tí Kristi, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.
”Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́.
”Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Filipi bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìhìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle.
”Láìsí àní àní, ẹ mọ̀ gbangba pé, irú ìṣòro báwọ̀nyí wà nínú ètò Ọlọ́run fún àwọn tí ó gbàgbọ́, kí a má ba dààmú. Tó bẹ́ẹ̀ tí a fi kìlọ̀ fún yín pé ìjìyà inúnibíni yóò dé. Ó sì rí bẹ́ẹ̀ nítòótọ́. Bí mo wí tẹ́lẹ̀, nígbà tí ara mi kò gba á mọ́, mo sì ránṣẹ́ kí èmi kí ó lè mọ́ ìgbàgbọ́ yín, kí olùdánwò nì má ba à dán an yín wò lọ́nàkọnà, kí làálàá wa sì jásí asán.
”Ẹ̀yin ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó jẹ́ òpè ní ti àwọn tí ó ti sùn, pé kí ẹ máa banújẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù tí kò ní ìrètí. A gbàgbọ́ pé, Jesu kú, ó sì tún jíǹde, àti pé Ọlọ́run yóò mú gbogbo àwọn tí ó ti sùn nínú rẹ̀ padà wá. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, pé àwa tí ó wà láààyè, tí a sì kù lẹ́yìn de à ti wá Olúwa, bí ó ti wù kí ó rí, kì yóò ṣáájú àwọn tí ó sùn láti pàdé rẹ̀.
”Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nínú ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kristi Jesu nítòótọ́.
”Kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀, Ọlọ́run àlàáfíà, sọ yín di mímọ́ pátápátá. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́ pátápátá ní àìlábùkù, títí di ìgbà wíwá Jesu Kristi Olúwa wa. Olóòtítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe.
”Nítorí náà, àwa tìkára wa ń fi yín ṣògo nínú ìjọ Ọlọ́run, nítorí sùúrù àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà. Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé nítorí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà. Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú, Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára.
”Ǹjẹ́ kí Jesu Kristi Olúwa wa tìkálára rẹ̀, àti Ọlọ́run baba wa, ẹni to ti fẹ́ wa, tí ó sì ti fi ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́ fún wa. Kí ó mú ọkàn yín le, kí ó sì kún yín pẹ̀lú agbára nínú iṣẹ́ gbogbo àti ọ̀rọ̀ rere gbogbo.
”Ǹjẹ́ kí Olúwa àlàáfíà, fúnrarẹ̀ máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo. Kí Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.
”Ma ṣe máa mu omi nìkan, ṣùgbọ́n máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí inú rẹ, àti nítorí àìlera ìgbàkúgbà.
”Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ. Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn.
”Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìsẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro.
”Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ́rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábápín nínú ìpọ́njú ìhìnrere nípa agbára Ọlọ́run, ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa nínú Kristi Jesu láti ìpìlẹ̀ ayérayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn nísinsin yìí nípa ìfarahàn Jesu Kristi Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ìhìnrere. Fún ti ìhìnrere tí a yàn mi láti jẹ oníwàásù àti aposteli àti olùkọ́. Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí: nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà.
”Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kristi Jesu pẹ̀lú ògo ayérayé. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà: Bi àwa bá bá a kú, àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀. Bí àwa bá faradà, àwa ó sì bá a jẹ ọba: Bí àwa bá sẹ́ ẹ, òun náà yóò sì sẹ́ wa.
”Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́ sùúrù. Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu ní Lysra; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn. Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kristi Jesu yóò faradà inúnibíni
”Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́njú, ṣe iṣẹ́ efangelisti, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé.
”Nítorí à ń fi mi rú ẹbọ nísinsin yìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etílé. Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́; Láti ìsinsin yìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàájọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.
”Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀: Àdúrà mi ni kí a má ṣe ká à sí wọn lọ́rùn. Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nípasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún náà. Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ búburú gbogbo, yóò sì mu mí dé inú ìjọba ọ̀run. Ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.
”ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti ṣe ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀,
”Èmi Paulu, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìhìnrere Jesu Kristi àti Timotiu arákùnrin wa. Sí Filemoni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábáṣiṣẹ́ wa,
”Síbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Paulu, arúgbó, àti nísinsin yìí òǹdè Jesu Kristi.
”Ǹjẹ́ ni ìwọ̀n bí àwọn ọmọ tí ṣe alábápín ará àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òun pẹ̀lú sì ṣe alábápín nínú ohun kan náà; kí ó lè ti ipa ikú rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára ikú run, èyí ni èṣù. Kí o sì lè gba gbogbo àwọn tí ó tìtorí ìbẹ̀rù ikú wà lábẹ́ ìdè lọ́jọ́ ayé wọn gbogbo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù.
”Nítorí níwọ̀n bí òun tìkára rẹ̀ ti jìyà tí a sì ti dán an wò, òun ní agbára láti ran àwọn tí a ń dánwò lọ́wọ́.
”Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí àtiwọ inú ìsinmi rẹ̀ fún wa, ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù, kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ba à dàbí ẹni pé ó tí kùnà rẹ̀. Nítorí tí àwa gbọ́ ìwàásù ìhìnrere, gẹ́gẹ́ bí a ti wàásù rẹ̀ fún àwọn náà pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ kò ṣe wọ́n ní àǹfààní, nítorí tí kò dàpọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú àwọn tí ó gbọ́ ọ. Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí, “Bí mo tí búra nínú ìbínú mi, ‘Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpìlẹ̀ ayé. Nítorí ó ti sọ níbìkan ní ti ọjọ́ keje báyìí pé, “Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.” Àti níhìn-ín yìí pẹ̀lú ó wí pé, “Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.” Nítorí náà bí ó tí jẹ́ pé, ó ku kí àwọn kan wọ inú rẹ̀, àti àwọn tí a ti wàásù ìhìnrere náà fún ní ìṣáájú kò wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbọ́ràn: Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dafidi pé, “Lónìí,” lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀; bí a tí wí níṣàájú, “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe sé ọkàn yín le.” Nítorí, ìbá ṣe pé Joṣua tí fún wọn ní ìsinmi, òun kì bá tí sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìsinmi mìíràn lẹ́yìn náà, nítorí náà ìsinmi kan kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.
”Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì ba ni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a wá si ibi ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí oore-ọ̀fẹ́ láti máa ran ni lọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.
”Ní ìgbà ọjọ́ Jesu nínú ayé, ó fi ìkérora rara àti omijé gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀. Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ ìgbọ́ran nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀;
”Ṣùgbọ́n ẹ rántí ọjọ́ ìṣáájú nínú èyí tí, nígbà tí a ti sí yin lójú, ẹ fi ara da wàhálà ńlá ti ìjìyà; lápákan, nígbà tí a sọ yín di ìran wíwò nípa ẹ̀gàn àti ìpọ́njú; àti lápákan, nígbà tí ẹ̀yin di ẹgbẹ́ àwọn tí a ṣe bẹ́ẹ̀ si. Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá. Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní sùúrù, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà. Nítorí, “Ni ìwọ̀n ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni náà ti ń bọ̀ yóò dé, kí yóò sì jáfara. Ṣùgbọ́n, “Olódodo ni yóò yè nípa ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n bí o ba fàsẹ́yìn, ọkàn mi kò ní inú dídùn sí i.”
”Nítorí náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe ti ara ọkùnrin kan jáde, àní ara ẹni tí o dàbí òkú, ọmọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ́pọ̀lọpọ̀, àti bí iyanrìn etí Òkun láìníye.
”Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ó kú nínú ìgbàgbọ́, láìrí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, tí wọ́n sì gbá wọn mú, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ pé àlejò àti àjèjì ni àwọn lórí ilẹ̀ ayé.
”Nípa ìgbàgbọ́ ni Mose, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọbìnrin Farao; o kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ: Nítorí tí ó ń wo èrè náà. Nípa ìgbàgbọ́ ni o kọ Ejibiti sílẹ̀ láìbẹ̀rù ìbínú ọba: nítorí tí o dúró ṣinṣin bí ẹni tí ó n ri ẹni àìrí.
”Èwo ni èmi o sì tún máa wí sí i? Nítorí pé ìgbà yóò kùnà fún mi láti sọ ti Gideoni, àti Baraki, àti Samsoni, àti Jefta; àti Dafidi, àti Samuẹli, àti ti àwọn wòlíì: Àwọn ẹni nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tiwọn ṣẹ́gun ilẹ̀ ọba, tí wọn ṣiṣẹ́ òdodo, tiwọn gba ìlérí, tiwọn dí àwọn kìnnìún lénu, Tí wọ́n pa agbára iná, tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ojú idà, tí a sọ di alágbára nínú àìlera, tí wọ́n dí akọni nínú ìjà, wọ́n lé ogun àwọn àjèjì sá. Àwọn obìnrin ri òkú wọn gbà nípa àjíǹde: a sì da àwọn ẹlòmíràn lóró, wọ́n kọ̀ láti gba ìdásílẹ̀; kí wọn ba lè rí àjíǹde tí o dára jù gbà; Àwọn ẹlòmíràn sì rí ìjìyà ẹ̀sín, àti nínà, àti ju bẹ́ẹ̀ lọ, ti ìdè àti ti túbú: A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn: wọ́n rìn káàkiri nínú awọ àgùntàn àti nínú awọ ewúrẹ́; wọn di aláìní, olùpọ́njú, ẹni tí a ń da lóró; Àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún: Wọ́n ń kiri nínú aṣálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀. Gbogbo àwọn wọ̀nyí tí a jẹ́rìí rere sí nípa ìgbàgbọ́, wọn kò sì rí ìlérí náà gbà: Nítorí Ọlọ́run ti pèsè ohun tí ó dára jù sílẹ̀ fún wa, pé láìsí wa, kí a má ṣe wọn pé.
”Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa, Kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run. Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìṣọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.
”Ẹ̀yin kò sá à tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ìjàkadì yín. Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé, “Ọmọ mi, ma ṣe aláìnání ìbáwí Olúwa, kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí: Nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i bá wí, a sì máa na olúkúlùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gbà.” Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí: Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í bá wí? Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, ǹjẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ. Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè? Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀. Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsin yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.
”Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera; “Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn.
”Ẹ máa rántí àwọn òǹdè bí ẹni tí a dè pẹ̀lú wọn, àti àwọn tí a ń pọn lójú bí ẹ̀yin tìkára yín pẹ̀lú tí ń bẹ nínú ara.
”Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé, “Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.” Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé, “Olúwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù; kín ni ènìyàn lè ṣe sí mi?”
”Nítorí náà Jesu pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ́yìn ibodè. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀. Nítorí pé àwa kò ní ìlú tí o wa títí níhìn-ín, ṣùgbọ́n àwa ń wá èyí tí ń bọ.
”Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín fun ni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.
”Ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀; nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣiṣẹ́ sùúrù. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò ṣe aláìní ohunkóhun.
”Ìbùkún ni fún ọkùnrin tí ó fi ọkàn rán ìdánwò; nítorí nígbà tí ó bá yege, yóò gba adé ìyè, tí Olúwa ti ṣèlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ.
”Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù. Sá à wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fi ara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jobu, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú.
”Inú ẹnikẹ́ni ha bàjẹ́ nínú yín bí? Jẹ́ kí ó gbàdúrà. Inú ẹnikẹ́ni ha dùn? Jẹ́ kí ó kọrin mímọ́. Ẹnikẹ́ni ha ṣe àìsàn nínú yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ìjọ, kí wọ́n sì gbàdúrà sórí rẹ̀, kí wọn fi òróró kùn ún ní orúkọ Olúwa: Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì gba aláìsàn náà là, Olúwa yóò sì gbé e dìde; bí ó bá sì ṣe pé ó ti dẹ́ṣẹ̀, a ó dáríjì í. Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, kí a lè mú yín láradá. Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń ṣe ní agbára púpọ̀.
”Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́: Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi.
”Nítorí pé èyí ní ìgbóríyìn fún, bí ènìyàn bá fi ara da ìrora, ìjìyà lọ́nà àìtọ́, nítorí ọkàn rere sí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ògo kín ni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba ṣẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á? Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, ẹ̀yín ní ọpẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Sí èyí ni a pè yín: nítorí Kristi pẹ̀lú jìyà fún un yin, ó fi àpẹẹrẹ sílẹ̀ fún un yín, kí ẹ̀yin lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀: “Òun kò dẹ́ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni, a kò rí ẹ̀tàn kan lẹ́nu rẹ̀.” Ẹni, nígbà tí a kẹ́gàn rẹ̀, tí kò sì padà kẹ́gàn; nígbà tí ó jìyà tí kò sì halẹ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹni ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́. Ẹni tí òun tìkára rẹ̀ fi ara rẹ̀ ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi àgbélébùú, pé kí àwa lè di òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ki a sì di ààyè sí òdodo: nípa ìjìyà ẹni tí ó mú yín láradá.
”Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.”
”Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ. Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí:
”Ǹjẹ́ bí Kristi ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra; nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀;
”Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrín yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín: Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábápín ìyà Kristi, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn. Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín. Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí apànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣe búburú, tàbí bí ẹni tí ń tojú bọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí Kristiani kí ojú má ṣe tì í: ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo nítorí ti o orúkọ yìí.
”Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwọn tí ń jìyà gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run ni ṣíṣe rere, fi ọkàn wọn lè Ẹlẹ́dàá olóòtítọ́ lọ́wọ́.
”Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrín yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, àti alábápín nínú ògo tí a ó fihàn:
”Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákokò. Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín. Ẹ máa wà ni àìrékọjá, ẹ máa ṣọ́ra; nítorí èṣù ọ̀tá yín, bí i kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń rìn káàkiri, ó ń wa ẹni tí yóò pajẹ. Ẹ kọ ojú ìjà sí i pẹ̀lú ìdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ìyà kan náà ni àwọn ará yín tí ń bẹ nínú ayé ń jẹ. Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kristi Jesu, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkára rẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀.
”Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀.
”Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdánwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
”Ṣùgbọ́n, olùfẹ́, ẹ má ṣe gbàgbé ohun kan yìí, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa bí ẹgbẹ̀rún ọdún ni ó rí, àti ẹgbẹ̀rún ọdún bí ọjọ́ kan. Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.
”Ẹ̀yin ọmọ mi, ti Ọlọ́run ni yín, ẹ̀yin sì tí ṣẹ́gun wọn: nítorí ẹni tí ń bẹ nínú yin tóbi jú ẹni tí ń bẹ nínú ayé lọ.
”Báyìí ni àwa mọ̀, tí a sì gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́. Ìfẹ́ ni Ọlọ́run; ẹni tí ó bá sì ń gbé inú ìfẹ́, ó ń gbé inú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀. Nínú èyí ni a mú ìfẹ́ tí ó wà nínú wa pé, kí àwa bà á lè ni ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́: nítorí pé bí òun tí rí, bẹ́ẹ̀ ni àwa sì rí ni ayé yìí. Ìbẹ̀rù kò sí nínú ìfẹ́; ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó pé ń lé ìbẹ̀rù jáde; nítorí tí ìbẹ̀rù ni ìyà nínú. Ẹni tí ó bẹ̀rù kò pé nínú ìfẹ́.
”nítorí olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run, ó ṣẹ́gun ayé. Èyí sì ni ìṣẹ́gun tí ó ṣẹ́gun ayé, àní ìgbàgbọ́ wa. Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé, bí kò ṣe ẹni tí ó gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jesu jẹ́?
”Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa; Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tí wa, ohunkóhun tí àwa bá béèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà.
”Olùfẹ́, èmi ń gbàdúrà pé nínú ohun gbogbo kí o lè máa dára fún ọ, kí o sì máa wà ni ìlera, àní bí o tí dára fún ọkàn rẹ.
”Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́.
”Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìyè nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrín Paradise Ọlọ́run.
”“Àti sí angẹli ìjọ ní Smirna kọ̀wé: Nǹkan wọ̀nyí ni ẹni tí í ṣe ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó ti kú, tí ó sì tún yè: Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́, èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé, Júù ni àwọn tìkára wọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ Sinagọgu ti Satani. Má ṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀. Kíyèsi i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túbú, kí a lè dán yin wò; ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá: ìwọ ṣa ṣe olóòtítọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ.
”Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun kì yóò fi ara pa nínú ikú kejì.
”Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ; Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi manna tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á.
”Ẹni tí ó bá sì ṣẹ́gun, àti tí ó sì ṣe ìfẹ́ mi títí dé òpin, èmi ó fún un láṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè: ‘Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn; gẹ́gẹ́ bí a ti ń fọ́ ohun èlò amọ̀kòkò ni a ó fọ́ wọn túútúú,’ gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tí gbà àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi. Èmi yóò sì fi ìràwọ̀ òwúrọ̀ fún un. Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
”Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀; èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn angẹli rẹ̀. Ẹni tí ó ba létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
”Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹmpili Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́: èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerusalẹmu tuntun, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá: àti orúkọ tuntun ti èmi tìkára mi. Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun ti Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
”Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi, bí èmi pẹ̀lú ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.”
”Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.” Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà. Nítorí náà ni, “wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹmpili rẹ̀; ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si ṣíji bò wọn. Ebi kì yóò pa wọn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ́ wọ́n mọ́; bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọn tàbí oorukóoru kan. Nítorí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń bẹ ni àárín ìtẹ́ náà ni yóò máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn wọn, ‘tí yóò sì máa ṣe amọ̀nà wọn sí ibi orísun omi ìyè:’ ‘Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn.’ ”
”Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn náà, àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn, wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀mí wọn àní títí dé ikú.
”Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jesu mọ́. Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.” Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sinmi kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”
”Àti nínú rẹ̀ ní a gbé ri ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì, àti ti àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé.”
”Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọ́n: mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jesu, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà ààmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn; wọ́n sì wà láààyè, wọ́n sì jẹ ọba pẹ̀lú Kristi ní ẹgbẹ̀rún ọdún.
”Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn; kì yóò sì ṣí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ.” Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, “Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun!” Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n.” Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí; èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi.
”