01 – Bibeli Mimọ
Awọn wọnyi ni awọn ọrọ mimọ ti Ọlọrun Olodumare.
A ko nifẹ si awọn ọrọ ti awọn eniyan.
Fun ẹnikẹni ti o ba fẹràn Ọlọrun ... Eyi ni ohun ti Ọlọrun sọ nipa: Bibeli Mimọ.
Awọn wọnyi ni awọn ọrọ mimọ ti Ọlọrun Olodumare.
A ko nifẹ si awọn ọrọ ti awọn eniyan.
Fun ẹnikẹni ti o ba fẹràn Ọlọrun ... Eyi ni ohun ti Ọlọrun sọ nipa: Bibeli Mimọ.
Gbogbo ìwé mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo.
”Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, ààmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé òfin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ.
”Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.
”Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn.
”Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí OLÚWA Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?”
”OLÚWA sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo.
”Ológun ni OLÚWA, OLÚWA ni orúkọ rẹ,
”Nígbà ti Mose lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ àti òfin OLÚWA, wọ́n wí ní ohùn kan pé, “Gbogbo ohun ti OLÚWA wí ni àwa yóò ṣe.” Nígbà náà ni Mose kọ gbogbo ohun tí OLÚWA sọ sílẹ̀. Ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mọ pẹpẹ ni ẹsẹ̀ òkè náà. Ó ṣe ọ̀wọ́n òkúta méjìlá. Èyí ti ó dúró fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.
”Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà. Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é? Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu un ṣẹ?
”Ẹ má ṣe fi kún àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún un yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ yọ kúrò nínú wọn, Ṣùgbọ́n ẹ pa òfin OLÚWA Ọlọ́run yín tí mo fún un yín mọ́.
”Ẹ kíyèsi i, mo ti kọ́ ọ yín ní àwọn òfin àti àṣẹ bí OLÚWA Ọlọ́run mi ti pàṣẹ fún mi, kí ẹ ba à le tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń lọ láti ní ní ìní. Ẹ máa kíyèsi wọn dáradára. Èyí ni yóò fi ọgbọ́n àti òye yín han àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn tí wọn yóò gbọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí wọn yóò sì máa wí pé, “Dájúdájú, orílẹ̀-èdè ńlá yìí kún fún ọgbọ́n àti òye.”
”Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín ní Horebu, nígbà tí ó wí fún mi pé, “Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ síwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.”
”Torí pé iná ajónirun ni OLÚWA Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni.
”Torí èyí, ẹ ṣọ́ra láti máa ṣe ohun tí OLÚWA Ọlọ́run yín tí pa ní àṣẹ fún un yín; ẹ má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì.
”Fẹ́ràn OLÚWA Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ. Àwọn àṣẹ tí mo fún un yín lónìí gbọdọ̀ máa wà lóókan àyà yín. Ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín gidigidi. Bí ẹ bá jókòó nínú ilé, ẹ jíròrò nípa wọn, àti nígbà tí ẹ bá ń rìn ní ojú ọ̀nà, bí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde. Ẹ so wọ́n sí ọwọ́ yín fún ààmì, ẹ so ó mọ́ iwájú orí yín. Kí ìwọ kí ó kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ̀, àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ.
”Ó rẹ̀ yín sílẹ̀ nípa fífi ebi pa yín, Ó sì fi manna bọ́ ọ yín, èyí tí ẹ kò mọ̀, tí àwọn baba yín kò mọ̀, kí ó ba à lè kọ́ ọ yín pé, ènìyàn kò ti ipa oúnjẹ nìkan wà láààyè, bí kò ṣe ohun gbogbo tí ó jáde láti ẹnu OLÚWA wá.
”Nítorí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin OLÚWA Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀.
”OLÚWA sì sọ fún mi pé, “Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle gbá à ni wọ́n.
”Nísinsin yìí ìwọ Israẹli, kín ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe kí ìwọ bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run rẹ àti láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti fẹ́ràn rẹ̀, láti fi gbogbo ọkàn rẹ sin OLÚWA Ọlọ́run rẹ ọkàn àti àyà rẹ, àti láti máa kíyèsi àṣẹ àti ìlànà OLÚWA tí mo ń fún ọ lónìí, fún ìre ara à rẹ.
”Ẹ fẹ́ràn OLÚWA Ọlọ́run yín, kí ẹ sì pa ìfẹ́ rẹ̀, ìlànà rẹ̀, òfin rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ ní ìgbà gbogbo.
”Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà a yín, àti ọkàn an yín, ẹ so wọ́n bí ààmì sórí ọwọ́ yín, kí ẹ sì so wọ́n mọ́ iwájú orí yín. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí. Kí ìwọ kí ó kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ̀, àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ.
”Ẹ kíyèsi i, mo fi ìbùkún àti ègún lélẹ̀ níwájú u yín lónìí: ìbùkún ni, bí ẹ bá pa òfin OLÚWA Ọlọ́run yín, tí mo ń fún un yín lónìí mọ́. Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin OLÚWA Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tí ì mọ̀.
”Ẹ rí i pé ẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tí mo ti pàṣẹ fún un yín. Ẹ má ṣe fi kún un, ẹ má sì ṣe yọ kúrò níbẹ̀.
”Bí wòlíì tàbí alásọtẹ́lẹ̀ nípa àlá lílá bá farahàn láàrín yín, tí ó sì ń kéde iṣẹ́ ààmì tàbí iṣẹ́ ìyanu, bí iṣẹ́ ààmì tàbí iṣẹ́ ìyanu tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ṣẹ tí òun sì wí pé, “ẹ wá ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn” (àwọn ọlọ́run tí ẹ kò mọ̀ rí) “kí ẹ sì jẹ́ kí a máa sìn wọ́n,” ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ wòlíì tàbí àlá náà, OLÚWA Ọlọ́run yín ń dán an yín wò ni, láti mọ̀ bóyá ẹ fẹ́ràn rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn an yín. OLÚWA Ọlọ́run yín ni kí ẹ tẹ̀lé, Òun ni kí ẹ bu ọlá fún, ẹ pa òfin rẹ̀ mọ́ kí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀: ẹ sìn ín, kí ẹ sì dìímú ṣinṣin.
”Èyí yóò sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun ó sì máa kà nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kí ó lè máa kọ́ àti bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀, láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà rẹ̀ tọkàntọkàn.
”OLÚWA Ọlọ́run rẹ pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa tẹ̀lé àwọn ìlànà àti òfin, kí o sì máa ṣe wọ́n pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo àyà rẹ.
”“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa ṣíṣe wọ́n.” Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
”Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ.
”Ṣùgbọ́n bí o kò bá gbọ́ ti OLÚWA Ọlọ́run rẹ kí o sì rọra máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mò ń fún ọ lónìí, gbogbo ègún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ:
”Ohun ìkọ̀kọ̀ jẹ́ ti OLÚWA Ọlọ́run wa, ṣùgbọ́n ohun tí a fihàn jẹ́ ti wa àti ti àwọn ọmọ wa títí láé, kí a lè tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.
”Bí o bá gbọ́ ti OLÚWA Ọlọ́run rẹ tí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́ àti àṣẹ tí a kọ sínú ìwé òfin yìí kí o sì yípadà sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.
”Èmi pe ọ̀run àti ilẹ̀ láti jẹ́rìí tì yín ní òní pé, èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ,
”Pe àwọn ènìyàn jọ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn àjèjì tí ń gbé àwọn ìlú u yín kí wọn lè fetí sí i kí wọn sì lè kọ́ láti bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run rẹ kí wọn sì rọra tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí.
”“Gba ìwé òfin yìí kí o sì fi sí ẹ̀gbẹ́ àpótí ẹ̀rí OLÚWA Ọlọ́run rẹ. Níbẹ̀ ni yóò wà bí ẹ̀rí sí ọ. Nítorí mo mọ irú ọlọ̀tẹ̀ àti ọlọ́rùn líle tí ẹ jẹ́. Bí o bá ṣe ọlọ̀tẹ̀ sí OLÚWA nígbà tí mo pàpà wà láyé Pẹ̀lú yín, báwo ní ẹ ó ti ṣe ọlọ̀tẹ̀ tó nígbà tí mo bá kú tán!
”Má ṣe jẹ́ kí Ìwé Ofin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí.
”Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé, ẹ bẹ̀rù OLÚWA, kí ẹ sì sìn ín nínú òtítọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an yín; Ẹ kíyèsi ohun ńlá tí ó ti ṣe fún un yín.
”Ṣùgbọ́n Samuẹli dáhùn pé, “OLÚWA ha ní inú dídùn sí ẹbọ sísun àti ẹbọ ju kí a gba ohùn OLÚWA gbọ́? Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ. Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ, àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà. Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ OLÚWA, Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.” Nígbà náà ni Saulu wí fún Samuẹli pé, “Èmi ti ṣẹ̀. Mo ti rú òfin OLÚWA àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́.
”Nítorí pé èmi pa ọ̀nà OLÚWA mọ́, èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi. Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn.
”Ṣùgbọ́n wọn kò ní gbọ́, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́rùn líle gẹ́gẹ́ bí i ti baba wọn, ẹni tí kò gbà OLÚWA Ọlọ́run wọn gbọ́.
”“Ẹ lọ kí ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ OLÚWA fún mi nípa àwọn ìyókù Israẹli àti Juda nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú OLÚWA tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ OLÚWA mọ́, wọn kò sì tí ì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.”
”Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùn sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣẹ̀sín títí tí ìbínú Ọlọ́run fi ru sórí wọn, sí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì ṣí àtúnṣe.
”Esra ti fi ara rẹ̀ jì fún kíkọ́ àti pípa òfin OLÚWA mọ́, ó sì ń kọ́ òfin àti ìlànà Mose ní Israẹli.
”Nígbà náà ni gbogbo àwọn tí ó wárìrì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Israẹli kó ara wọn jọ yí mi ká nítorí àìṣòótọ́ àwọn ìgbèkùn yìí. Èmi sì jókòó níbẹ̀ ní ìjayà títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́.
”Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!’ Nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ.
”Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹnu rẹ̀, èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ.
”Nígbà náà ní OLÚWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé: “Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìlóye láti fi ṣókùnkùn bo ìmọ̀ mi? Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dá mi lóhùn. “Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye.
”Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin OLÚWA àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
”Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì jẹ aláìlábùkù, gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀, tí a sọ di mímọ́ nígbà méje. OLÚWA, ìwọ yóò pa wá mọ́ kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.
”Nítorí mo ti pa ọ̀nà OLÚWA mọ́; èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi
”Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé, a ti rídìí ọ̀rọ̀ OLÚWA òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
”Pípé ni òfin OLÚWA, ó ń yí ọkàn padà. Ẹ̀rí OLÚWA dánilójú, ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n. Ìlànà OLÚWA tọ̀nà, ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn. Àṣẹ OLÚWA ni mímọ́, ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú. Ìbẹ̀rù OLÚWA mọ́, ó ń faradà títí láéláé. Ìdájọ́ OLÚWA dájú òdodo ni gbogbo wọn. Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ, ju wúrà tí o dára jùlọ, wọ́n dùn ju oyin lọ, àti ju afárá oyin lọ. Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí; nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
”Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi, èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.
”Ohùn OLÚWA ní agbára; ohùn OLÚWA kún fún ọláńlá.
”Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé; ìwọ ni o ti rà mí padà, OLÚWA, Ọlọ́run òtítọ́.
”Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ. Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka, tí kò ní òye ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀, kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.
”Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù OLÚWA: jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.
”Ìgbìmọ̀ OLÚWA dúró títí ayérayé, àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.
”Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi; èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù OLÚWA.
”Nígbà náà ni mo wí pé, “Èmi nìyí; nínú ìwé kíká ni a kọ ọ nípa tèmi wí pé. Mo ní inú dídùn láti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi; Òfin rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.” Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlà láàrín àwùjọ ńlá; wò ó, èmi kò pa ètè mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀, ìwọ OLÚWA. Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà sin ní àyà mi; èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ àti ìgbàlà rẹ. Èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò láàrín àwọn ìjọ ńlá.
”Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú: “Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ, tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ? Ìwọ kórìíra àṣẹ mi, ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.
”Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run, kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.
”Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀, púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.
”Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́ wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀
”“Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi; Israẹli kò ní tẹríba fún mi. Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn. “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi, Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn! Àwọn tí ó kórìíra OLÚWA yóò tẹríba níwájú rẹ̀. Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé
”Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLÚWA, èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ; fún mi ní ọkàn tí kì í yapa, kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.
”Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi; ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.
”Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
”Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo, Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀; wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.
”Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú.
”Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú. Wọ́n dúró láé àti láé, ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.
”Ìbẹ̀rù OLÚWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n: òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀, ìyìn rẹ̀ dúró láé.
”Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.
”Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA ju àti gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn lọ. Ó dára láti máa gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA ju à ti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ-aládé lọ.
”Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀, ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin OLÚWA,
”Nígbà náà, ojú kò ní tì mí nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.
”Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.
”Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.
”Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ
”Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.
”La ojú mi kí èmi lè ríran rí ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.
”Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.
”Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.
”Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
”Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́ èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
”Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
”Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo láé àti láéláé.
”Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
”Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú, tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
”Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
”Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.
”Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.
”Ọ̀rọ̀ rẹ, OLÚWA, títí láé ni; ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run
”Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
”Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó, ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
”Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ; nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.
”Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi
”Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́ láé dé òpin.
”Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú, kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!
”Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ, nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.
”Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, OLÚWA; nítorí òfin rẹ ti fọ́.
”Omijé sàn jáde ní ojú mi, nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
”Ìtara mi ti pa mí run, nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
”Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
”Òdodo rẹ wà títí láé òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
”Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru, nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
”Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ; gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
”Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí, ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ.
”Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀.
”Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, OLÚWA, àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi.
”Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀ èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ; nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
”Ìbẹ̀rù OLÚWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.
”“Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ̀kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó? Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó? Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀?
”Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀ tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù OLÚWA. Níwọ́n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi, Wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún
”tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n tí ìwọ sì fi ọkàn rẹ sí òye, àní, bí ìwọ bá ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn, tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bí i fàdákà tí ìwọ sì wa kiri bí ìṣúra tí a fi pamọ́. Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù OLÚWA, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.
”Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ.
”Gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ;
”Gba ọgbọ́n, gba òye, Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀ Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́, fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.
”Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ; fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ;
”Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú, jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á. Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì; pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.
”Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà, ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí ni ọ̀nà sí ìyè.
”Ìbẹ̀rù OLÚWA ni ìkórìíra ibi mo kórìíra ìgbéraga àti agídí, ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
”Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ. Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;
”“Ìbẹ̀rù OLÚWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ nípa Ẹni mímọ́ ni òye.
”Ìbẹ̀rù OLÚWA jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.
”Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ àti láti yan òye dípò o fàdákà!
”Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè; nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ.
”Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin, kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.
”“Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù; òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.
”Nísinsin yìí, òpin gbogbo ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́, nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn.
”Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná, bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku: nítorí pé wọ́n ti kọ òfin OLÚWA àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀ wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli.
”Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé: “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’
”Sí òfin àti májẹ̀mú! Bí wọn kò bá sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò rí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́.
”Lọ nísinsin yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara wàláà fún wọn, tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká, pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀ kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé. Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn àti ẹlẹ́tanu ọmọ, àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí sí ìtọ́ni OLÚWA. Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé, “Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!” Àti fún àwọn wòlíì, “Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́! Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa, ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn. Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀, ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọ wá pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ Israẹli!” Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni Mímọ́ Israẹli wí: “Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, ẹ gbára lé ìnilára kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀tàn, ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì tí ó sì wó lójijì, àti ní ìṣẹ́jú kan.
”Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”
”Ta ni ó ti gba ìròyìn in wa gbọ́ àti ta ni a ti fi apá OLÚWA hàn fún?
”“Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín, tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,” ni OLÚWA wí. “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ àti èrò mi ju èrò yín lọ.
”bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá; kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́, yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ.
”Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín! Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ, èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀ ni yóò jogún ilẹ̀ náà yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”
”“Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni OLÚWA wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé” ni OLÚWA wí.
”Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?” ni OLÚWA wí. “Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí: ẹni náà tí ó rẹra rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀, tí ó sì wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi.
”Fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọn n ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn. Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn, nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tí sílẹ̀. Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú mi wọ́n sì yan ohun tí mo kórìíra rẹ̀.” Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA, Ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kórìíra yín, tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé, ‘Jẹ́ kí a yin OLÚWA lógo, kí a le rí ayọ̀ yín!’ Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.
”OLÚWA, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́ Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n. Ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà. Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ, wọ́n sì kọ̀ láti yípadà. Èmi sì rò pé, “Tálákà ni àwọn yìí; wọn jẹ́ aṣiwèrè, nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà OLÚWA, àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.
”Gbọ́, ìwọ ayé! Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, èso ìrò inú wọn, nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀.
”Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé: Gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Máa rìn ní ojú ọ̀nà tí mo pàṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín. Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, wọn kò sì fetísílẹ̀ dípò èyí wọ́n ń tẹ̀ sí ọ̀nà agídí ọkàn wọn. Dípò kí wọn tẹ̀síwájú wọ́n ń rẹ̀yìn.
”Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n, a ó dà wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn. Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLÚWA. Irú ọgbọ́n wo ló kù tí wọ́n ní?
”Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀, Èmi yóò sọkún ní ìkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín; Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò, tí omi ẹkún, yóò sì máa sàn jáde, nítorí a kó agbo OLÚWA lọ ìgbèkùn.
”Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n Àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi Nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí Ìwọ OLÚWA Ọlọ́run Alágbára.
”Báyìí ni OLÚWA wí: “Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn, tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara, àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ OLÚWA
”Síbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí.
”“Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò mú ìdààmú tí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ bá ìlú yìí àti ìgbèríko tí ó yí i ká, nítorí ọlọ́rùn líle ni wọ́n, wọn kò si ní fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.’ ”
”Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ má ṣe fi etí sí àsọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlíì èké ń sọ fún un yín. Wọ́n ń kún inú ọkàn yín pẹ̀lú ìrètí asán. Wọ́n ń sọ ìran láti ọkàn ara wọn, kì í ṣe láti ẹnu OLÚWA.
”“Ọ̀rọ̀ mi kò ha a dàbí iná?” ni OLÚWA wí, “àti bí òòlù irin tí ń fọ́ àpáta túútúú?
”Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLÚWA ti rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì sí i yín láti ìgbà dé ìgbà, ẹ̀yin kò fetísílẹ̀.
”Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé kalẹ̀ níwájú yín, àti tí ẹ kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín léraléra (ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́), nígbà náà ni èmi yóò ṣe ilé yìí bí Ṣilo, èmi yóò sì ṣe ìlú yìí ní ìfibú sí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’ ”
”Nísinsin yìí, tún ọ̀nà rẹ ṣe àti ìṣe rẹ, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run yín. OLÚWA yóò yí ọkàn rẹ̀ padà, kò sì ní mú ohun gbogbo tí ó ti sọ jáde ní búburú ṣẹ lórí yín.
”Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: “Ẹ má ṣe gbà kí àwọn wòlíì èké àti àwọn aláfọ̀ṣẹ àárín yín tàn yín jẹ. Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí àlá, èyí tí ẹ gbà wọ́n níyànjú láti lá. Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín lórúkọ mi; Èmi kò rán wọn níṣẹ́,” ni OLÚWA wí.
”“Ìgbà kan ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “tí Èmi yóò bá ilé Israẹli àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun. Kò ní dàbí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́, tí mo mú wọn jáde ní Ejibiti nítorí wọ́n da májẹ̀mú mi. Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn,” ni OLÚWA wí. “Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá lẹ́yìn ìgbà náà,” ni OLÚWA wí pé: “Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn, èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn. Èmi ó jẹ́ OLÚWA wọn; àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi. Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀ tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ OLÚWA,’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,” ni OLÚWA wí. “Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì, èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”
”“Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin tún wí pe, ‘ọ̀nà Olúwa kò gún.’ Gbọ́ nísinsin yìí ìwọ ilé Israẹli: ọ̀nà mi ni kò ha gún? Kì í wa ṣé pé ọ̀nà tiyín gan an ni kò gún?
”Wọn yóò sì fi ìyàtọ̀ tí ó wà láàrín mímọ́ àti àìmọ́ kọ́ àwọn ènìyàn mi, wọn yóò sì fihàn wọ́n bi wọn yóò ṣe dá aláìmọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí mímọ́.
”Àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀. “Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀. Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi; nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀ Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.
”Ègbé ní fún wọn, nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun wà lórí wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi! Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà. Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi
”“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA Olódùmarè wí, “nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òǹgbẹ fún omi. Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA.
”“Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́. Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun. “ ‘Ó sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti kígbe, tí wọn kò sì fẹ́ gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kígbe, tí èmi kò sì fẹ́ gbọ́,’ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.
”Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá.’ ”
”“Ẹ má ṣe rò pé, èmí wá láti pa òfin àwọn wòlíì run, èmi kò wá láti pa wọn rẹ́, bí kò ṣe láti mú wọn ṣẹ. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, ààmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé òfin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ. Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jùlọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jùlọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe wọ́n, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run.
”“Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.
”“Ẹ ba ẹnu-ọ̀nà tóóró wọlé; gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé. Nítorí kékeré ni ẹnu-ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú ọ̀nà náà, ti ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín.
”“Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run. Ọ̀pọ̀ ni yóò wí fún mi ní ọjọ́ náà pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, àti ní orúkọ rẹ kọ́ ni a fi lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu?’ Nígbà náà ni èmi yóò wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí, ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
”“Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fiwé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta. Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sí bì lu ilé náà; síbẹ̀síbẹ̀ náà kò sì wó, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí kò bá sì ṣe wọ́n, òun ni èmi yóò fiwé aṣiwèrè ènìyàn kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí iyanrìn. Òjò sì rọ̀, ìkún omi sì dé, afẹ́fẹ́ sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ilé náà sì wó; wíwó rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ.”
”Bí ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tàbí tí kò gba ọ̀rọ̀ yín, ẹ gbọn eruku ẹ̀ṣẹ̀ yín sílẹ̀ tí ẹ bá ń kúrò ní ilé tàbí ìlú náà. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò sàn fún ìlú Sodomu àti Gomorra ní ọjọ́ ìdájọ́ ju àwọn ìlú náà lọ.
”“Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú ènìyàn, òun náà ni èmi yóò jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mí níwájú àwọn ènìyàn, òun náà ni èmi náà yóò sọ wí pé n kò mọ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run.
”“Ẹni tí ó bá fẹ́ baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi, ẹni tí ó ba fẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi; Ẹni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀lé mi kò yẹ ní tèmi. Ẹni tí ó bá wa ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i. “Ẹni tí ó bá gbà yín, ó gbà mí, ẹni tí ó bá sì gbà mí gba ẹni tí ó rán mi.
”Ó sì da wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a ti fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wọn.
”Ìdí nìyìí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀: “Ní ti rí rí, wọn kò rí; ní ti gbígbọ́ wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yé wọn. Sí ara wọn ni a ti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Isaiah ṣẹ: “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọ́n kì yóò sì yé yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye. Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́ etí wọn sì wúwo láti gbọ́ ojú wọn ni wọ́n sì dì nítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn rí kí wọ́n má ba à fi etí wọn gbọ́ kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òye, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi ba à le mú wọn láradá.’ Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ojú yín, nítorí wọ́n ríran, àti fún etí yín, nítorí ti wọ́n gbọ́. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti ènìyàn Ọlọ́run ti fẹ́ rí ohun tí ẹ̀yin ti rí, ki wọ́n sì gbọ́ ohun tí ẹ ti gbọ́, ṣùgbọ́n kò ṣe é ṣe fún wọn. “Nítorí náà, ẹ fi etí sí ohun tí òwe afúnrúgbìn túmọ̀ sí: Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìjọba ọ̀run ṣùgbọ́n tí kò yé e, lẹ́yìn náà èṣù á wá, a sì gba èyí tí a fún sí ọkàn rẹ̀ kúrò. Èyí ni irúgbìn ti a fún sí ẹ̀bá ọ̀nà. Ẹni tí ó sì gba irúgbìn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ orí àpáta, ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, lọ́gán, ó sì fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà. Ṣùgbọ́n nítorí kò ní gbòǹgbò, ó wà fún ìgbà díẹ̀; nígbà tí wàhálà àti inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà ní ojú kan náà yóò sì kọsẹ̀. Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e; òun sì so èso òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n.”
”Jesu dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi ti ń bẹ ni ọ̀run kò bá gbìn ni á ó fàtu tigbòǹgbò tigbòǹgbò,
”Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí. Nítorí ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run.
”Jesu dáhùn pé, “ ‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ.’ Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ. Èkejì tí ó tún dàbí rẹ̀ ní pé, ‘Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ Lórí àwọn òfin méjèèjì yìí ni gbogbo òfin àti àwọn wòlíì rọ̀ mọ́.”
”A ó sì wàásù ìhìnrere nípa ìjọba náà yìí ní gbogbo ayé ká, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.
”Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.
”Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi.
”Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Herodu ti fi Johanu sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jesu lọ sí Galili, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run. Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìhìnrere yìí gbọ́.”
”Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, “ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run. Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ” Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Bí òwe tí ó rọrùn yìí kò bá yé e yín? Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn mìíràn tí mo ń sọ fún un yín? Afúnrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà. Àwọn èso tó bọ́ sí ojú ọ̀nà, ni àwọn ọlọ́kàn líle tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lójúkan náà èṣù wá ó sì mú kí wọn gbàgbé ohun tí wọ́n ti gbọ́. Bákan náà, àwọn tí ó bọ́ sórí àpáta, ni àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kò ni gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n á wà fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà nígbà ti wàhálà tàbí inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà, wọ́n á kọsẹ̀. Àwọn tí ó bọ́ sáàrín ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí àti ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà á lóòtítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”
”Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.”
”Ẹ̀yin ń fi òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tiyín tí ẹ fi lélẹ̀, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán àti ọ̀pọ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń ṣe.”
”Nígbà náà ni Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn. Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìhìnrere, òun náà ni yóò gbà á là. Nítorí èrè kí ni ó jẹ́ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàṣípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀? Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, tí ó kún fún àìgbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, Ọmọ Ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá padà dé nínú ògo Baba rẹ̀, pẹ̀lú àwọn angẹli mímọ́.”
”Jesu dáhùn ó wí fún wọn pé, “Kì í há ṣe nítorí èyí ni ẹ ṣe ṣìnà, pé ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́, tàbí agbára Ọlọ́run.
”Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé.
”Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun.
”Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì máa wàásù ìhìnrere mi fún gbogbo ẹ̀dá. Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí a sì tẹ̀bọmi yóò là. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò gbàgbọ́ yóò jẹ̀bi.
”Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì jáde lọ. Wọ́n ń wàásù káàkiri. Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, ó sì ń fi ìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nípa àwọn ààmì tí ó tẹ̀lé e.
”(Idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”
”Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan.’ ”
”Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàṣẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀.
”“Nítorí náà, èéṣe tí ẹ̀yin ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ tí ẹ̀yin kò sì ṣe ohun tí mo wí? Ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ mí wá, tí ó sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì ń ṣe é, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín; Ó jọ Ọkùnrin kan, tí ó kọ́ ilé, tí ó sì wa ilẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta, nígbà tí kíkún omi sì dé, ìgbì omi kọlu ilé náà, kò sì lè mì ín nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́, tí kò sì ṣe é, ó dàbí ọkùnrin tí ó kọ́ ilé sí orí ilẹ̀ láìní ìpìlẹ̀; nígbà tí ìgbì omi kọlù ú, lọ́gán, ó sì wó; wíwó ilé náà sì pọ̀ púpọ̀.”
”Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn wọn yóò jẹ́ òwe, pé ní rí rí, “ ‘kí wọn má ba à rí, àti ní gbígbọ́ kí ó má lè yé wọn.’ “Ǹjẹ́ òwe náà ni èyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ti ẹ̀bá ọ̀nà ni àwọn tí ó gbọ́ nígbà náà ni èṣù wá ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò ní ọkàn wọn, kí wọn má ba à gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là. Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sá à díẹ̀; nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn. Àwọn tí ó bọ́ sínú ẹ̀gún ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ tán, wọ́n ti n lọ, wọn a sì fi ìtọ́jú àti ọrọ̀ àti ìrora ayé fún un pa, wọn kò sì lè so èso àsogbó. Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dìímú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso.
”Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn wọ̀nyí tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é.”
”Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là. Nítorí pé èrè kín ni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó fi ṣòfò. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni ọmọ ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn angẹli mímọ́.
”Ó sì wí fún ẹlòmíràn pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n èyí wí fún un pé, “Olúwa, jẹ́ kí èmi lọ sìnkú baba mi ná.” Jesu sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sìnkú ara wọn: ṣùgbọ́n ìwọ lọ kí o sì máa wàásù ìjọba Ọlọ́run.” Ẹlòmíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.” Jesu sì wí fún un pé, “Kò sí ẹni, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun èlò ìtulẹ̀, tí ó sì wo ẹ̀yìn, tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.”
”Ṣùgbọ́n òun wí pé, nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!”
”Ẹnìkan sì bi í pé, Olúwa, díẹ̀ ha kọ ni àwọn tí a ó gbàlà? Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ làkàkà láti gba ojú ọ̀nà tóóró wọlé: nítorí mo wí fún yín, ènìyàn púpọ̀ ni yóò wá ọ̀nà láti wọ̀ ọ́, wọn kì yóò sì lè wọlé.
”“Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kórìíra baba àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
”“Òfin àti àwọn wòlíì ń bẹ títí di ìgbà Johanu: Láti ìgbà náà wá ni a ti ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù sì ń fi ipá wọ inú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó rọrùn fún ọ̀run òun ayé láti kọjá lọ, ju kí èyí tí ó kéré jù nínú òfin kí ó yẹ.
”“Abrahamu sì wí fún un pé, ‘Wọ́n ní Mose àti àwọn wòlíì; kí wọn kí ó gbọ́ tiwọn.’ “Ó sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, Abrahamu baba; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ti inú òkú tọ̀ wọ́n lọ, wọn ó ronúpìwàdà.’ “Ó sì wí fún un pé, ‘Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mose àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde.’ ”
”Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.
”Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́:
”Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mose àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.
”Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé: A ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mose, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Saamu, nípasẹ̀ mi.” Nígbà náà ni ó ṣí wọn ní iyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn.
”Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà.
”Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá.
”Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn; wọ́n sì gba ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ gbọ́.
”Bí mo bá sọ ohun ti ayé yìí fún yín, tí ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbàgbọ́ bí mo bá sọ ohun ti ọ̀run fún yín?
”“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là. Ẹni tí ó bá gbà á gbọ́, a kò ní dá a lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n a ti dá ẹni tí kò gbà á gbọ́ lẹ́jọ́ ná, nítorí tí kò gba orúkọ ọmọ kan ṣoṣo ti Ọlọ́run gbọ́.
”Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke.
”Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun: ẹni tí kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yóò rí ìyè; nítorí ìbínú Ọlọ́run ń bẹ lórí rẹ̀.”
”Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”
”“Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ó ní ìyè tí kò nípẹ̀kun, òun kì yóò sì wá sí ìdájọ́; ṣùgbọ́n ó ti ré ikú kọjá bọ́ sí ìyè. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn ọmọ Ọlọ́run: àwọn tí ó bá gbọ́ yóò sì yè.
”Ẹ kò sì ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti máa gbé inú yín: nítorí ẹni tí ó rán, òun ni ẹ̀yin kò gbàgbọ́. Ẹ̀yin ń wá ìwé mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rìí mi.
”Ẹ̀mí ní ń sọ ni di ààyè; ara kò ní èrè kan; ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo sọ fún yín, ẹ̀mí ni, ìyè sì ni pẹ̀lú.
”Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.”
”Nítorí náà Jesu wí fún àwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi nítòótọ́. Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”
”Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké. Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́. Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣọ òtítọ́, èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà mí gbọ́? Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”
”Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò rí ikú láéláé.”
”Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín. Àwọn àgùntàn mi ń gbọ́ ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn:
”Bí ó bá pè wọ́n ní Ọlọ́run, àwọn ẹni tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, a kò sì lè ba ìwé mímọ́ jẹ́.
”Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun. Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn: àti pe níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú: bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún.
”Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́. Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé: “Olúwa, ta ni ó gba ìwàásù wa gbọ́ Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?” Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Isaiah sì tún sọ pé: “Ó ti fọ́ wọn lójú, Ó sì ti sé àyà wọn le; kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.” Nǹkan wọ̀nyí ni Isaiah wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisi wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sinagọgu: Nítorí wọ́n fẹ́ ìyìn ènìyàn ju ìyìn ti Ọlọ́run lọ.
”Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.
”Nítorí èmi kò dá ọ̀rọ̀ sọ fún ara mi, ṣùgbọ́n Baba tí ó rán mi, ni ó ti fún mi ní àṣẹ, ohun tí èmi ó sọ, àti èyí tí èmi ó wí. Èmi sì mọ̀ pé ìyè àìnípẹ̀kun ni òfin rẹ̀: nítorí náà, àwọn ohun tí mo bá wí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wí!”
”Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.
”“Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́.
”Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì ń pa wọ́n mọ́, òun ni ẹni tí ó fẹ́ràn mi: ẹni tí ó bá sì fẹ́ràn mi, a ó fẹ́ràn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba mi, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un.”
”Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́; Baba mi yóò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀. Ẹni tí kò fẹ́ràn mi ni kò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́; ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin ń gbọ́ kì í ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ti Baba tí ó rán mi.
”Bí ẹ̀yin bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi bá sì gbé inú yín, ẹ ó béèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, a ó sì ṣe é fún yín.
”Ṣùgbọ́n nígbà tí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ náà bá dé, yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo; nítorí kì yóò sọ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, òun ni yóò máa sọ: yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín.
”Èmi ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn; ayé sì ti kórìíra wọn, nítorí tí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe ti ayé.
”Sọ wọ́n di mímọ́ nínú òtítọ́: òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.
”Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “ọba ni ọ́ nígbà náà?” Jesu dáhùn wí pé, “Ìwọ wí pé, ọba ni èmi jẹ́. Nítorí èyí ni a ṣe bí mí, àti nítorí ìdí èyí ni mo sì ṣe wá sí ayé kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́, olúkúlùkù ẹni tí í ṣe ti òtítọ́ ń gbọ́ ohùn mi.”
”Ṣùgbọ́n Peteru àti àwọn aposteli dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ!
”Paulu àti Barnaba sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà.
”Àwọn Júù Berea sì ní ìyìn ju àwọn tí Tẹsalonika lọ, ní tí pé wọn fi tọkàntọkàn gbà ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì ń wá inú ìwé mímọ́ lójoojúmọ́ bí nǹkan wọ̀nyí bá rí bẹ́ẹ̀.
”Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ ni ilé ìwé Tirannusi.
”Nítorí tí èmi mọ̀ pé, lẹ́yìn lílọ mi, ìkookò búburú yóò wọ àárín yín, yóò sì tú agbo ká. Láàrín ẹ̀yin tìkára yín ni àwọn ènìyàn yóò sì dìde, tí wọn yóò máa sọ̀rọ̀-òdì, láti fa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sẹ́yìn wọn. Nítorí náà ẹ máa ṣọ́ra, ki ẹ sì máa rántí pé, fún ọdún mẹ́ta, èmi kò dẹ́kun láti máa fi omijé kìlọ̀ fún olúkúlùkù ní ọ̀sán àti ní òru.
”“ ‘Tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, kí ó sì wí pé, “Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; à ti ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ẹ̀yin kì yóò sí wòye.” Nítorí ti àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì, etí wọn sì wúwo láti fi gbọ́, ojú wọn ni wọn sì ti di. Nítorí kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn kí ó má ba à fi etí wọn gbọ́, àti kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn kí ó má ba à yípadà, àti kí èmi má ba à mú wọn láradá.’
”Paulu, ìránṣẹ́ Jesu Kristi, ẹni tí a ti pè láti jẹ́ aposteli, tí a sì ti yà sọ́tọ̀ láti wàásù ìhìnrere Ọlọ́run, ìhìnrere tí ó ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ rí láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ nínú ìwé Mímọ́.
”Èmi kò tijú ìhìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú. Nítorí nínú ìhìnrere ni òdodo Ọlọ́run ti farahàn, òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí. Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá,
”Ǹjẹ́ àǹfààní wo ní Júù ní? Tàbí kín ni èrè ilà kíkọ? Púpọ̀ lọ́nà gbogbo; pàtàkì jùlọ ni pé àwọn ni a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lé lọ́wọ́. Ǹjẹ́ kí ha ni bí àwọn kan jẹ́ aláìgbàgbọ́? Àìgbàgbọ́ wọn yóò ha sọ òtítọ́ Ọlọ́run di asán bí? Kí a má rí! Kí Ọlọ́run jẹ́ olóòtítọ́, àti olúkúlùkù ènìyàn jẹ́ èké; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Kí a lè dá ọ láre nínú ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n kí ìwọ lè borí nígbà tí ìwọ bá wá sí ìdájọ́.”
”Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Kò sí ẹni tí í ṣe olódodo, kò sí ẹnìkan Kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọ́run.
”Àwa ha ń sọ òfin dasán nípa ìgbàgbọ́ bí? Kí a má rí i: ṣùgbọ́n a ń fi òfin múlẹ̀.
”Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa kíkú ohun tó so wá pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í ṣe ní ìlànà àtijọ́ tí ìwé òfin gùnlé.
”Bẹ́ẹ̀ ni mímọ́ ni òfin, mímọ́ sì ni àṣẹ, àti òdodo, àti dídára.
”Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa! Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi fúnra mi jẹ́ ẹrú sí òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mo jẹ́ ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.
”Nítorí èrò ti ara ọ̀tá ni sí Ọlọ́run, nítorí kì í tẹríba fún òfin Ọlọ́run, òun kò tilẹ̀ le ṣe e.
”Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìhìnrere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ohun rere!” Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìhìnrere. Nítorí Isaiah wí pé, “Olúwa, ta ni ó gba ìyìn wa gbọ́?” Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
”Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Ọlọ́run ti fún wọn ní ẹ̀mí oorun, àwọn ojú tí kò le ríran àti àwọn etí tí kò le gbọ́rọ̀, títí ó fi di òní olónìí yìí.”
”Nítorí ohun gbogbo tí a kọ tẹ́lẹ̀, ni a kọ láti fi kọ́ wa pé, nípa sùúrù àti ìtùnú ìwé mímọ́, kí àwa lè ní ìrètí.
”Èmí rọ̀ yín, ara, kí ẹ máa sọ àwọn tí ń fa ìyapa, àti àwọn tí ń mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá sí ọ̀nà yín, èyí tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin kọ́. Ẹ yà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kristi Olúwa wa, bí kò ṣe ikùn ara wọn. Nípa ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà.
”Nítorí pé òmùgọ̀ ni ọ̀rọ̀ àgbélébùú jẹ́ sí àwọn tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún àwa tí a ń gbàlà ó jẹ́ agbára Ọlọ́run.
”Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrín àwọn tí a pè; ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó fi ara sin, ọgbọ́n tí ó ti fi ara pamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa.
”Èyí ni àwa ń wí, kì í ṣe èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ènìyàn nípa ti ara kò gba ohun ti Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀n-ọ́n-nì, nítorí pé wèrè ni wọ́n jásí fún un, òun kò sì le mọ̀ wọ́n, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀.
”Ìkọlà kò jẹ́ nǹkan àti àìkọlà kò jẹ́ nǹkan, bí kò ṣe pípa òfin Ọlọ́run mọ́.
”Ǹjẹ́ ará, èmi ń sọ ìhìnrere náà dí mí mọ̀ fún un yín, tí mo ti wàásù fún un yín, èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ti gbá, nínú èyí tí ẹ̀yin sì dúró. Nípasẹ̀ ìhìnrere yìí ni a fi ń gbà yín là pẹ̀lú, bí ẹ̀yin bá di ọ̀rọ̀ ti mo ti wàásù fún yín mú ṣinṣin. Bí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ẹ̀yin kàn gbàgbọ́ lásán.
”Bí ẹnikẹ́ni kò bá ní ìfẹ́ Jesu Kristi Olúwa, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú. Máa bọ Olúwa wa!
”Nítorí òórùn dídùn Kristi ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé: Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó ha si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí?
”Ẹni tí ó mú wa yẹ bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe ní ti ìwé àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí, nítorí ìwé a máa pa ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ní di ààyè. Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ); yóò ha ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù? Nítorí pé bi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo.
”Ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífi òtítọ́ hàn, àwa ń fi ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n báyìí, bí Ìhìnrere wa bá sí fi ara sin, ó fi ara sin fún àwọn tí ó ń ṣègbé. Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn.
”Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi.
”Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn èké Aposteli àwọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa wọ́n dà di aposteli Kristi. Kì í sì í ṣe ohun ìyanu; nítorí Satani, tìkára rẹ̀ ń pa ara rẹ̀ dàbí angẹli ìmọ́lẹ̀.
”Nítorí àwa kò lè ṣe ohun kan lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe fún òtítọ́.
”Ó yà mi lẹ́nu pé ẹ tètè yapa kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó pè yín sínú oore-ọ̀fẹ́ Kristi, sí ìhìnrere mìíràn: Nítòótọ́, kò sí ìhìnrere mìíràn: bí ó tilẹ̀ ṣe pé àwọn kan wà, tí ń yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n sì ń fẹ́ yí ìhìnrere Kristi padà. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe àwa ni tàbí angẹli kan láti ọ̀run wá, ni ó bá wàásù ìhìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí a tí wàásù rẹ̀ fún yín lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé! Bí àwa ti wí ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni mo sì tún wí nísinsin yìí pé: Bí ẹnìkan bá wàásù ìhìnrere mìíràn fún yín ju èyí tí ẹ̀yin tí gbà lọ, jẹ́ kí ó di ẹni ìfibú títí láéláé!
”Àwọn ẹni ti a kò fún ni àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn fún ìṣẹ́jú kan; kí ẹ̀yin kí o lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ ìhìnrere náà.
”Nítorí pé iye àwọn tí ń bẹ ni ipa iṣẹ́ òfin ń bẹ lábẹ́ ègún: nítorí tí a tí kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí kò dúró nínú ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé òfin láti máa ṣe wọ́n.
”Kristi ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.” Ó gbà wá là ki ìbùkún Abrahamu ba à lè wá sórí àwọn aláìkọlà nípa Kristi Jesu; kí àwa ba à lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa ìgbàgbọ́.
”Ǹjẹ́ fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Ìwé Mímọ́ kò ṣe wí pé, Fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀, bí ẹni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀; ṣùgbọ́n bí ẹni pé ọ̀kan ṣoṣo, àti fún irú-ọmọ rẹ̀, èyí tí í ṣe Kristi.
”Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùtọ́jú láti mú ènìyàn wá sọ́dọ̀ Kristi, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́.
”Ǹjẹ́ mo ha di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fún yín bí?
”Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́,
”Kí àwa má ṣe jẹ́ èwe mọ́, tí a ń fi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá tì sẹ́yìn, tí a sì fi ń gbá kiri, nípa ìtànjẹ ènìyàn, nípa àrékérekè fun ọgbọ́nkọ́gbọ́n àti mú ni ṣìnà;
”Kí òun lè sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fi ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí.
”Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
”Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti síwájú sí i nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní òye ohun tí ó dára jùlọ; kí ó sì jásí òdodo àti aláìjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ títí di ọjọ́ dídé Jesu Kristi:
”Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán.
”bí ẹ̀yin bá dúró nínú ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ sì dúró ṣinṣin, láláìyẹsẹ̀ kúrò nínú ìrètí ti ìhìnrere ti ẹ̀yin ti gbọ́, èyí tí a ti wàásù rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lábẹ́ ọ̀run, àti èyí ti èmi Paulu ṣe ìránṣẹ́ fún.
”Ẹ rí dájú pé ẹnikẹ́ni kò mú yin ní ìgbèkùn pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àròsọ àti ìmọ̀ ẹ̀tàn, èyí tí ó gbára lé ìlànà ti ènìyàn àti àgbékalẹ̀ àwọn ẹ̀mí ayé yìí tí ó yàtọ̀ sí ti Kristi.
”Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣí ìlẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kristi, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú:
”Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín.
”Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Filipi bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìhìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle.
”Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.
”Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára. Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìhìnrere Jesu Olúwa wa. A ó fi ìparun àìnípẹ̀kun jẹ wọ́n ní yà, a ó sì ṣe wọn mọ̀ kúrò níwájú Olúwa àti inú ògo agbára rẹ̀
”Nígbà náà ni a ó fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, ẹni tí Jesu Olúwa yóò fi èémí ẹnu rẹ̀ pa, tí yóò sì fi ọlá ìpadàbọ̀ rẹ̀ parun. Wíwá ẹni ẹ̀ṣẹ̀ yóò rí bí iṣẹ́ Satani, gbogbo èyí tí a fihàn gẹ́gẹ́ bí àdàmọ̀dì iṣẹ́ ìyanu, àdàmọ̀dì ààmì àti àdàmọ̀dì idán, Ní gbogbo ọ̀nà búburú tí a fi ń tan àwọn tí ń ṣègbé jẹ. Wọ́n ṣègbé nítorí wọ́n kọ̀ láti fẹ́ràn òtítọ́ kí wọn sì di ẹni ìgbàlà. Nítorí ìdí èyí, Ọlọ́run rán ohun tó ń ṣiṣẹ́ ìṣìnà sí wọn kí wọn lè gba èké gbọ́, kí wọn kí ó lè gba ìdálẹ́bi, àní àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ní inú dídùn nínú ìwà búburú.
”Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára. Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá wọn àti àwọn apànìyàn, fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro. Gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere ti ògo Ọlọ́run olùbùkún, tí a fi sí ìtọ́jú mi.
”Nítorí èyí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Olùgbàlà wa; Ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́.
”Ṣùgbọ́n bí mo bá pẹ́, kí ìwọ lè mọ̀ bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn láti máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run, tì í ṣe ìjọ Ọlọ́run alààyè, ọ̀wọ́n àti ìpìlẹ̀ òtítọ́.
”Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.
”Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ ìránṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé.
”Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbani-níyànjú àti ìkọ́ni.
”Máa ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láìyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.
”Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ́rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábápín nínú ìpọ́njú ìhìnrere nípa agbára Ọlọ́run,
”Bí àwa bá faradà, àwa ó sì bá a jẹ ọba: Bí àwa bá sẹ́ ẹ, òun náà yóò sì sẹ́ wa.
”Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò ní láti tijú, tí ó ń pín ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ
”Ìránṣẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà; bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, àti onísùúrù. Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrètí pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtítọ́,
”Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́.
”Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. Gbogbo ìwé mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo. Kí ènìyàn Ọlọ́run lè pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fun iṣẹ́ rere gbogbo.
”Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsimi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bá ni wí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo. Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó olùkọ́ jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán.
”Ó gbọdọ̀ di ẹ̀kọ́ nípa ìdúró ṣinṣin mú dáradára gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ ọ, kí ó lè fi ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Nípa èyí, yóò lè fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀ fún àwọn alátakò.
”Òtítọ́ ni ẹ̀rí yìí. Nítorí náà, bá wọn wí gidigidi, kí wọn ba à lè yè koro nínú ìgbàgbọ́
”Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro lórí ìgbé ayé onígbàgbọ́ tòótọ́.
”Nítorí náà, ó yẹ kí àwa máa fi iyè sí àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì gidigidi tí àwa ti gbọ́, kí a má ba à gbá wa lọ kúrò nínú wọn nígbà kan. Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tí ẹnu àwọn angẹli sọ bá sì dúró ṣinṣin, àti tí olúkúlùkù ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin àti àìgbọ́ràn gba ìjìyà tí ó tọ́ sí i, kín ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí? Ìgbàlà tí Olúwa fúnrarẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀.
”Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí: “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le, bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀, bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní aginjù: Níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò, tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún. Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà, mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn ṣìnà ní ọkàn wọn; wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’ Bí mo tí búra nínú ìbínú mi, ‘wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ” Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.
”Nítorí tí àwa gbọ́ ìwàásù ìhìnrere, gẹ́gẹ́ bí a ti wàásù rẹ̀ fún àwọn náà pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ kò ṣe wọ́n ní àǹfààní, nítorí tí kò dàpọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú àwọn tí ó gbọ́ ọ. Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí, “Bí mo tí búra nínú ìbínú mi, ‘Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpìlẹ̀ ayé.
”Nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ní agbára, ó sì mu ju idàkídà olójú méjì lọ, ó sì ń gún ni, àní títí dé pínpín ọkàn àti ẹ̀mí ní yà, àti ní oríkèé àti ọ̀rá inú egungun, òun sì ni olùmọ̀ èrò inú àti ète ọkàn. Kò sí ẹ̀dá kan tí kò farahàn níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni ó wà níhòhò tí a sì ṣípáyà fún ojú rẹ̀, níwájú ẹni tí àwa yóò jíyìn.
”Nítorí pé, kò ṣe é ṣe fún àwọn tí a ti là lójú lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n sì ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, tí wọn sì ti di alábápín Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọn sì tọ́ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run wò, àti agbára ayé tí ń bọ̀, láti tún sọ wọ́n di ọ̀tun sí ìrònúpìwàdà bí wọn bá ṣubú kúrò; nítorí tí wọ́n tún kan ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélébùú sí ara wọn lọ́tun, wọ́n sì dójútì í ní gbangba.
”Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá lẹ́yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí. Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn, èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn, èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.
”“Èyí ni májẹ̀mú ti èmi o ba wọn dá lẹ́hìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí. Èmi o fi òfin mi sí wọn ní ọkàn, inú wọn pẹ̀lú ni èmi o sì kọ wọn sí.”
”Nítorí bí àwa ba mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ni lẹ́rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀tá run. Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Mose, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta: Mélòó mélòó ni ẹ rò pé a o jẹ ẹni náà ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹ́gàn ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́.
”Ṣùgbọ́n láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣe é ṣe láti wù ú; nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá kò lè ṣàì gbàgbọ́ pé ó ń bẹ, àti pé òun ní olùṣẹ̀san fún àwọn tí o fi ara balẹ̀ wá a.
”Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe kọ̀ ẹni tí ń kìlọ̀. Nítorí bí àwọn wọ̀nyí kò bá bọ́ nígbà tí wọn kọ̀ ẹni ti ń kìlọ̀ ni ayé, mélòó mélòó ni àwa kì yóò bọ́, bí àwa ba pẹ̀hìndà sí ẹni tí ń kìlọ̀ láti ọ̀run wá:
”Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó ni run ni.”
”Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kì í sì ka àlébù sí; a ó sì fi fún un.
”Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburú tí ó gbilẹ̀ yíká, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là. Ẹ má kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà lásán, kí ẹ má ba à ti ipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣe ohun tí ó sọ. Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú dígí Nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójúkan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí.
”Ẹ̀yin panṣágà ọkùnrin, àti panṣágà obìnrin, ẹ kò mọ̀ pé ìbárẹ́ ayé ìṣọ̀tá Ọlọ́run ni? Nítorí náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọ̀tá Ọlọ́run. Ẹ̀yin ṣe bí Ìwé mímọ́ sọ lásán pé, Ẹ̀mí tí ó fi sínú wa ń jowú gidigidi lórí wa? Ṣùgbọ́n ó fún ni ní oore-ọ̀fẹ́ sí i. Nítorí náà ni ìwé mímọ́ ṣe wí pé, “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga, ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn.” Nítorí náà, ẹ tẹríba fún Ọlọ́run. Ẹ kọ ojú ìjà sí èṣù, òun ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ súnmọ́ Ọlọ́run, òun ó sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀; ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyèméjì. Ẹ banújẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì hu fún ẹkún. Ẹ jẹ́ kí ẹ̀rín yín kí ó di ọ̀fọ̀, àti ayọ̀ yín kí ó di ìbànújẹ́. Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, òun ó sì gbé yín ga.
”Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá. Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láààyè tí ó sì dúró. Nítorí pé, “Gbogbo ènìyàn dàbí koríko, àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko. Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù, Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.” Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìhìnrere tí a wàásù fún yín.
”Bí ọmọ ọwọ́ tuntun, kí ẹ máa fẹ́ wàrà ti Ẹ̀mí, èyí tí kò lẹ́tàn, kí ẹ̀yin lè máa tipasẹ̀ rẹ̀ dàgbà sí ìgbàlà,
”Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́, “Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun ni ó di pàtàkì igun ilé,” àti pẹ̀lú, “Òkúta ìdìgbòlù, àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.” Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.
”Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá: bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀yìn àwọn tí kò gba ìhìnrere Ọlọ́run yó ha ti rí?
”Àwa pẹ̀lú sì gbọ́ ohun yìí tí ó ti ọ̀run wá nígbà tí àwa wà pẹ̀lú rẹ̀ ní orí òkè mímọ́ náà. Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì dunjúdunjú sí i, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsi gẹ́gẹ́ bí fìtílà tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí ẹ ní òye yìí pé kò sí àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mímọ́ kankan tí ó wáyé nípa ìtumọ̀ wòlíì fún rara rẹ̀. Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipá ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá.
”Ṣùgbọ́n àwọn wòlíì èké wà láàrín àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ni èké yóò ti wà láàrín yín. Wọn yóò yọ́ kẹ́lẹ́ mú ẹ̀kọ́ òdì àti ègbé tọ̀ yín wa, àní tí yóò sẹ́ Olúwa tí ó rà wọ́n padà, wọ́n ó sì mú ìparun ti o yára kánkán wá sórí ara wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì sí. Nínú ìwà wọ̀bìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì wọ̀nyí yóò máa rẹ́ ẹ yín jẹ nípa ìtàn asán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé.
”Bí ó tí ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú nínú ìwé rẹ̀ gbogbo nínú èyí ti ohun mìíràn sọ̀rọ̀ láti yé ni gbé wà, èyí ti àwọn òpè àti àwọn aláìdúró níbìkan ń lo, bí wọ́n ti ń lo ìwé mímọ́ ìyókù, sí ìparun ara wọn. Nítorí náà ẹ̀yin olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti mọ nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀, ẹ máa kíyèsára, kí a má ba à fi ìṣìnà àwọn ènìyàn búburú fà yín lọ, kí ẹ sì ṣubú kúrò ní ìdúró ṣinṣin yín.
”Àwa mọ̀ pé àwa ti wá mọ̀ ọ́n, bí àwa bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́. Ẹni tí ó bá wí pé, “Èmi mọ̀ ọ́n,” tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì ṣí nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́, lára rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń wà nínú rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti rìn.
”Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run: nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé.
”Ti Ọlọ́run ni àwa: ẹni tí ó bá mọ Ọlọ́run, ó ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í ṣe ti Ọlọ́run kò ni gbọ́ ti wa. Nípa èyí ni àwa mọ ẹ̀mí òtítọ́, àti ẹ̀mí èké.
”Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run, tí a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́.
”Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́, ó ni ẹ̀rí nínú ara rẹ̀; ẹni tí kò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó ti mú un ni èké; nítorí kò gba ẹ̀rí náà gbọ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ní ti Ọmọ rẹ̀.
”Èyí sì ni ìfẹ́, pé, kí àwa máa rin nípa òfin rẹ̀, èyí ni òfin náà, àní bí ẹ ti gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé, kí ẹ̀yin rìn nínú rẹ̀.
”Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò si dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi, kò mọ Ọlọ́run. Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó mọ Baba àti Ọmọ. Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mu ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé, kí ẹ má sì ṣe kí i kú ààbọ̀. Nítorí ẹni tí ó bá kí kú ààbọ̀, ó ní ọwọ́ nínú iṣẹ́ búburú rẹ̀.
”Nítòótọ́, ẹ ti mọ nǹkan wọ̀nyí ní ẹ̀ẹ̀kan rí, mo fẹ́ rán an yín létí pé, lẹ́yìn tí Olúwa ti gba àwọn kan là láti ilẹ̀ Ejibiti wá, lẹ́yìn náà ni ó run àwọn tí kò gbàgbọ́.
”Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde: Ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn.
”Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú: àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọ́n kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n;
”Nítorí náà, ronúpìwàdà; bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó tọ̀ ọ́ wá nísinsin yìí, èmí o sì fi idà ẹnu mi bá wọn jà.
”Ǹjẹ́ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi. Nítorí tí ìwọ wí pé, Èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò sì ṣe aláìní ohunkóhun; tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ìkáàánú, tálákà, afọ́jú, àti ẹni ìhòhò:
”Dragoni náà sì bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn irú-ọmọ rẹ̀ ìyókù jagun, tí wọ́n ń pa òfin Ọlọ́run mọ̀, tí wọn sì di ẹ̀rí Jesu mú, Ó sì dúró lórí iyanrìn Òkun.
”Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìhìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn. Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”
”Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa, tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀? Nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni mímọ́. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò sì wá, ti yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ, nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”
”Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀. A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
”Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè.
”Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde: Gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran-ara wọn yó.
”Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkù ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fi kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un. Bí ẹnikẹ́ni bá sì mú kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò sì mú ipa tirẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, àti kúrò nínú ìlú mímọ́ náà, àti kúrò nínú àwọn ohun tí a kọ sínú ìwé yìí.
”